Àkọsílẹ̀ Jòhánù 19:1-42

  • Wọ́n na Jésù, wọ́n sì fi ṣe yẹ̀yẹ́ (1-7)

  • Pílátù tún bi Jésù léèrè ọ̀rọ̀ (8-16a)

  • Wọ́n kan Jésù mọ́ òpó igi ní Gọ́gọ́tà (16b-24)

  • Jésù ṣètò bí wọ́n ṣe máa bójú tó ìyá rẹ̀ (25-27)

  • Ikú Jésù (28-37)

  • Wọ́n sìnkú Jésù (38-42)

19  Pílátù wá mú Jésù, ó sì nà án.+  Àwọn ọmọ ogun fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n dé e sí i lórí, wọ́n sì wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù fún un,+  wọ́n ń wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ṣáá, wọ́n sì ń sọ pé: “A kí ọ o,* ìwọ Ọba Àwọn Júù!” Wọ́n sì ń gbá a létí léraléra.+  Pílátù bá tún bọ́ síta, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Mo mú un jáde wá bá yín, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.”+  Torí náà, Jésù jáde síta, ó dé adé ẹ̀gún, ó sì wọ aṣọ aláwọ̀ pọ́pù náà. Pílátù wá sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin náà nìyí!”  Àmọ́, nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rí i, wọ́n kígbe pé: “Kàn án mọ́gi! Kàn án mọ́gi!”*+ Pílátù sọ fún wọn pé: “Ẹ mú un fúnra yín, kí ẹ sì pa á,* torí èmi ò rí i pé ó jẹ̀bi kankan.”+  Àwọn Júù dá a lóhùn pé: “A ní òfin kan, bí òfin yẹn sì ṣe sọ, ó yẹ kó kú,+ torí ó pe ara rẹ̀ ní ọmọ Ọlọ́run.”+  Nígbà tí Pílátù gbọ́ ohun tí wọ́n ń sọ, ẹ̀rù túbọ̀ bà á,  ló bá tún wọ ilé gómìnà, ó sì sọ fún Jésù pé: “Ibo lo ti wá?” Àmọ́ Jésù ò dá a lóhùn.+ 10  Torí náà, Pílátù sọ fún un pé: “Ṣé o ò fẹ́ bá mi sọ̀rọ̀ ni? Àbí o ò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti tú ọ sílẹ̀, mo sì tún ní àṣẹ láti pa ọ́?”* 11  Jésù dá a lóhùn pé: “O ò lè ní àṣẹ kankan lórí mi àfi tí a bá fún ọ láṣẹ látòkè. Ìdí nìyẹn tí ẹ̀ṣẹ̀ ọkùnrin tó fi mí lé ọ lọ́wọ́ fi tóbi jù.” 12  Torí èyí, Pílátù ṣáà ń wá bó ṣe máa tú u sílẹ̀, àmọ́ àwọn Júù kígbe pé: “Tí o bá tú ọkùnrin yìí sílẹ̀, o kì í ṣe ọ̀rẹ́ Késárì. Ṣe ni gbogbo ẹni tó bá pe ara rẹ̀ ní ọba ń ta ko* Késárì.”+ 13  Lẹ́yìn tí Pílátù gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, ó mú Jésù wá síta, ó sì jókòó sórí ìjókòó ìdájọ́ níbi tí wọ́n ń pè ní Ibi Tí A Fi Òkúta Tẹ́, ìyẹn Gábátà lédè Hébérù. 14  Ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́+ Ìrékọjá; nǹkan bíi wákàtí kẹfà ni.* Ó wá sọ fún àwọn Júù pé: “Ẹ wò ó! Ọba yín nìyí!” 15  Àmọ́ wọ́n kígbe pé: “Mú un lọ! Mú un lọ! Kàn án mọ́gi!”* Pílátù sọ fún wọn pé: “Ṣé kí n pa ọba yín ni?” Àwọn olórí àlùfáà dá a lóhùn pé: “A ò ní ọba kankan àfi Késárì.” 16  Ó wá fà á lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kàn án mọ́gi.+ Ni wọ́n bá mú Jésù lọ. 17  Ó ru òpó igi oró* náà fúnra rẹ̀, ó sì lọ síbi tí wọ́n ń pè ní Ibi Agbárí,+ ìyẹn Gọ́gọ́tà lédè Hébérù.+ 18  Ibẹ̀ ni wọ́n ti kàn án mọ́gi+ pẹ̀lú ọkùnrin méjì, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn wà ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, Jésù sì wà ní àárín.+ 19  Pílátù tún kọ àkọlé kan, ó sì fi sórí òpó igi oró* náà. Ó kọ ọ́ pé: “Jésù Ará Násárẹ́tì Ọba Àwọn Júù.”+ 20  Ọ̀pọ̀ àwọn Júù ló ka àkọlé yìí, torí pé ibi tí wọ́n ti kan Jésù mọ́gi kò jìnnà sí ìlú náà, wọ́n sì kọ ọ́ ní èdè Hébérù, èdè Látìn àti èdè Gíríìkì. 21  Àmọ́ àwọn olórí àlùfáà àwọn Júù sọ fún Pílátù pé: “Má kọ ọ́ pé, ‘Ọba Àwọn Júù,’ àmọ́ pé ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọba Àwọn Júù.’” 22  Pílátù dáhùn pé: “Ohun tí mo ti kọ, mo ti kọ ọ́.” 23  Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ ogun kan Jésù mọ́gi tán, wọ́n mú aṣọ àwọ̀lékè rẹ̀, wọ́n pín in sí mẹ́rin, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan, wọ́n tún mú aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀. Àmọ́ aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ náà ò ní ojú rírán, ṣe ni wọ́n hun ún látòkè délẹ̀. 