Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́

Mo Pinnu Pé Ọmọ Ogun Kristi Ni Màá Jẹ́

Bí ìbọn ṣe ń dún kẹ̀ù-kẹ̀ù, tí ọta ìbọn sì ń fò kiri, mo rọra na áńkáṣíìfù funfun tó wà lọ́wọ́ mi sókè. Ìyẹn làwọn sójà rí, wọ́n bá pariwo mọ́ mi pé kí n jáde níbi tí mo sá pa mọ́ sí. Mo jáde, mo wá rọra ń lọ sọ́dọ̀ wọn, mi ò mọ̀ bóyá wọ́n á pa mí àbí wọn ò ní pa mí. Kí ló bá mi débí?

ỌDÚN 1926 ni wọ́n bí mi ní Karítsa, ìyẹn abúlé kékeré kan lórílẹ̀-èdè Gíríìsì. Èmi ni ìkeje lára ọmọ mẹ́jọ táwọn òbí wa bí.

Ní ọdún 1925, àwọn òbí mi pàdé arákùnrin kan tó ń jẹ́ John Papparizos. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì onítara ni, ó sì máa ń rojọ́ gan-an. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì là ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Bí John ṣe máa ń ṣàlàyé Bíbélì mú káwọn òbí mi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó wà lábúlé wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé màmá mi ò kàwé, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jèhófà Ọlọ́run lágbára gan-an, wọ́n sì máa ń lo gbogbo àǹfààní tí wọ́n ní láti wàásù fáwọn míì. Ó bani nínú jẹ́ pé àṣìṣe àwọn ará ni bàbá mi máa ń rí ṣáá, ìyẹn ló sì mú kí wọ́n pa ìpàdé tì.

Àwa ọmọ náà gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, àmọ́ bá a ṣe ń dàgbà, bá a ṣe máa jayé orí wa là ń bá kiri. Lọ́dún 1939, nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì gba ilẹ̀ Yúróòpù kan, ohun kan ṣẹlẹ̀ lábúlé wa tó bà wá lẹ́rù. Ó ní mọ̀lẹ́bí wa kan tó ń jẹ́ Nicolas Psarras tó ń gbé ládùúgbò wa. Lọ́jọ́ kan, wọ́n wá fipá mú un pé kóun náà wá di ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ ogún [20] ọdún ni Nicolas, tí kò sì pẹ́ tó ṣèrìbọmi, ó fìgboyà sọ fún wọn pé, “Mi ò ní jagun torí pé ọmọ ogun Kristi ni mí.” Ni wọ́n bá gbé e lọ sílé ẹjọ́ àwọn ológun, wọ́n sì rán an lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́wàá gbáko. Ó yà wá lẹ́nu gan-an!

Àmọ́ lọ́dún 1941, àwọn ọmọ ogun kan wọ ilẹ̀ Gíríìsì, bí wọ́n ṣe dá Nicolas sílẹ̀ lẹ́wọ̀n nìyẹn. Nígbà tó pa dà dé Karítsa, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Ilias bẹ̀rẹ̀ sí í da ìbéèrè bò ó, èmi náà sì ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn ìyẹn, èmi, Ilias àti àbúrò wa obìnrin tó ń jẹ́ Efmorfia bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a sì ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, a sì ṣèrìbọmi. Nígbà tó yá, mẹ́rin lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi náà di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Lọ́dún 1942, àwa ọ̀dọ́ mẹ́sàn-án ló wà níjọ Karítsa, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lèyí tó kéré jù láàárín wa, ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] sì lẹni tó dàgbà jù. Gbogbo wa la mọ̀ pé àdánwò ń bẹ níwájú fún wa, torí náà a máa ń pàdé pọ̀ láti gbé ara wa ró. Tá a bá ti pàdé, a máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, a máa ń kọ àwọn orin Ìjọba Ọlọ́run, a sì máa ń gbàdúrà. Àwọn ohun tá à ń ṣe yìí fún ìgbàgbọ́ wa lókun gan-an.

