Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 1

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 1

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Ló Yẹ Kí N Mọ̀ Nípa Ìkànnì Àjọlò Orí Íńtánẹ́ẹ̀tì?—Apá 1

“Mo ní àwọn ọ̀rẹ́ láwọn orílẹ̀-èdè míì, ọ̀nà tó sì dáa jù tí mo ronú pé a lè máa gbà kàn sí ara wa ni pé ká jọ máa sọ̀rọ̀ lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Inú mi dùn pé mo lè máa bá wọn sọ̀rọ̀, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ibi tí wọ́n wà jìnnà gan-an.”—Sue, ọmọ ọdún 17. a

“Èrò tèmi ni pé bí ẹni ń fàkókò ṣòfò lásán ni kéèyàn máa lọ sí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn ọ̀lẹ ló máa ń gbé orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wá ọ̀rẹ́. Tí èèyàn bá fẹ́ ní ọ̀rẹ́ gidi, kò sóhun tá a lè fi wé ká báni sọ̀rọ̀ lójúkojú.”—Gregory, ọmọ ọdún 19.

ÈWO nínú èrò méjì yìí ni ìwọ fara mọ́? Èyí tó wù kó o fara mọ́ nínú méjèèjì, ohun kan tó dájú ni pé: Ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń lò kárí ayé. b Ronú nípa èyí ná: Ó tó ọdún méjìdínlógójì [38] tí wọ́n ti ṣe rédíò, kó tó di pé àwọn èèyàn tí ó tó àádọ́ta [50] mílíọ̀nù bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó, ó tó ọdún mẹ́tàlá káwọn èèyàn tó ń lo tẹlifíṣọ̀n tí ó tó iye yẹn, ó sì tó ọdún mẹ́rin kí àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì tó tó bẹ́ẹ̀. Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, láàárín oṣù méjìlá péré, àwọn èèyàn tó ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó ń jẹ́ Facebook ti tó ọgọ́rùn-ún méjì [200] mílíọ̀nù!

Fi àmì sí òótọ́ tàbí irọ́ níwájú gbólóhùn yìí:

Àwọn ọ̀dọ́ tí kò tíì pé ọmọ ogún [20] ọdún ló pọ̀ jù lára àwọn tó ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. ․․․․․ Òótọ́ ․․․․․ Irọ́

Ìdáhùn: Irọ́. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdá méjì nínú mẹ́ta àwọn tó ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] tàbí tí wọ́n ti jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lọ́dún 2009, àwọn tó pọ̀ jù lára àwọn tó ń lo ìkànnì yìí ti lé lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́ta [55]!

Síbẹ̀ náà, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọ̀dọ́ ló ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé ọ̀nà yìí ni wọ́n yàn láàyò láti báni sọ̀rọ̀. Ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jessica sọ pé: “Nígbà kan, mi ò lo ìkànnì yìí mọ́, àmọ́ nígbà tí mo rí i pé kò sẹ́ni tó ń pè mí lórí tẹlifóònù, ńṣe ni mo tún pa dà síbẹ̀. Ńṣe ló máa dà bíi pé àwọn èèyàn ti gbàgbé ẹ tí o kò bá sí lórí ìkànnì àjọlò!”

Kí ló mú káwọn èèyàn máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ohun tó fà á ni pé: Ìwà àwa èèyàn ni láti máa bá ara wa sọ̀rọ̀. Ohun tí àwọn èèyàn sì máa ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì gan-an nìyẹn. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó lè mú kí àwọn kan máa lo ìkànnì náà.

1. Ó rọrùn láti lò.

“Ó máa ń ṣòro láti máa mọ bí nǹkan ṣe ń lọ sí fún gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ tí èèyàn ní, àmọ́ bí gbogbo wọn bá wà lórí ìkànnì kan, ó máa ń rọrùn!”—Leah, ọmọ ọdún 20.

