Àkọsílẹ̀ Lúùkù 18:1-43

  • Àpèjúwe opó tí kò juwọ́ sílẹ̀ (1-8)

  • Farisí àti agbowó orí (9-14)

  • Jésù àti àwọn ọmọdé (15-17)

  • Alákòóso kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ béèrè ìbéèrè (18-30)

  • Jésù tún sọ tẹ́lẹ̀ nípa ikú rẹ̀ (31-34)

  • Alágbe kan tó fọ́jú pa dà ríran (35-43)

18  Ó wá sọ àpèjúwe kan fún wọn nípa ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn,+  ó ní: “Ní ìlú kan, adájọ́ kan wà tí kò bẹ̀rù Ọlọ́run, tí kò sì ka àwọn èèyàn sí.  Opó kan wà ní ìlú yẹn tó máa ń lọ sọ́dọ̀ adájọ́ náà ṣáá, ó máa ń sọ pé, ‘Rí i dájú pé o dá ẹjọ́ bó ṣe tọ́ láàárín èmi àti ẹni tó ń bá mi ṣẹjọ́.’  Adájọ́ náà ò kọ́kọ́ fẹ́ gbà, àmọ́ nígbà tó yá, ó sọ fún ara rẹ̀ pé, ‘Bí mi ò tiẹ̀ bẹ̀rù Ọlọ́run, tí mi ò sì ka èèyàn kankan sí,  torí pé opó yìí ò yéé yọ mí lẹ́nu, màá rí i dájú pé a dá ẹjọ́ rẹ̀ bó ṣe tọ́, kó má bàa máa pa dà wá ṣáá, kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ má bàa sú mi torí ohun tó ń béèrè.’”*+  Olúwa wá sọ pé: “Ẹ gbọ́ ohun tí adájọ́ náà sọ, bó tiẹ̀ jẹ́ pé aláìṣòdodo ni!  Ṣé kò wá dájú pé Ọlọ́run máa mú kí a dájọ́ bó ṣe tọ́ fún àwọn àyànfẹ́ rẹ̀ tí wọ́n ń ké pè é tọ̀sántòru,+ bó ṣe ń ní sùúrù fún wọn?+  Mò ń sọ fún yín, ó máa mú kí a dá ẹjọ́ wọn bó ṣe tọ́ kíákíá. Àmọ́ tí Ọmọ èèyàn bá dé, ṣé ó máa bá ìgbàgbọ́ yìí* ní ayé lóòótọ́?”  Ó tún sọ àpèjúwe yìí fún àwọn kan tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé òdodo ara wọn, tí wọ́n sì ka àwọn míì sí ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan: 10  “Ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ọ̀kan jẹ́ Farisí, ìkejì sì jẹ́ agbowó orí. 11  Farisí náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó ń dá sọ àwọn nǹkan yìí pé, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ pé mi ò dà bíi gbogbo àwọn èèyàn yòókù, àwọn tó ń fipá gba tọwọ́ àwọn èèyàn, àwọn aláìṣòdodo, àwọn alágbèrè, kódà mi ò dà bí agbowó orí yìí. 12  Ẹ̀ẹ̀mejì lọ́sẹ̀ ni mò ń gbààwẹ̀; mò ń san ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’+ 13  Àmọ́ agbowó orí náà dúró ní ọ̀ọ́kán, kò fẹ́ gbé ojú rẹ̀ sókè láti wo ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó ń lu àyà rẹ̀ ṣáá, ó ń sọ pé, ‘Ọlọ́run, ṣàánú mi,* ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí.’+ 14  Mo sọ fún yín, ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sílé rẹ̀, a sì kà á sí olódodo ju Farisí yẹn lọ.+ Torí pé gbogbo ẹni tó bá gbé ara rẹ̀ ga, a máa rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, a máa gbé e ga.”+ 15  Àwọn èèyàn tún ń mú àwọn ọmọ wọn kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀ kó lè fọwọ́ kàn wọ́n, àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn rí èyí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn wí.+ 16  Ṣùgbọ́n, Jésù pe àwọn ọmọ kéékèèké náà wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó ní: “Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọdé wá sọ́dọ̀ mi, ẹ má sì dá wọn dúró, torí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ti irú wọn.+ 17  Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, ó dájú pé ẹnikẹ́ni tí kò bá gba Ìjọba Ọlọ́run bí ọmọdé kò ní wọnú rẹ̀.”+ 18  Ọ̀kan lára àwọn alákòóso wá béèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Olùkọ́ Rere, kí ni mo gbọ́dọ̀ ṣe kí n lè jogún ìyè àìnípẹ̀kun?”