Nọ́ńbà 1:1-54

  • Wọ́n forúkọ àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun sílẹ̀ (1-46)

  • Àwọn ọmọ Léfì ò ní wọṣẹ́ ológun (47-51)

  • Bí wọ́n á ṣe pàgọ́ wọn létòlétò (52-54)

1  Jèhófà bá Mósè sọ̀rọ̀ ní aginjù Sínáì,+ nínú àgọ́ ìpàdé,+ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì, ọdún kejì tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ Ó sọ pé:  “Ẹ ka+ gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì* lọ́kọ̀ọ̀kan,* ní ìdílé-ìdílé, agbo ilé bàbá wọn, kí ẹ fi orúkọ ka gbogbo ọkùnrin.  Kí ìwọ àti Áárónì fi orúkọ gbogbo àwọn tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì sílẹ̀, ní àwùjọ-àwùjọ,* láti ẹni ogún (20) ọdún sókè.+  “Kí ẹ mú ọkùnrin kan látinú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan; kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́ olórí agbo ilé bàbá+ rẹ̀.  Orúkọ àwọn ọkùnrin tó máa dúró tì yín nìyí: ní ẹ̀yà Rúbẹ́nì, Élísúrì+ ọmọ Ṣédéúrì;  ní ẹ̀yà Síméónì, Ṣẹ́lúmíẹ́lì+ ọmọ Súríṣádáì;  ní ẹ̀yà Júdà, Náṣónì+ ọmọ Ámínádábù;  ní ẹ̀yà Ísákà, Nétánélì+ ọmọ Súárì;  ní ẹ̀yà Sébúlúnì, Élíábù+ ọmọ Hélónì; 10  nínú àwọn ọmọ Jósẹ́fù: látinú ẹ̀yà Éfúrémù,+ Élíṣámà ọmọ Ámíhúdù; látinú ẹ̀yà Mánásè, Gàmálíẹ́lì ọmọ Pédásúrì; 11  ní ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì, Ábídánì+ ọmọ Gídéónì; 12  ní ẹ̀yà Dánì, Áhíésérì+ ọmọ Ámíṣádáì; 13  ní ẹ̀yà Áṣérì, Págíẹ́lì+ ọmọ Ókíránì; 14  ní ẹ̀yà Gádì, Élíásáfù+ ọmọ Déúélì; 15  ní ẹ̀yà Náfútálì, Áhírà+ ọmọ Énánì. 16  Àwọn yìí ni wọ́n pè látinú àpéjọ náà. Wọ́n jẹ́ ìjòyè+ nínú ẹ̀yà àwọn bàbá wọn, olórí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ní Ísírẹ́lì.”+ 17  Mósè àti Áárónì wá mú àwọn ọkùnrin tí wọ́n forúkọ pè yìí. 18  Wọ́n pe gbogbo àwọn èèyàn náà jọ ní ọjọ́ kìíní oṣù kejì, kí wọ́n lè forúkọ sílẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan, ní ìdílé-ìdílé àti agbo ilé bàbá wọn, láti ẹni ogún (20) ọdún sókè,+ 19  bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè. Ó forúkọ wọn sílẹ̀ ní aginjù Sínáì.+ 20  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn ọmọkùnrin Rúbẹ́nì, àwọn àtọmọdọ́mọ àkọ́bí+ Ísírẹ́lì. Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan, 21  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Rúbẹ́nì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (46,500). 22  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Síméónì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà lọ́kọ̀ọ̀kan, 23  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Síméónì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kàndínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (59,300). 24  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Gádì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 25  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Gádì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti àádọ́ta (45,650). 26  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Júdà.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 27  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Júdà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́rin ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (74,600). 28  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Ísákà.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 29  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Ísákà jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (54,400). 30  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Sébúlúnì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 31  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Sébúlúnì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (57,400). 32  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù nípasẹ̀ Éfúrémù.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 33  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Éfúrémù jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (40,500). 