“Tí mo bá kọ ọ̀rọ̀ kan sórí ìkànnì àjọlò, ó máa dà bíi pé ńṣe ni mo kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ́kọ̀ọ̀kan.”—Kristine, ọmọ ọdún 20.

2. Ṣohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe.

“Gbogbo ìgbà ni àwọn kan máa ń pè mí pé kí èmi náà wá di ọ̀rẹ́ àwọn lórí ìkànnì àjọlò, àmọ́ èmi kò sí lórí ìkànnì àjọlò kankan, torí náà kò ṣeé ṣe fún mi láti di ọ̀rẹ́ wọn.”—Natalie, ọmọ ọdún 18.

“Bí mo bá sọ fún àwọn èèyàn pé mi ò fẹ́ lo ìkànnì àjọlò, ńṣe ni wọ́n máa ń wò mí bíi pé, ‘Nǹkan kan ń ṣe mí.’”—Eve, ọmọ ọdún 18.

3. Ohun táwọn ilé ìṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde ń sọ.

“Àwọn ilé iṣẹ́ tó ń gbé ìròyìn jáde máa ń jẹ́ kí àwọn èèyàn gbà pé, téèyàn ò bá máa lo onírúurú àwọn ọ̀nà ìgbàlódé láti máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní lọ́rẹ̀ẹ́. Ẹni tí kò bá sì ní àwọn ọ̀rẹ́ kò rí ayé wá. Torí náà, tó bá jẹ́ pé o kì í lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, a jẹ́ pé o kò já mọ́ nǹkan kan nìyẹn.”—Katrina, ọmọ ọdún 18.

4. Ilé ìwé.

“Àwọn olùkọ́ mi máa ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn kan máa ń fi ìsọfúnni síbẹ̀ láti jẹ́ ká mọ ìgbà tá a máa ṣe ìdánwò. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé mi ò lóye ohun kan nínú ìṣirò, mo lè kọ ọ̀rọ̀ sí olùkọ́ mi lórí ìkànnì náà, ó sì máa bá mi yanjú ìṣòro náà látorí ìkànnì náà.”—Marina, ọmọ ọdún 17.

5. Iṣẹ́.

“Àwọn tó ń wáṣẹ́ máa ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì láti mọ àwọn èèyàn. Nígbà míì, irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè bá wọn wá iṣẹ́.”—Amy, ọmọ ọdún 20.

“Mo máa ń lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì fún iṣẹ́ mi. Ó máa ń jẹ́ kí àwọn oníbàárà mi mọ iṣẹ́ tí mò ń ṣe lọ́wọ́.”—David, ọmọ ọdún 21.

Ǹjẹ́ o yẹ kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Tó o bá ṣì wà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ, àwọn ló máa pinnu ìyẹn. c (Òwe 6:20) Bí àwọn òbí rẹ kò bá fẹ́ kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, o ní láti fara mọ́ ohun tí wọ́n fẹ́.—Éfésù 6:1.

Àwọn òbí kan máa ń gbà kí àwọn ọmọ wọn tó ti dàgbà díẹ̀ máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, wọ́n sì máa ń bojú tó bí wọ́n ṣe ń lò ó. Tó bá jẹ́ pé àwọn òbí rẹ máa ń fẹ́ mọ bí o ṣe ń lo ìkànnì àjọlò, ǹjẹ́ o rò pé ńṣe ni wọ́n ń tojú bọ àṣírí rẹ? Má ṣe rò bẹ́ẹ̀ o! Ìkànnì àjọlò orí íńtánẹ́ẹ̀tì wúlò gan-an ni, àmọ́ ó tún ní àwọn ewu tirẹ̀, torí náà, ọ̀nà tí ò ń gbà lò ó gbọ́dọ̀ jẹ àwọn òbí rẹ lógún. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, bó ṣe jẹ́ pé ìkànnì àjọlò òrí Íńtánẹ́ẹ̀tì ní àwọn ewu tirẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ewu ṣe wà nínú ọ̀nà èyíkéyìí tí èèyàn lè gbà lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Bí àwọn òbí rẹ bá gbà kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, báwo lo ṣe lè yẹra fún àwọn ewu tó wà níbẹ̀?

