Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Báwo La Ṣe Lè Yanjú Aáwọ̀?

Báwo La Ṣe Lè Yanjú Aáwọ̀?

Frank àti Jerry jọ múlé tira, ọ̀rọ̀ àwọn méjèèjì sì wọ̀ dáadáa. Àmọ́ láti ọjọ́ tí Jerry ti ṣe àríyá dòru nínú ilé rẹ̀ ni wàhálà ti dé. a Frank lọ bá a pé ariwo wọn ti pọ̀ jù, ni Jerry bá da ọ̀rọ̀ náà sí ìbínú, ó ní kò yẹ kó bá òun sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Wọ́n ṣáà fa ọ̀rọ̀ yẹn títí. Lọ́rọ̀ kan, wọn ò kíra wọn mọ́ látìgbà náà.

OHUN kan náà ló ń ṣe Frank àti Jerry. Nítorí tí ọ̀rọ̀ bá ṣe bí ọ̀rọ̀ láàárín ẹni méjì, inú lè bí wọn, ẹnì kìíní á sì máa dá ẹnì kejì lẹ́bi. Bí wọn ò bá sì tètè yanjú aáwọ̀ náà, ó lè jẹ́ ibi tí ọ̀rẹ́ wọn máa parí sí nìyẹn.

Ó ṣeé ṣe kí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí. Ó sì dájú pé inú rẹ kì í dùn tó o bá rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ohun kan ni pé, kò sẹ́ni tí kò wù kó máa gbé ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn aládùúgbò rẹ̀. Àmọ́ bí èdèkòyédè bá tiẹ̀ ń wáyé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, kí la lè ṣe kí àlàáfíà lè wà láàárín wa? Ǹjẹ́ a lè gbójú fo ohun tẹ́nì kan ṣe sí wa láìka bó ṣe dùn wá tó, ká sì jẹ́ kó tán nínú wa? Ṣé a lè fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ yanjú èdèkòyédè tó wà láàárín wa?

Tá a bá wo ohun tó ṣẹlẹ̀ láàárín Jerry àti Frank dáadáa, a máa rí i pé nǹkan mẹ́rin ló fa ìjà wọn. (1) Jerry kò gba ti Frank rò nígbà tó dá àríyá sílẹ̀, (2) Frank fìbínú sọ̀rọ̀ sí Jerry, (3) Àwọn méjèèjì dà á sí ìbínú, (4) Àwọn méjèèjì kò fẹ́ gbà.

Lẹ́yìn-ọ-rẹyìn, àwọn méjèèjì fọwọ́ wọ́nú, wọ́n sì ń bá ọ̀rẹ́ wọn nìṣó. Báwo ni wọ́n ṣe yanjú aáwọ̀ náà? Àwọn ìlànà tí wọ́n tẹ̀ lé ló jẹ́ kí wọ́n kẹ́sẹ járí. Irú àwọn ìlànà bẹ́ẹ̀ ti ran ọ̀pọ̀ lọ́wọ́ láti gbádùn ọ̀rẹ́ wọn nígbà dídùn àti nígbà kíkan. Ó sì ti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ àwọn míì túbọ̀ wọ̀ dáadáa.

Inú Bíbélì la ti lè rí irú àwọn ìlànà tí à ń sọ yìí. Ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà sí ẹni tí kò ní Bíbélì. Ẹni tó bá ń fi ohun tó kà nínú rẹ̀ sílò, á jẹ́ èèyàn àlàáfíà, kò sì ní máa ránró. Á tún ní àwọn ìwà míì bí ìfòyemọ̀, ìjìnlẹ̀ òye, inú rere, ìfẹ́ àti sùúrù.—Òwe 14:29; 1 Kọ́ríńtì 13:4, 5.

Ọ̀rọ̀ Frank àti Jerry tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ gbé yẹ̀ wò wulẹ̀ jẹ́ àpẹẹrẹ méjì nínú àwọn èèyàn tó ti rí agbára Bíbélì láyé wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì ti tún ayé wọn ṣe, pàápàá àwọn kan tí ìwà tí ò dáa ti mọ́ lára. Bí àpẹẹrẹ, Robert tó ń gbé ní Ọsirélíà máa ń bínú gan-an tẹ́lẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, ó di onínú tútù. Bẹ́ẹ̀ náà ni Nelson tó ń gbé nílùú Timor-Leste, ó pa dà di ọ̀rẹ́ pẹ̀lú ẹnì kan tó ń bá ṣọ̀tá láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Báwo ni Bíbélì ṣe ran Robert àti Nelson lọ́wọ́? Àwọn tó ń kọ ìwé ìròyìn Jí! fi ọ̀rọ̀ wá àwọn méjèèjì lẹ́nu wò.