+ 19  Jésù sọ fún un pé: “Kí ló dé tí o fi pè mí ní ẹni rere? Kò sí ẹni rere kankan, àfi Ọlọ́run nìkan.+ 20  O mọ àwọn àṣẹ náà pé: ‘O ò gbọ́dọ̀ ṣe àgbèrè,+ o ò gbọ́dọ̀ pààyàn,+ o ò gbọ́dọ̀ jalè,+ o ò gbọ́dọ̀ jẹ́rìí èké,+ bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.’”+ 21  Ọkùnrin náà wá sọ pé: “Gbogbo nǹkan yìí ni mo ti ń ṣe láti ìgbà ọ̀dọ́ mi.” 22  Lẹ́yìn tó gbọ́ ìyẹn, Jésù sọ fún un pé, “Ohun kan ṣì wà tó ò tíì ṣe: Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o pín owó tí o bá rí níbẹ̀ fún àwọn aláìní, wàá sì ní ìṣúra ní ọ̀run; kí o wá máa tẹ̀ lé mi.”+ 23  Nígbà tó gbọ́ èyí, inú rẹ̀ bà jẹ́ gan-an, torí ó ní ọrọ̀ púpọ̀.+ 24  Jésù wò ó, ó sì sọ pé: “Ẹ wo bó ṣe máa ṣòro tó fún àwọn olówó láti rí ọ̀nà wọ Ìjọba Ọlọ́run!+ 25  Ní tòótọ́, ó rọrùn fún ràkúnmí láti gba ojú abẹ́rẹ́ ìránṣọ kọjá ju fún ọlọ́rọ̀ láti wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 26  Àwọn tó gbọ́ èyí sọ pé: “Ta ló máa wá lè rígbàlà?”+ 27  Ó sọ pé: “Àwọn ohun tí kò ṣeé ṣe fún èèyàn ṣeé ṣe fún Ọlọ́run.”+ 28  Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Wò ó! A ti fi àwọn nǹkan tí a ní sílẹ̀, a sì ti tẹ̀ lé ọ.”+ 29  Ó sọ fún wọn pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún yín, kò sí ẹni tó fi ilé sílẹ̀ tàbí ìyàwó, àwọn arákùnrin, àwọn òbí tàbí àwọn ọmọ nítorí Ìjọba Ọlọ́run,+ 30  tí kò ní gba ìlọ́po-ìlọ́po sí i lásìkò yìí àti ìyè àìnípẹ̀kun nínú ètò àwọn nǹkan tó ń bọ̀.”*+ 31  Ó wá pe àwọn Méjìlá náà sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ wò ó! À ń gòkè lọ sí Jerúsálẹ́mù, gbogbo nǹkan tí a tipasẹ̀ àwọn wòlíì kọ sílẹ̀ nípa Ọmọ èèyàn ló sì máa ṣẹ délẹ̀délẹ̀.*+ 32  Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa fà á lé àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́,+ wọ́n máa fi ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n á hùwà àfojúdi sí i, wọ́n á sì tutọ́ sí i lára.+ 33  Lẹ́yìn tí wọ́n bá sì nà án, wọ́n máa pa á,+ àmọ́ ó máa dìde ní ọjọ́ kẹta.”+ 34  Ṣùgbọ́n, ìkankan nínú àwọn ọ̀rọ̀ yìí ò yé wọn, torí wọn ò mọ ìtúmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ yìí, wọn ò sì lóye ohun tó sọ. 35  Bí Jésù ṣe ń sún mọ́ Jẹ́ríkò, ọkùnrin afọ́jú kan jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó ń ṣagbe.+ 36  Torí ó gbọ́ ariwo èrò tó ń kọjá lọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wádìí ohun tó ń ṣẹlẹ̀. 37  Wọ́n sọ fún un pé: “Jésù ará Násárẹ́tì ló ń kọjá lọ!” 38  Ló bá kígbe pé: “Jésù, Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 39  Àwọn tó wà níwájú sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá a wí, wọ́n ní kó dákẹ́, àmọ́ ṣe ló túbọ̀ ń kígbe pé: “Ọmọ Dáfídì, ṣàánú mi!” 40  Jésù wá dúró, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú ọkùnrin náà wá sọ́dọ̀ òun. Lẹ́yìn tó sún mọ́ tòsí, Jésù bi í pé: 41  “Kí lo fẹ́ kí n ṣe fún ọ?” Ó sọ pé: “Olúwa, jẹ́ kí n pa dà ríran.” 42  Jésù wá sọ fún un pé: “Kí ojú rẹ pa dà ríran; ìgbàgbọ́ rẹ ti mú ọ lára dá.”+ 43  Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, ó pa dà ríran, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ̀ lé e,+ ó ń yin Ọlọ́run lógo. Bákan náà, gbogbo èèyàn yin Ọlọ́run nígbà tí wọ́n rí èyí.+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “kó sì máa lù mí láti tán mi lókun.”
Tàbí “irú ìgbàgbọ́ yìí.” Ní Grk., “ìgbàgbọ́ náà.”
Tàbí “ṣojúure sí mi.”
Tàbí “ní àsìkò tó ń bọ̀.” Wo Àlàyé Ọ̀rọ̀.
Tàbí “ló máa ṣẹlẹ̀ pátápátá.”