34  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Mánásè.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 35  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Mánásè jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlélọ́gbọ̀n ó lé igba (32,200). 36  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Bẹ́ńjámínì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 37  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì jẹ́ ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (35,400). 38  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Dánì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 39  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Dánì jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélọ́gọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje (62,700). 40  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Áṣérì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 41  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Áṣérì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mọ́kànlélógójì ó lé ọgọ́rùn-ún márùn-ún (41,500). 42  Wọ́n fi orúkọ wọn, ìdílé wọn àti agbo ilé bàbá wọn to àwọn àtọmọdọ́mọ Náfútálì.+ Gbogbo ọkùnrin tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè, tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun ni wọ́n kà, 43  iye àwọn tí wọ́n sì forúkọ wọn sílẹ̀ nínú ẹ̀yà Náfútálì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́tàléláàádọ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (53,400). 44  Èyí ni àwọn tí Mósè pẹ̀lú Áárónì àti àwọn ìjòyè méjìlá (12) Ísírẹ́lì forúkọ wọn sílẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣojú fún agbo ilé bàbá rẹ̀. 45  Gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹni ogún (20) ọdún sókè tó lè dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì ni wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ bí wọ́n ṣe wà nínú agbo ilé bàbá wọn, 46  gbogbo àwọn tí wọ́n forúkọ wọn sílẹ̀ sì jẹ́ ọgbọ̀n ọ̀kẹ́ ó lé ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ààbọ̀ àti àádọ́ta (603,550).+ 47  Àmọ́ wọn ò forúkọ àwọn ọmọ Léfì+ sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn yòókù bí wọ́n ṣe wà nínú ẹ̀yà bàbá+ wọn. 48  Jèhófà wá sọ fún Mósè pé: 49  “Ẹ̀yà Léfì nìkan ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ forúkọ wọn sílẹ̀, má sì kà wọ́n mọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì+ yòókù. 50  Kí o yan àwọn ọmọ Léfì láti máa bójú tó àgọ́ Ẹ̀rí+ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ pẹ̀lú gbogbo ohun tó jẹ́ ti àgọ́ náà.+ Kí wọ́n máa gbé àgọ́ ìjọsìn náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,+ kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀,+ kí wọ́n sì pàgọ́ yí àgọ́ ìjọsìn+ náà ká. 51  Nígbàkigbà tí ẹ bá fẹ́ kó àgọ́ ìjọsìn náà kúrò,+ àwọn ọmọ Léfì ni kó tú u palẹ̀; tí ẹ bá sì fẹ́ to àgọ́ ìjọsìn náà pa dà, àwọn ọmọ Léfì ni kó tò ó; tí ẹnikẹ́ni tí kò lẹ́tọ̀ọ́* bá sún mọ́ ọn, ṣe ni kí ẹ pa á.+ 52  “Kí ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan pa àgọ́ rẹ̀ sí ibi tí wọ́n yàn fún un, ọkùnrin kọ̀ọ̀kan níbi tí wọ́n pín àwọn ẹ̀yà sí ní mẹ́ta-mẹ́ta,*+ ní àwùjọ-àwùjọ.* 53  Kí àwọn ọmọ Léfì sì pàgọ́ yí àgọ́ Ẹ̀rí ká, kí n má bàa bínú sí àpéjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì;+ àwọn ọmọ Léfì ni kó máa bójú tó* àgọ́ ìjọsìn Ẹ̀rí+ náà.” 54  Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe gbogbo ohun tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́.

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “àwọn ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.”
Tàbí “ní orí ò jorí.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Ní Héb., “àjèjì kankan,” ìyẹn ẹni tí kì í ṣe ọmọ Léfì.
Tàbí “tí àmì (àsíá) rẹ̀ wà.”
Ní Héb., “ẹgbẹ́ ọmọ ogun kọ̀ọ̀kan.”
Tàbí “ṣọ́; ṣiṣẹ́ ní.”