“Wakọ̀” Jẹ́jẹ́

Láwọn ọ̀nà kan, a lè fi lílo Íńtánẹ́ẹ̀tì wé wíwa ọkọ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìwọ náà ti kíyè sí i pé, kì í ṣe gbogbo awakọ̀ tó ní ìwé ẹ̀rí ìwakọ̀ ló ṣeé gbára lé. Kódà, jàǹbá ọkọ̀ tó burú jáì ti ṣẹlẹ̀ sí ọ̀pọ̀ èèyàn torí pé wọn kò bìkítà tàbí pé wọn ṣàìka ìkìlọ̀ sí.

Bí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì náà ṣe rí nìyẹn. Àwọn kan máa ń “wakọ̀” jẹ́jẹ́; àwọn kan sì máa ń “wakọ̀” níwàkuwà. Bí àwọn òbí rẹ bá gbà kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ńṣe ni wọ́n fọkàn tán ẹ́ pé wàá máa fi ìṣọ́ra lo ìkànnì tó léwu yìí. Torí náà, irú “awakọ̀” wo ni wọ́n mọ̀ ẹ́ sí? Ǹjẹ́ o ti fi hàn pé ò ń “fi ìṣọ́ ṣọ́ ọgbọ́n tí ó gbéṣẹ́ àti agbára láti ronú”?—Òwe 3:21.

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa sọ̀rọ̀ nípa apá méjì tó yẹ kó o ronú lé lórí nípa ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Àwọn apá náà ni, àṣírí rẹ àti àkókò rẹ. Àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” míì nínú ìtẹ̀jáde yìí máa sọ̀rọ̀ nípa irú ojú tí àwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́ àti àwọn tó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́.

ÀṢÍRÍ RẸ

O lè má ronú kàn án pé ó yẹ kó o ṣe àwọn ohun kan láṣìírí tó bá dọ̀rọ̀ lílo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ó ṣe tán, ohun tó wà fún ni pé kó o máa fi kàn sí àwọn èèyàn. Síbẹ̀ náà, tí o kò bá ṣọ́ra, èyí lè kó ẹ sí wàhálà.

Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o ní owó tabua kan lọ́wọ́. Ṣé wàá gbé owó náà lọ́nà tí gbogbo èèyàn á fi lè rí i bí ìwọ àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ṣe ń rìn lọ lójú pópó? Ìwà òmùgọ̀ nìyẹn máa jẹ́, torí pé ńṣe nìyẹn dà bí ìgbà tí ò ń fúnra rẹ sọ pé kí àwọn èèyàn wá jà ẹ́ lólè! Tó o bá gbọ́n, ńṣe lo máa tọ́jú owó rẹ sí ibi táwọn èèyàn kò ti ní rí i.

Fojú wò ó bíi pé owó ni àwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ́ àṣírí ara rẹ. Bó o ṣe ń ronú nípa rẹ̀, wo àwọn ohun tá a kọ sí ìsàlẹ̀ yìí, kó o sì fi àmì sí àwọn ohun tí o kò ní fẹ́ sọ fún ẹnì tí o kò mọ̀ rárá.

․․․․․ àdírẹ́sì ilé mi

․․․․․ àdírẹ́sì tí mo fi ń gba lẹ́tà lórí kọ̀ǹpútà

․․․․․ ilé ìwé tí mò ń lọ

․․․․․ àkókò tí mo máa ń wà nílé

․․․․․ ìgbà tí kì í sí ẹnì kankan nílé

․․․․․ fọ́tò mi

․․․․․ ohun tí mò ń rò

․․․․․ àwọn ohun tí mo nífẹ̀ẹ́ sí

Kódà, tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé ìwọ ni ara rẹ̀ yọ̀ mọ́ èèyàn jù lọ láyé, ó ṣeé ṣe kó o gbà pé àwọn kan wà nínú ohun tó wà lókè yìí tí o kò ní fẹ́ kí àwọn kan mọ̀. Àmọ́, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ àti àwọn àgbàlagbà míì ti fún àwọn tí wọn kò tiẹ̀ mọ̀ rárá ní irú àwọn ìsọfúnni bẹ́ẹ̀ láìmọ! Báwo ni o kò ṣe ní kó sínú irú ìṣòro yìí?