Demetrius àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ nílùú Karítsa

OGUN ABẸ́LÉ BẸ̀RẸ̀

Bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe ń parí lọ, àwọn kọ́múníìsì ilẹ̀ Gíríìsì dìtẹ̀ sí ìjọba, bí ogun abẹ́lé tó burú gan-an ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn. Àwọn ọmọ ogun kọ́múníìsì yìí máa ń wá sáwọn abúlé, wọ́n sì máa ń fipá mú àwọn ará abúlé pé kí wọ́n dara pọ̀ mọ́ wọn. Nígbà tí wọ́n dé abúlé wa, wọ́n fipá mú àwa ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí mẹ́ta, ìyẹn Antonio Tsoukaris, Ilias àti èmi. A bẹ̀ wọ́n, a sì sọ fún wọn pé a kì í jagun torí pé Kristẹni ni wá. Àmọ́, ṣe ni wọ́n kọtí ikún, wọ́n sì fipá mú wa lọ sí Òkè Olympus. Ibẹ̀ tó ìrìn wákàtí méjìlá sí ìlú wa.

Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn, ọ̀kan lára àwọn sójà kọ́múníìsì yẹn pàṣẹ pé ká dara pọ̀ mọ́ àwọn tó fẹ́ lọ jà. Nígbà tá a ṣàlàyé fún un pé a kì í pààyàn torí pé Kristẹni ni wá, ló bá bínú, ó sì wọ́ wa lọ sọ́dọ̀ ọ̀gágun kan. Nígbà tá a ṣàlàyé fún ọ̀gágun náà, ó sọ pé, “Ó dáa, ẹ lọ gbé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kẹ́ ẹ máa fi kó àwọn tó bá ṣèṣe lójú ogun lọ sílé ìwòsàn.”

A wá sọ fún un pé, “Táwọn sójà ìjọba bá mú wa ńkọ́? Ṣé wọn ò ní sọ pé sójà kọ́múníìsì làwa náà?” Ó wá sọ pé, “Ẹn, ẹ lọ máa kó búrẹ́dì fáwọn tó wà lójú ogun.” A wá sọ pé, “Tí ọmọ ogun kan bá rí wa pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tó wá sọ pé ká fi kó ìbọn lọ sójú ogun ńkọ́?” Ọ̀gágun náà ronú lọ sàà, ó wá pariwo mọ́ wa, ó ní: “Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ kẹ́ ẹ lè sin àgùntàn! Ẹ dúró sórí òkè yìí, kẹ́ ẹ máa tọ́jú àwọn àgùntàn.”

Nígbà tá a ro ọ̀rọ̀ náà síwá sẹ́yìn, a rí i pé ẹ̀rí ọkàn wa ṣì máa gbà wá láyè láti tọ́jú àwọn àgùntàn. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn, wọ́n gbà kí Ilias pa dà sílé kó lè tọ́jú màmá wa torí pé bàbá wa ti kú nígbà yẹn. Antonio ní tiẹ̀ ṣàìsàn, torí náà wọ́n ní kó máa lọ sílé. Àmọ́ wọn ò gbà kí èmi pa dà sílé.

Nígbà tó yá, àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Gíríìsì ń sún mọ́ ibi táwọn ọmọ ogun kọ́múníìsì wà. Ni àwọn tó mú mi lóǹdè bá bẹ̀rẹ̀ sí í sá gba orí òkè kan kí wọ́n lè sá lọ sórílẹ̀-èdè Alibéníà. Nígbà tó ku díẹ̀ ká dé ibodè Alibéníà, ńṣe làwọn ọmọ ogun Gíríìsì yí wa ká. Nígbà táwọn ọmọ ogun kọ́múníìsì yìí rí wọn, àyà wọn já, ni wọ́n bá fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Mo wá sá sábẹ́ igi kan tó wó lulẹ̀, ohun tó bá mi dé ibi ọ̀rọ̀ tí mo sọ níbẹ̀rẹ̀ nìyẹn.

Mo sọ fáwọn ọmọ ogun Gíríìsì náà pé ṣe ni àwọn ọmọ ogun kọ́múníìsì jí mi gbé, torí náà wọ́n lọ ṣàyẹ̀wò mi ní àgọ́ wọn nítòsí ìlú Véroia, ìyẹn ìlú tí Bíbélì pè ní Bèróà. Níbẹ̀, wọ́n ní kí n máa gbẹ́ kòtò táwọn sójà máa ń sá pa mọ́ sí, àmọ́ mo kọ̀. Torí náà, ọ̀gágun tó wà níbẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n lọ jù mí sí erékùṣù kékeré kan tó ń jẹ́ Makrónisos. Ẹ̀rù jẹ̀jẹ̀ ni erékùṣù yìí torí pé ìyà ibẹ̀ pọ̀.

