Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Jésù

Jésù

Ṣé Jésù ni Ọlọ́run?

“Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.”—Jòhánù 1:18.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé Jésù kọ́ ni Ọlọ́run. Síbẹ̀, àwọn míì máa ń tọ́ka sí àwọn ẹsẹ Bíbélì tí wọ́n rò pé ó sọ pé Jésù náà ni Ọlọ́run.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kò sọ pé Jésù ni Ọlọ́run Olódùmarè tàbí pé ó bá Ọlọ́run dọ́gba. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì kọ́ wa pé Ọlọ́run ju Jésù lọ. Bí àpẹẹrẹ, nínú Bíbélì a rí ọ̀rọ̀ tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé: “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 14:28) Bíbélì tún sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Jésù kò lè jẹ́ Ọlọ́run nítorí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló rí Jésù.

Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù kò sọ pé Jésù ni Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, Jòhánù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Ìhìn Rere sọ nípa àkọsílẹ̀ rẹ̀ pé: “Ṣùgbọ́n ìwọ̀nyí ni a ti kọ sílẹ̀ kí ẹ lè gbà gbọ́ pé Jésù ni Kristi Ọmọ Ọlọ́run.”Jòhánù 20:31. a

Ìgbà wo ni wọ́n bí Jésù?

“Àwọn olùṣọ́ àgùntàn . . . ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.”—Lúùkù 2:8.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan máa ń ṣe ayẹyẹ Kérésìmesì ní December 25, ìyẹn ọjọ́ táwọn kan rò pé wọ́n bí Jésù. Apá ìbẹ̀rẹ̀ oṣù January làwọn míì sì máa ń ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì kò sọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Àmọ́, ó sọ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, “àwọn olùṣọ́ àgùntàn . . . ń gbé ní ìta, tí wọ́n sì ń ṣọ́ àwọn agbo ẹran wọn ní òru.” (Lúùkù 2:8) Kò dájú pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn yẹn máa jẹ́ kí àwọn àgùntàn wọn wà níta lóru lóṣù December àti January. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀?

Oṣù December àti January ló máa ń tutù ju lọ láàárín ọdún ní àgbègbè tí wọ́n ti bí Jésù. Bíbélì ṣàlàyé ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ lákòókò yẹn láàárín ọdún, ó sọ pé àwọn èèyàn “ń gbọ̀n nítorí . . . ọ̀wààrà òjò.” (Ẹ́sírà 10:9, 13; Jeremáyà 36:22) Nítorí náà, kò ní jẹ́ irú àkókò yẹn làwọn olùṣọ́ àgùntàn àtàwọn àgùntàn wọn á máa “gbé ní ìta.”

Ṣé òótọ́ ni Jésù jíǹde lẹ́yìn tó kú?

“Ọlọ́run gbé [Jésù] dìde kúrò nínú òkú.”—Ìṣe 3:15.

OHUN TÁWỌN KAN SỌ

Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹni tó bá kú kò lè jíǹde, èyí ló mú kírú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ gbà pé Jésù pàápàá kò jíǹde.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé òun máa ‘jìyà ohun púpọ̀, wọ́n á pa òun, òun á sì dìde ní ọjọ́ kẹta.’ (Mátíù 16:21) Bíbélì sọ pé lẹ́yìn tí wọ́n pa Jésù, tó sì jíǹde, ó fara han àwọn èèyàn tí ó tó ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500]. (1 Kọ́ríńtì 15:6) Ó dá àwọn tó rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde lójú pé lóòótọ́ ló jí dìde. Wọn ò tiẹ̀ kọ̀ láti kú nítorí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ yẹn!—Ìṣe 7:51-60; 12:1, 2.

ÌDÍ TÓ FI ṢE PÀTÀKÌ

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé bí Jésù ṣe kú tó sì jíǹde ló máa mú kó ṣeé ṣe fún gbogbo èèyàn láti jàǹfààní látinú ìlérí tí Bíbélì ṣe pé ayé máa di Párádísè. (Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Ọpẹ́lọpẹ́ ìfẹ́ tí Jésù àti Baba rẹ̀, Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè fi hàn sí wa ló jẹ́ ká nírètí pé a máa gbádùn ayé láìní kú nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 3:16; Róòmù 6:23.

a Bíbélì kò sọ pé Ọlọ́run ní ìyàwó kan tó ń bímọ fún un. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run” nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló dá Jésù, ó sì fi ìwà jọ Bàbá rẹ̀.