Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Mo Lè Máa Retí Tá A Bá Di Tọkọtaya?—Apá Kìíní

Kí Ni Mo Lè Máa Retí Tá A Bá Di Tọkọtaya?—Apá Kìíní

Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé

Kí Ni Mo Lè Máa Retí Tá A Bá Di Tọkọtaya?​—Apá Kìíní

“Tí mo bá ti wà lọ́dọ̀ ẹ̀ báyìí, ṣe ni inú mi máa ń dùn ṣìnkìn! Ó ń ṣe mí bíi pé ká ti di tọkọtaya!”

“Ọ̀rọ̀ wa ò tiẹ̀ wọ̀ rárá. Ṣe la kàn jọ ń gbénú ilé, a ò tiẹ̀ jọ gbé bíi tọkọtaya rárá. Ó wá dà bíi pé mò ń dá gbé!”

Ó ṢEÉ ṣe kó o rò pé ọ̀dọ́bìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ ló sọ ọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí, àti pé ẹnì kan tó ti ṣèyàwó ló sọ̀rọ̀ tó wà lápá òsì yìí. Àmọ́, ohun kan tó lè yà ẹ́ lẹ́nu ni pé ẹnì kan náà ló sọ ọ̀rọ̀ méjèèjì.

Kí ló lè mú kó sọ irú ọ̀rọ̀ yìí? Tó o bá ń ronú láti níyàwó tàbí ọkọ lọ́jọ́ iwájú, báwo lo ṣe lè máa ronú lọ́nà tó tọ́ nípa ọjọ́ iwájú ẹ̀yin méjèèjì kí ìṣòro má bàa dá wàhálà sílẹ̀ láàárín yín?

Òótọ́ ọ̀rọ̀: Ohun tó o bá ń retí lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá di tọkọtaya ló máa pinnu bó o ṣe máa láyọ̀ tó nígbà tó o bá ní ọkọ tàbí aya.

Àpilẹ̀kọ yìí àti àpilẹ̀kọ míì nínú abala “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” èyí tó máa jáde nínú ìwé ìròyìn Jí! tó máa tẹ̀ lé èyí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní èrò tó tọ́ nípa ohun tó o lè máa retí lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá di tọkọtaya.

Kí làwọn ohun tó yẹ kó o máa retí lẹ́yìn tẹ́ ẹ bá fẹ́ra? Ká má fọ̀rọ̀ gùn, o lè máa:

(1) Retí pé àǹfààní máa wà

(2) Retí pé ìṣòro máa wà

(3) Retí àwọn nǹkan míì tí o kò ronú kàn tẹ́lẹ̀

Jẹ́ ká wá gbé àwọn nǹkan yìí yẹ̀ wò dáadáa.

RETÍ PÉ ÀǸFÀÀNÍ MÁA WÀ

Bíbélì jẹ́ ká ní èrò tó dáa nípa ìgbéyàwó. (Òwe 18:22) Díẹ̀ lára àwọn àǹfààní tó o lè máa retí rèé.

Rírí ẹni bá kẹ́gbẹ́. Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́, Ọlọ́run sọ pé: “Kò dára kí ọkùnrin náà máa wà nìṣó ní òun nìkan,” lẹ́yìn náà Ó dá Éfà, ó sì fi ṣe ẹnì kejì fún Ádámù. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Ọlọ́run dá ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn pẹ̀lú ìwà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ kí wọ́n lè yàtọ̀ síra, àmọ́ lọ́nà tí wọ́n á fi lè gbé pa pọ̀. Torí náà, tọkọtaya jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ rere fún ara wọn.—Òwe 5:18.

Jíjẹ́ ẹnì kejì fún ara yín. Bíbélì sọ pé: “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn.” (Oníwàásù 4:9) Bí ọ̀rọ̀ tọkọtaya ṣe rí nìyẹn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Brenda, a tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣè ìgbéyàwó sọ pé: “Tọkọtaya gbọ́dọ̀ mọwọ́ ara wọn, kí wọ́n jọ máa ṣe àwọn nǹkan pa pọ̀, kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ tó múra tán láti gba nǹkan mọ́ra fún ara wọn lẹ́nì-kìíní-kejì.”