ERÉKÙṢÙ Ẹ̀RÙ JẸ̀JẸ̀

Etíkun Attica ni erékùṣù Makrónisos wà, ibẹ̀ sì fi nǹkan bí ọgbọ̀n [30] máìlì jìn sílùú Áténì. Ibẹ̀ ò dáa rárá, ó gbẹ táútáú, oòrùn ibẹ̀ sì lè jóni gbẹ. Erékùṣù yìí kò fẹ̀ rárá, síbẹ̀ láàárín ọdún 1947 sí 1958, àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] ni wọ́n kó wá síbẹ̀. Lára wọn ni àwọn Kọ́múníìsì, àwọn míì tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ Kọ́múníìsì, àwọn tí ìjọba kà sí ọlọ̀tẹ̀ àti ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ olóòótọ́.

Nígbà tí mo débẹ̀ lọ́dún 1949, wọ́n pín àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà sí àgọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àgọ́ kan táwọn ẹ̀ṣọ́ ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ ni wọ́n fi mí sí pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin míì. Àwa bí ogójì [40] la máa ń sùn sábẹ́ tẹ́ǹtì kan tí wọ́n ṣe fún ẹni mẹ́wàá péré. Omi ìdọ̀tí là ń mu, ẹ̀wà àti ìgbá la sì máa ń jẹ. Eruku tó wà níbẹ̀ àti atẹ́gùn yẹn ò bára dé rárá. Síbẹ̀, a dúpẹ́ pé wọn ò ní ká máa fọ́ àpáta lójoojúmọ́ torí iṣẹ́ tí wọ́n fi ń dá ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n lóró nìyẹn. Ṣe nìyẹn sì máa ń mú káwọn ẹlẹ́wọ̀n náà bọ́hùn.

Èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí míì tí wọ́n jù sí erékùṣù Makrónisos

Bí mo ṣe ń rìn gba etíkun lọ́jọ́ kan, mo pàdé àwọn ará mélòó kan tí wọ́n wà láwọn àgọ́ míì. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó nígbà tá a ríra! Kí wọ́n má bàa mú wa, a máa ń pàdé pọ̀ ní bòókẹ́lẹ́ tí àyè bá ti yọ. A tún máa ń fọgbọ́n wàásù fáwọn ẹlẹ́wọ̀n míì, àwọn kan lára wọn sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tó yá. Àdúrà àtàwọn nǹkan tá à ń ṣe yìí ló fún wa lókun ní gbogbo àsìkò yẹn.

WỌ́N FIMÚ MI DÁNRIN

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fìyà jẹ mí fún oṣù mẹ́wàá, tí wọ́n sì ronú pé màá ti tún èrò mi pa, wọ́n ní kí n wọṣọ ológun. Torí pé mo kọ̀, wọ́n wọ́ mi lọ sọ́dọ̀ ọ̀gá àwọn sójà tó wà ní àgọ́ náà. Mo wá fún un ní ìwé kan tí mo kọ, ohun tó wà nínú ìwé náà ni pé, “Ọmọ ogun Kristi nìkan ni mo fẹ́ jẹ́.” Ó halẹ̀ mọ́ mi, lẹ́yìn náà ó fà mí lé igbá kejì rẹ̀ lọ́wọ́. Bíṣọ́ọ̀bù àgbà Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ilẹ̀ Gíríìsì ni igbá kejì yìí, aṣọ oyè ṣọ́ọ̀ṣì ló sì wọ̀. Ó da ìbéèrè bò mí, mo sì fìgboyà dáhùn àwọn ìbéèrè náà látinú Ìwé Mímọ́. Ló bá tutọ́ sókè ló fojú gbà á, ó ní: “Ẹ mú un kúrò lọ́dọ̀ mi. Agbawèrèmẹ́sìn ni!”

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, àwọn sójà tún pàṣẹ fún mi pé kí n wọṣọ ológun. Nígbà tí mo sọ fún wọn pé mi ò wọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹ̀ṣẹ́ bò mí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń lù mí ní kóńdó. Nígbà tó ṣe, wọ́n gbé mi lọ sílé ìwòsàn tó wà níbẹ̀ kí wọ́n lè mọ̀ bóyá àwọn egungun mi ti ṣẹ́, lẹ́yìn náà, wọ́n wọ́ mi pa dà sí tẹ́ńtì mi. Bí wọ́n ṣe ń fimú mi dánrin nìyẹn lójoojúmọ́, fún odindi oṣù méjì gbáko.