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ 1

Arákùnrin ROBERT, ẹ sọ díẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe tọ́ yín dàgbà.

Ṣé ẹ rí i, ìdílé wa ò láyọ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ rí. Èèyàn líle ni bàbá mi, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì máa ń nà mí. Lọ́jọ́ kan, ó lù mí títí gbogbo ara mi fi bẹ́jẹ̀, mo sì dá kú. Ohun tó sọ mi di èèyàn líle nìyẹn tí èmi náà fi máa ń bínú lódìlódì. Ìgbà tí mo máa fi di géńdé, ìwà mi ti le débi pé wọ́n fi mí sí iléèwé àwọn ọmọ aláìgbọràn. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo dá ọ̀ràn ńlá kan tó gbé mi dé ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ògbólógbòó ọ̀daràn. Lẹ́yìn-ò-rẹyìn, wọ́n dá mi sílẹ̀, mo sì kọjá sí orílẹ̀-èdè Ọsirélíà kí n lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé tuntun níbẹ̀.

Àti kékeré ni arákùnrin Robert ti jẹ́ oníbìínú, tó sì máa ń hùwà ipá. Ó tiẹ̀ ṣẹ̀wọ̀n nígbà kan rí

Ǹjẹ́ ìwà yín wá yí pa dà nígbà tẹ́ ẹ débẹ̀?

Mi ò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé bí mo ṣe kó wá sí ibí yìí mú ìyípadà kankan tó dà bí alárà wá. Ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ mi nínú Bíbélì ló tún ayé mi ṣe. Àmọ́ mo ṣì máa ń bínú lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, èyí sì máa ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi. Lọ́jọ́ kan, mo ronú lórí ohun tó wà nínú ìwé Òwe 19:11, tó sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú, ẹwà ni ó sì jẹ́ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti gbójú fo ìrélànàkọjá.” Ó wù mí kí n ní irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀, torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ lórí bí mo ṣe ń ronú, bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ àti bí mo ṣe ń hùwà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo dẹni tó ń dárí jini, tó ń mú sùúrù, tó sì ń fòye ṣe nǹkan.

Ṣẹ́ ẹ lè fún wa ní àpẹẹrẹ ohun tẹ́ ẹ̀ ń sọ?

Lọ́jọ́ kan, mo ṣẹ ọ̀rẹ́ mi kan, ló bá fìbínú sọ̀rọ̀ sí mi lójú àwọn èèyàn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mi ò mọ̀ọ́mọ̀ ṣe nǹkan yẹn, ojú tì mí wẹ̀lẹ̀mù! Síbẹ̀, mi ò fi ṣèbínú, mo rántí ẹsẹ Bíbélì tó sọ pé “ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan,” torí náà mo lọ bẹ̀ ẹ́. (Róòmù 12:17) Ìgbà tí ara rẹ̀ wálẹ̀, a jọ sọ̀rọ̀, mo wá rí i pé ìṣòro kan ló ń dà á láàmú nílé. Ibi tí aáwọ̀ náà parí sí nìyẹn, ó sì fún mi ní ẹ̀wù kan tí wọ́n máa ń wọ̀ nígbà òjò. Mo wá ronú pé ká ni mo gbé e gbóná fún un lọ́jọ́ náà, ohun tá à ń wí yìí kọ́ là bá máa wí.

Bí nǹkan ò bá fara rọ nínú ilé, kí lẹ máa ń ṣe?

Èmi àti ìyàwó mi ní ọmọkùnrin tó ti tó ọmọ ogún ọdún, á sì máa ń ní èdèkòyédè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan bíi tàwọn ìdílé míì. Àmọ́ ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì ti ràn mí lọ́wọ́, mo sì ti mọ bó ti ṣe pàtàkì tó láti máa sọ pé: “Jọ̀ọ́ máà bínú.” Ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò mọ̀ pé àwọn ọ̀rọ̀ yẹn wúlò gan-an, téèyàn bá sọ ọ́ látọkàn wá, ó lè yí ìbínú pa dà.

ÌFỌ̀RỌ̀WÁNILẸ́NUWÒ 2

Arákùnrin NELSON, ẹ̀rín yìí mà tuni lára kẹ̀, àmọ́ tẹ́lẹ̀ ẹ máa ń bínú gan-an, àbí?