Bí àwọn òbí rẹ bá gbà kó o máa lo ìkànnì àjọlò, ó yẹ kó o fara balẹ̀ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ètò kan tó máa ń wà níbẹ̀, èyí tó wà fún pípa àṣírí mọ́, kó o sì máa lò ó láti pa àṣírí rẹ mọ́. Má ṣe rò pé ìkànnì náà ni yóò máa bá ẹ pa àṣírí rẹ mọ́ o. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, ńṣe ni ètò tí wọ́n ṣe sórí ìkànnì náà máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ rí ibi tí ò ń lò lórí ìkànnì náà, kí wọ́n sì kọ ọ̀rọ̀ síbẹ̀. Ìdí nìyẹn tí ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Allinson fi ṣe ohun tí kò ní jẹ́ kí àwọn míì tó yàtọ̀ sí àwọn ọ̀rẹ́ tó sún mọ́ ọn gan-an máa rí ohun tó bá kọ. Ó sọ pé: “Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi ní àwọn ọ̀rẹ́ tí mi ò mọ̀, mi ò sì fẹ́ kí àwọn tí mi ò mọ̀ rí yẹn máa ka ìsọfúnni tí mo kọ nípa ara mi.”

Tó bá tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó sún mọ́ ẹ gan-an nìkan lò ń bá sọ̀rọ̀, o ṣì ní láti ṣọ́ra. Corrine tó jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sọ pé: “Gbígba ọ̀rọ̀ látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ lè wá di bárakú fún ẹ débi pé, wàá bẹ̀rẹ̀ sí í fí ọ̀pọ̀ ìsọfúnni nípa ara rẹ síbẹ̀ kọjá bó ṣe yẹ.”

Rántí pé Íńtánẹ́ẹ̀tì kì í ṣe ibi téèyàn lè fi àṣírí pa mọ́ sí. Kí nìdí? Nínú ìwé CyberSafe, tí ọ̀gbẹ́ni Gwenn Schurgin O’Keeffe ṣe, ó sọ pé: “Àwọn ìkànnì ńlá máa ń ṣe ẹ̀dà àwọn ìsọfúnni tí àwọn èèyàn bá fi sórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tí èèyàn bá sì fi síbẹ̀ kì í kúrò níbẹ̀. Ohun tó bá ti wọ ibẹ̀ kò tún lè jáde mọ́, torí pé ó ṣeé ṣe kí ẹ̀dà rẹ̀ wà ní ibì kan; òmùgọ̀ èèyàn ló máa sọ pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀.”

ÀKÓKÒ RẸ

Yàtọ̀ sí àwọn àṣírí rẹ, a tún lè fi àkókò rẹ wé owó tabua kan. Ó yẹ kó o ṣètò àkókò rẹ dáadáa. (Oníwàásù 3:1) Ìṣòro ńlá lèyí sì máa ń jẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ lílo apá èyíkéyìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tó fi mọ́ lílo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì. d

“Mo sábà máa ń sọ pé, ‘Mi ò ní lò ju ìṣẹ́jú kan péré lọ.’ Àmọ́ lẹ́yìn wákàtí kan, mo ṣì máa wà níbẹ̀.”—Amanda, ọmọ ọdún 18.

“Ó ti di bárakú fún mi. Gbogbo ìgbà tí mo bá ti dé láti iléèwé, mo máa ń fi ọ̀pọ̀ wákàtí ka ohun táwọn èèyàn sọ nípa ohun tí mo kọ síbẹ̀ àti ohun tí àwọn náà kọ.”—Cara, ọmọ ọdún 16.