24  Torí náà, wọ́n sọ fún ara wọn pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ ká ya á, àmọ́ ẹ jẹ́ ká fi kèké pinnu ti ẹni tó máa jẹ́.”+ Èyí jẹ́ torí kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ pé: “Wọ́n pín ẹ̀wù mi láàárín ara wọn, wọ́n sì ṣẹ́ kèké nítorí aṣọ mi.”+ Àwọn ọmọ ogun náà ṣe àwọn nǹkan yìí lóòótọ́. 25  Àmọ́ ìyá+ Jésù àti arábìnrin ìyá rẹ̀ dúró sí tòsí òpó igi oró* rẹ̀; Màríà ìyàwó Kílópà àti Màríà Magidalénì.+ 26  Torí náà, nígbà tí Jésù rí ìyá rẹ̀ àti ọmọ ẹ̀yìn tó nífẹ̀ẹ́,+ tí wọ́n dúró nítòsí, ó sọ fún ìyá rẹ̀ pé: “Obìnrin, wò ó! Ọmọ rẹ!” 27  Lẹ́yìn náà, ó sọ fún ọmọ ẹ̀yìn náà pé: “Wò ó! Ìyá rẹ!” Láti wákàtí yẹn lọ, ọmọ ẹ̀yìn náà mú un lọ sí ilé ara rẹ̀. 28  Lẹ́yìn náà, nígbà tí Jésù mọ̀ pé a ti ṣe ohun gbogbo parí, kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ, ó sọ pé: “Òùngbẹ ń gbẹ mí.”+ 29  Ìṣà kan wà níbẹ̀ tí wáìnì kíkan kún inú rẹ̀. Torí náà, wọ́n fi kànrìnkàn tí wọ́n rẹ sínú wáìnì kíkan sórí pòròpórò hísópù,* wọ́n sì gbé e sí i lẹ́nu.+ 30  Lẹ́yìn tó gba wáìnì kíkan náà, Jésù sọ pé: “A ti ṣe é parí!”+ ló bá tẹ orí rẹ̀ ba, ó sì jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀.*+ 31  Torí pé ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́,+ àwọn Júù ní kí Pílátù ṣẹ́ ẹsẹ̀ wọn, kí wọ́n sì gbé òkú wọn lọ, kí àwọn òkú náà má bàa wà lórí òpó igi oró+ ní Sábáàtì (torí pé ọjọ́ ńlá ni Sábáàtì yẹn).+ 32  Torí náà, àwọn ọmọ ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ ẹsẹ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́ àti ti ọkùnrin kejì tó wà lórí òpó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. 33  Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jésù, wọ́n rí i pé ó ti kú, torí náà, wọn ò ṣẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀. 34  Ṣùgbọ́n ọ̀kan lára àwọn ọmọ ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́,+ ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. 35  Ẹni tó rí i ti jẹ́rìí yìí, òótọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ó sì mọ̀ pé òótọ́ ni ohun tí òun sọ, kí ẹ̀yin náà lè gbà gbọ́.+ 36  Ní tòótọ́, àwọn nǹkan yìí ṣẹlẹ̀ kí ìwé mímọ́ lè ṣẹ pé: “Wọn ò ní ṣẹ́* ìkankan nínú egungun rẹ̀.”+ 37  Ẹsẹ ìwé mímọ́ míì tún sọ pé: “Wọ́n máa wo ẹni tí wọ́n gún.”+ 38  Lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí, Jósẹ́fù ará Arimatíà, tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àmọ́ tí kò jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ torí pé ó ń bẹ̀rù àwọn Júù,+ béèrè lọ́wọ́ Pílátù pé kó jẹ́ kí òun gbé òkú Jésù lọ, Pílátù sì gbà á láyè. Torí náà, ó wá gbé òkú rẹ̀ lọ.+ 39  Nikodémù+ náà wá, ọkùnrin tó ti kọ́kọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ní òru, ó mú àdàpọ̀* òjíá àti álóé wá, ó tó nǹkan bí ọgọ́rùn-ún (100) ìwọ̀n pọ́n-ùn.*+ 40  Torí náà, wọ́n gbé òkú Jésù, wọ́n sì fi aṣọ ọ̀gbọ̀* dì í pẹ̀lú àwọn èròjà tó ń ta sánsán náà,+ bí àwọn Júù ṣe máa ń sìnkú. 41  Ó ṣẹlẹ̀ pé ọgbà kan wà níbi tí wọ́n ti pa á,* ibojì* tuntun+ kan sì wà nínú ọgbà náà, tí wọn ò tẹ́ ẹnì kankan sí rí. 42  Torí pé ó jẹ́ ọjọ́ Ìpalẹ̀mọ́ + àwọn Júù, tí ibojì náà sì wà nítòsí, wọ́n tẹ́ Jésù síbẹ̀.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “A júbà rẹ.”
Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kàn án mọ́ òpó igi.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “kàn ọ́ mọ́ òpó igi?” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “sọ̀rọ̀ òdì sí.”
Ìyẹn, nǹkan bí aago méjìlá ọ̀sán.
Tàbí “mọ́ òpó igi!” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ó sì gbẹ́mìí mì.”
Tàbí “fọ́.”
Tàbí kó jẹ́, “àdìpọ̀.”
Ìyẹn, pọ́n-ùn ti àwọn ará Róòmù. Wo Àfikún B14.
Tàbí “aṣọ àtàtà.”
Tàbí “kàn án mọ́gi.”
Tàbí “ibojì ìrántí.”