Àjọṣe tímọ́tímọ́. Bíbélì sọ pé: “Ki ọkọ máa fún aya rẹ̀ ni ẹ̀tọ́-ìgbéyàwó rẹ̀: bẹẹ gẹ́gẹ́ sì ni aya pẹ̀lú si ọkọ.” (1 Kọ́ríńtì 7:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Tó o bá ṣe ìgbéyàwó, o lè gbádùn ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹnì kejì rẹ láìsí pé ò ń fòyà tàbí pé ò ń kábàámọ̀ bíi ti àwọn tó ń bá ara wọn lòpọ̀ láìṣe ìgbéyàwó.—Òwe 7:22, 23; 1  Kọ́ríńtì 7:8, 9.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni ìgbéyàwó jẹ́. (Jákọ́bù1:17) Tó o bá ń fi àwọn ìlànà Ọlọ́run sílò, o lè retí pé wàá ṣe àṣeyọrí tó o bá níyàwó tàbí ọkọ, wàá sì gbádùn ìgbésí ayé.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé àpẹẹrẹ àwọn ìgbéyàwó tó ti forí ṣánpọ́n, bóyá nínú ìdílé yín, ti mú kó o máa rò pé ìgbéyàwó lè má yọrí sí rere. Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn àpẹẹrẹ àtàtà tó ṣeé fara wé wo lo lè ronú lé?

RETÍ PÉ ÌṢÒRO MÁA WÀ

Bíbélì sọ òótọ́ ọ̀rọ̀ nípa ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ láàárín tọkọtaya. (1 Kọ́ríńtì 7:28) Díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó o lè máa retí rèé.

Àìgbọ́ra-ẹni-yé. Kò sẹ́ni méjì tí ìwà wọn dọ́gba láìkù síbì kan, ohun kan tó dájú ni pé aláìpé ni gbogbo èèyàn. (Róòmù 3:23) Torí náà, kò sí bí tọkọtaya kan ṣe lè wà tí èdèkòyédè kò ní máa wáyé láàárín wọn lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Kódà wọ́n lè sọ ọ̀rọ̀ tí wọ́n á pa dà wá kábàámọ̀ rẹ̀ sí ara wọn nígbà míì. Bíbélì sọ pé: “Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé.” (Jákọ́bù 3:2) Kò sí ọgbọ́n tá a lè dá tí àìgbọ́ra-ẹni-yé kò fi ní máa ṣẹlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ohun tó dáa jù ni pé kí tọkọtaya mọ bí wọ́n ṣe lè yanjú ìṣòro wọn ní ìtùnbí ìnùbí.

Ìjákulẹ̀. Ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Karen sọ pé: “Àwọn ohun tí wọ́n sábà máa ń gbé jáde nínú Tẹlifíṣọ̀n àti fíìmù ni bí ọmọbìnrin kan ṣe rí ọkùnrin tó dáa fẹ́, tí wọ́n sì jọ ń gbé pa pọ̀ láìsí ìṣòro kankan.” Àmọ́ lójú ayé, tí ọ̀rọ̀ kò bá wá rí bẹ́ẹ̀ láàárín tọkọtaya, ìjákulẹ̀ ló máa ń yọrí sí. Ó dájú pé lẹ́yìn tí wọ́n bá fẹ́ra, kò sí bí tọkọtaya kò ṣe ní máa rí àwọn nǹkan kan nípa ara wọn tó kù díẹ̀ káàtó. Ohun tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n máa rántí pé ìfẹ́ tòótọ́ “a máa fara da ohun gbogbo,” títí kan ìjákulẹ̀.—1 Kọ́ríńtì 13:4, 7.

Àníyàn. Bíbélì sọ pé àwọn tó gbéyàwó ń “ṣàníyàn fún àwọn ohun ti ayé.” (1 Kọ́ríńtì 7:33, 34) Kò sí ohun tó burú nínú irú àníyàn bẹ́ẹ̀, ohun tó yẹ kó o retí pé ó máa ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣòro láti rówó gbọ́ bùkátà. Ó sì lè pọn dandan pé kí tọkọtaya máa ṣiṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kí wọ́n lè rówó ra oúnjẹ àti aṣọ, kí wọ́n sì lè san owó ilé. Àmọ́, ẹ lè ṣàṣeyọrí tẹ́ ẹ bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti gbọ́ bùkátà ìdílé yín.—1 Tímótì 5:8.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Bí wíwa kẹ̀kẹ́ ṣe yàtọ̀ sí wíwa mọ́tò, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbà tẹ́ni méjì ń fẹ́ra sọ́nà ṣe yàtọ̀ sí ìgbà tí wọ́n bá di tọkọtaya. Ó máa nílò pé kí o túbọ̀ sapá, kó o sì mọ bó o ṣe lè máa yanjú àwọn ìṣòro tí àìgbọ́ra-ẹni-yé máa ń fà. Ṣùgbọ́n fọkàn balẹ̀ pé wàá ṣàṣeyọrí.