“Mo lè wo ìkànnì náà látorí fóònù mi, torí náà mo máa ń wò ó tí mo bá ń lọ sí iléèwé, nígbà tí mo bá wà ní iléèwé, àti nígbà tí mo bá ń bọ̀ láti iléèwé. Tí mo bá wá pa dà délé, máà wá lọ sídìí kọ̀ǹpútà. Mo mọ̀ pé ó ti di bárakú fún mi, àmọ́ mi ò fẹ́ jáwọ́ nínú rẹ̀.”—Rianne, ọmọ ọdún 17.

Bí àwọn òbí rẹ bá gbà kó o máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ronú nípa bí àkókò tó bọ́gbọ́n mu pé kó o máa lò lórí rẹ̀ lọ́jọ́ kan ṣe yẹ kó pọ̀ tó, kó o sì pinnu iye àkókò tí wàá fi máa lò ó. Lẹ́yìn náà, máa ṣàkíyèsí ara rẹ. Fún oṣù kan, wo iye àkókò tó o lò lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, kó o sì wò ó bóyá o kò tíì kọjá iye àkókò tó o pinnu pé wàá máa lò. Má ṣe gbàgbé pé, ńṣe ni àkókò rẹ dà bí owó. Torí náà má ṣe jẹ́ kí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì jà ẹ́ ní olè àkókò. Ó ṣe tán, àwọn ohun kan wà tó ṣe pàtàkì jù!—Éfésù 5:15, 16; Fílípì 1:10.

Àwọn ọ̀dọ́ kan ti ṣe ohun tí kì í jẹ́ kí wọ́n fi àkókò wọn ṣòfò. Gbé àwọn àpẹẹrẹ yìí yẹ̀ wò:

“Mo yọ orúkọ mi kúrò lórí ìkànnì náà, mo sì wá rí i pé mo ní àkókò tó pọ̀ sí i. Mo wá ní òmìnira! Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó pa dà, àmọ́ mi ò kì í lò kọjá àkókò tí mo ti pinnu. Nígbà míì, mi ò kì ń lọ sórí ìkànnì náà fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Mo tiẹ̀ máa ń gbàgbé rẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bí ìkànnì náà bá tún di ìṣòro fún mi, màá tún yọ orúkọ mi kúrò níbẹ̀.”—Allison, ọmọ ọdún 19.

“Mo máa ń gba ìsinmi lórí ìkànnì náà, nígbà míì mo máa ń yọ orúkọ mi kúrò lórí ìkànnì náà fún oṣù mélòó kan, màá sì tún fi sí i tó bá yá. Ìgbà tí mo bá kíyè sí i pé mo ti ń lo àkókò tó pọ̀ jù ni mo máa ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ní báyìí, kò wọ̀ mí lára bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Ó ní ìdí tí mo fi máa ń lò ó, tí mo bá sì ti ṣe tán, mo kúrò nídìí rẹ̀ nìyẹn.”—Anne, ọmọ ọdún 22.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

Nǹkan míì tún ṣì wà nípa ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó yẹ kó o ronú nípa rẹ̀. Kó o lè mọ nǹkan náà, fi àmì yìí ✔ síwájú ohun tó o rò pé ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wà fún.

Ohun pàtàkì tí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wà fún ni . . .

(A) ․․․․․ iṣẹ́ ajé.

(B) ․․․․․ kíkẹ́gbẹ́.

(D) ․․․․․ ṣíṣeré ìnàjú.

Ìdáhùn wo ló tọ̀nà? Bóyá o gbà bẹ́ẹ̀ àbí o kò gbà, “A” ló tọ̀nà. Iṣẹ́ ajé ni ohun pàtàkì tí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì wà fún. Ìdí tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ ni kí wọ́n lè jèrè látara ìpolówó ọjà. Ní ti àwọn tó ń polówó ọjà, ìkànnì náà á túbọ̀ níye lórí sí i, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe ń lò ó, tí wọ́n ń fi ọ̀rọ̀ síbẹ̀ tí wọ́n sì jọ ń ṣàjọpín àwọn ìsọfúnni náà. Ó ṣe tán, bí àkókò tí ìwọ tàbí ẹnikẹ́ni mìíràn bá lò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì bá ṣe pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ìpolówó ọjà tó o máa wò á ṣe pọ̀ tó.