Bẹ́ẹ̀ ni! Látìgbà tí mo ti di géńdé ni mo ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń tako ìjọba. Mo sì kórìíra ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń bá wa figagbága, tí wọ́n fẹ́ máa darí àgbègbè wa. Kódà, mo lọ kọ́ ìjà kọnfú kí n lè gbéjà ko ẹnikẹ́ni tó bá ta félefèle dé ọ̀dọ̀ mi.

Látìgbà tí Nelson ti wà ní géńdé ló ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń tako ìjọba

Kí ló wá jẹ́ kẹ́ ẹ yí ìwà yín pa dà?

Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì sílò nígbèésí ayé mi. Màá sọ méjì nínú wọn. Àkọ́kọ́ ni pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” (Mátíù 7:12) Èkejì ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ gẹ́gẹ́ bí ara rẹ.” (Mátíù 22:39) Irú ìfẹ́ tí mo rí láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìyẹn. Wọn kì í bá ara wọn ṣọ̀tá torí wọn ò ka ìran, ẹ̀yà àti èdè sí bàbàrà. Ni èmi náà bá fara wé wọn. Kò sì pẹ́ tí àwọn èèyàn fi bẹ̀rẹ̀ sí í rí ìyàtọ̀ lára mi, ní báyìí, wọn ò bẹ̀rù mi mọ́.

Ṣé látìgbà náà, ẹ ò hùwà bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́?

Mo ṣì máa ń bínú, àmọ́ kì í ṣe ní gbangba. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan tí mo bá wà nílé, inú máa ń bí mi. Ọjọ́ kan tiẹ̀ wà tí mo gbá ìyàwó mi lójú, nígbà tí ara mi wálẹ̀, ó dùn mí gan-an. Ìyàwó mi fọ̀rọ̀ náà ṣe osùn ó fi para, bó ṣe dárí jì mí jẹ́ kí n túbọ̀ pinnu láti kápá ìbínú mi.

Ẹ sọ lẹ́ẹ̀kan pé àwọn èèyàn ò bẹ̀rù yín mọ́, kí lẹ ní lọ́kàn?

Lọ́jọ́ kan, mo pàdé ọ̀gbẹ́ni kan tó ń jẹ́ Augusto, ìyẹn ọ̀kan lára àwọn abẹnugan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú kan tó ń bá ẹgbẹ́ tiwa jà. Ẹ̀rù kọ́kọ́ bà á. Àmọ́ ó túra ká sí mi nígbà tí mo kí i tẹ̀rín-tẹ̀rín, tí mo sì sọ fún un pé kó jẹ́ ká gbàgbé ọ̀rọ̀ àná. Mo tún pè é wá sílé mi, ó sì gbà. Ó yà á lẹ́nu láti rí bí Bíbélì ṣe tún ayé mi ṣe, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, ọ̀rẹ́ àtàtà ni èmi àti Augusto, ó sì ti n jọ́sìn Jèhófà.

“Ẹ Jẹ́ Ẹlẹ́mìí Àlàáfíà Pẹ̀lú Gbogbo Ènìyàn”

Oríṣiríṣi nǹkan ló lè dá aáwọ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, kì í ṣe gbogbo èèyàn ló máa gbà pẹ̀lú rẹ pé kí àwọn parí aáwọ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi gbà wá nímọ̀ràn pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”—Róòmù 12:18.

Ìrírí àwọn tá a mẹ́nu kàn nínú àkòrí yìí fi hàn pé téèyàn bá fi ọgbọ́n inú Bíbélì sílò, á rí i pé ó lágbára láti dojú “àwọn nǹkan tí a fìdí wọn rinlẹ̀ gbọn-in” dé. Lédè míì, ọgbọ́n inú Bíbélì lè jẹ́ ká kọ àwọn ìwà tí ò dáa sílẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 10:4) Ìwé Òwe 3:17, 18 tún sọ nípa irú ọgbọ́n bẹ́ẹ̀ pé: “Àwọn ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ àwọn ọ̀nà adùn, gbogbo òpópónà rẹ̀ sì jẹ́ àlàáfíà. Ó jẹ́ igi ìyè fún àwọn tí ó dì í mú, àwọn tí ó sì dì í mú ṣinṣin ni a ó pè ní aláyọ̀.”

Nelson àti Augusto ti di ọ̀rẹ́ báyìí

Ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ jẹ́ èèyàn àlàáfíà kó o sì láyọ̀? Ṣé o fẹ́ ní àwọn ọ̀rẹ́ tí kò ní dà ẹ́ tí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀? Bó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì máa tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà rẹ̀.

a A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.