Ohun tó yẹ kó o ronú lé:lo máa ń ṣe tí àìgbọ́ra-ẹni-yé bá wáyé láàárín ìwọ àti òbí, àbúrò tàbí ẹ̀gbọ́n rẹ? Tí ẹnì kan bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an, ṣé o lè gbàgbé ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ náà sì tán lọ́kàn rẹ? Kí lo máa ń ṣe tí ọ̀rọ̀ kan bá ń jẹ ọ́ lọ́kàn?

NÍNÚ “ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ” TÓ TẸ̀ LÉ E . . . Báwo làwọn ìlànà Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa retí àwọn nǹkan míì tí o kò ronú kàn tẹ́lẹ̀?

O lè ka púpọ̀ sí i nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ “Àwọn Ọ̀dọ́ Béèrè Pé” nínú ìkànnì wa lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ìyẹn www.dan124.com

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

OHUN TÁWỌN OJÚGBÀ Ẹ SỌ

Brittany—Ní tèmi, mo rò pé kì í ṣe ohun tó bọ́gbọ́n mu rárá pé kéèyàn kàn lọ ṣègbéyàwó torí pé ó ti sú u bí àwọn èèyàn ṣe ń bí i pé, “Ìgbà wo lo máa gbéyàwó?” Ó ṣe tán, tí ìṣòro bá délẹ̀ tán, ìwọ fúnra ẹ ni wàá máa bá nǹkan ẹ yí, kì í ṣe àwọn tó ń fúngun mọ́ ẹ pé kó o ṣègbéyàwó.

Ciara—Bọ́rọ̀ bá ṣe rí lára èèyàn nígbà míì lè ṣàkóbá fún béèyàn ṣe ń ronú. Ìdí nìyẹn ti mo fi rò pé ó yẹ kí àwọn òbí lọ́wọ́ nínú ìpinnu tí àwọn ọmọ bá máa ṣe nípa yíyan ẹni tí wọ́n máa fẹ́. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó mọ ọmọ bí àwọn òbí rẹ̀, torí náà ó yẹ kí àwọn òbí ran ọmọ wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè wá ẹni tó dáa fẹ́.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

KÍ NI ÌWỌ RÒ?

Ọmọkùnrin kan tó ń jẹ́ Josh àti ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Melanie ti jọ ń fẹ́ra wọn bọ̀ fún ọdún kan báyìí. Láàárín ìgbà yẹn, ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni àárín wọn ti fẹ́ dà rú. Àkọ́kọ́ ni ìgbà tí Josh halẹ̀ mọ́ Melanie pé òun kò fẹ́ ẹ mọ́ torí pé ó máa ń bá àwọn ọkùnrin kan tage. Ẹ̀ẹ̀kejì ni ìgbà tí Melanie sọ fún Josh pé òun kò fẹ́ ẹ mọ́ torí pé òun kò lè fara da gbogbo ẹ̀sùn tó máa ń fi kan òun. Nígbà méjèèjì, Josh àti Melanie yanjú ìṣòro tí wọ́n ní yẹn.

Kí ni ìwọ rò? Ìṣòro wo lo rò pé ó lè jẹ yọ lọ́jọ́ iwájú láàárín àwọn méjèèjì? Kí lo rò nípa bí Josh àti Melanie ṣe fẹ́ ja ara wọn jù sílẹ̀ lẹ́ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀? Kí lo rò nípa bí àwọn méjèèjì ṣe yanjú ìṣòro tó wà láàárín wọn? Kí lo rò pé Josh àti Melanie lè máa retí tí wọ́n bá di tọkọtaya?

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

O Ò ṢE BÉÈRÈ LỌ́WỌ́ ÀWỌN ÒBÍ RẸ?

Kí ìwọ àti àwọn òbí rẹ jọ jíròrò àpótí tá a pe akọ́lé rẹ̀ ní “Kí Ni Ìwọ Rò?” Kó o wá wò ó bóyá ohun tí wọ́n rò nípa Josh àti Melanie yàtọ̀ sí ohun tí ìwọ rò.