Bó o ṣe ti wá mọ èyí á jẹ́ kó o mọ̀ pé tó o bá ń fún àwọn èèyàn ní ìsọfúnni tó pọ̀ jù nípa ara rẹ tàbí tí ò ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí Íńtánẹ́ẹ̀tì, àwọn tó ni ìkànnì náà kì í pàdánù, àwọn tó sì ń polówó ọjà máa jèrè gan-an. Torí náà, tó o bá tiẹ̀ máa lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, rí i dájú pé o pa àṣírí ara rẹ mọ́, kó o sì máa kíyè sí iye àkókò tí ò ń lò.

NÍNÚ ÀPILẸ̀KỌ “ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ” TÓ KÀN

A máa jíròrò bí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣe lè nípa lórí ojú tí àwọn èèyàn á fi máa wò ẹ́ àti àwọn tó o yàn lọ́rẹ̀ẹ́. Jẹ́ ká wò ó.

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.watchtower.org/ype

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

b Ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni ìkànnì tí èèyàn ti lè forúkọ sílẹ̀ láti máa bá àwọn ọ̀rẹ́ tó bá yàn sọ̀rọ̀.

c Ìwé ìròyìn Jí! kò sọ pé ìkànnì kan ló dáa kò sì sọ pé àwọn kan kò dáa. Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ rí i dájú pé bí àwọn ṣe ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì kò ta ko ìlànà Bíbélì kankan.—1 Tímótì 1:5, 19.

d Fún ìsọfúnni síwájú sí i, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé . . . Ṣé Mo Ti Sọ Àwọn Ohun Tó Ń Gbé Ìsọfúnni Jáde Di Bárakú?” nínú Jí! April–June 2011. Kó o sì túbọ̀ kíyè sí ìsọfúnni tó wà nínú àpótí tó wà lójú ìwé 26, ìyẹn “Ìkànnì Táwọn Èèyàn Ti Ń Fọ̀rọ̀ Jomi Toro Ọ̀rọ̀ Lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì Di Bárakú fún Mi.”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Ó tó ọdún méjìdínlógójì [38] tí wọ́n ti ṣe rédíò kó tó di pé àwọn èèyàn tí ó tó àádọ́ta [50] mílíọ̀nù bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Ìwádìí kan lẹ́nu láìpẹ́ yìí fi hàn pé, láàárín ọdún kan àwọn èèyàn tó bẹ̀rẹ̀ sí í lo ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn Facebookọgọ́rùn-ún méjì [200] mílíọ̀nù

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 19]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Bá àwọn òbí rẹ sọ̀rọ̀ nípa bí o ṣe lè pa àṣírí mọ́ nígbà tó o bá ń lo Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí làwọn ohun tó yẹ kéèyàn pa mọ́ láṣìírí, kí sì nìdí? Àwọn ìsọfúnni wo ló léwu téèyàn bá fi sí apá èyíkéyìí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Bákan náà, ní kí àwọn òbí rẹ fún ẹ ní ìmọ̀ràn lórí bí o kò ṣe ní jẹ́ kí bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ṣàkóbá fún sísọ̀rọ̀ lójúkojú. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n rò pé ó yẹ kó o ṣiṣẹ́ lé lórí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Má ṣe rò pé àṣírí ni àwọn ohun tí ò ń ṣe lórí ìkànnì àjọlò orí Íńtánẹ́ẹ̀tì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ńṣe ni owó dà bí àkókò. Tó o bá ń fi àkókò rẹ ṣòfò, o lè má ní àkókò tó pọ̀ tó nígbà tó o bá nílò rẹ̀