Nígbà tí wọ́n rí i pé mi ò bọ́hùn, wọ́n dá ọgbọ́n tuntun kan. Wọ́n so ọwọ́ mi mọ́ ẹ̀yìn, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í kó ẹgba bo àtẹ́lẹsẹ̀ mi. Bí mo ṣe ń jẹ̀rora yẹn, mò ń rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, . . . Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run; nítorí ní ọ̀nà yẹn ni wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn wòlíì tí ó wà ṣáájú yín.” (Mát. 5:​11, 12) Ìyà yìí kọjá bẹ́ẹ̀, kódà mi ò mọ̀gbà tí mo dákú.

Nígbà tí mo ta jí, mo bá ara mi nínú àhámọ́ kan tó tutù gan-an. Kò sóúnjẹ, kò sómi tàbí aṣọ tí mo lè fi bora. Síbẹ̀, ṣe lọkàn mi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Gẹ́lẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ ló rí, pé “àlàáfíà Ọlọ́run” á máa ṣọ́ ọkàn mi àti ìrònú mi. (Fílí. 4:7) Lọ́jọ́ kejì, sójà onínúure kan fún mi ní búrẹ́dì àti omi, ó sì tún fún mi láṣọ òtútù kan. Yàtọ̀ síyẹn, sójà míì tún bẹ̀rẹ̀ sí í fún mi lára oúnjẹ rẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn ọ̀nà tí Jèhófà gbà fi inú rere hàn sí mi nìyẹn, mo sì rí ọwọ́ Jèhófà lára mi ní gbogbo àsìkò yẹn.

Àwọn ọ̀gágun yẹn gbà pé ọlọ̀tẹ̀ tí ò ṣeé yí pa dà ni mí, torí náà, wọ́n mú mi lọ sí ilé ẹjọ́ àwọn ológun tó wà nílùú Áténì. Ibẹ̀ ni wọ́n ti rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Yíaros, ìyẹn erékùṣù kan tó wà ní nǹkan bí ọgbọ̀n [30] máìlì sí ìlà oòrùn Makrónisos.

“A FỌKÀN TÁN YÍN”

Bíríkì pupa ni wọ́n fi kọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n Yíaros, ọ̀rọ̀ òṣèlú ló sì gbé àwọn tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún débẹ̀. Yàtọ̀ sáwọn yẹn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà méje ló wà níbẹ̀ torí pé a ò lọ́wọ́ sí ogun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèwọ̀ ni fún ẹnikẹ́ni láti pàdé pọ̀, àwa méjèèje máa ń dọ́gbọ́n ṣèpàdé, ká lè jọ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà, a máa ń rí àwọn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n dọ́gbọ́n kó wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. Àá wá dà á kọ ká lè fi kẹ́kọ̀ọ́.

Lọ́jọ́ kan, wọ́dà kan ká wa mọ́ ibi tá a ti ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́, ló bá gba ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́. Bí wọ́n ṣe ní ká máa bọ̀ ní ọ́fíìsì igbá kejì ọ̀gá àwọn wọ́dà nìyẹn. Àyà wa já, a rò pé ṣe ni wọ́n máa fi kún iye ọdún tá a máa lò lẹ́wọ̀n. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ló sọ pé: “A mọ̀ yín dáadáa, a sì máa ń bọ̀wọ̀ fún yín. A mọ̀ pé a lè fọkàn tán yín. Ẹ pa dà sẹ́nu iṣẹ́ yín.” Ìyẹn nìkan kọ́ o, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí í fún àwọn kan lára wa níṣẹ́ tí ò gba agbára púpọ̀. Èyí múnú wa dùn gan-an, a sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà. A wá rí i pé bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀wọ̀n la wà, ìwà wa ṣì ń fògo fún Jèhófà.

Ìwà rere wa tún sèso rere míì. Ẹlẹ́wọ̀n kan tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìṣirò fara balẹ̀ kíyè sí ìwà wa dáadáa, torí náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í bi wá nípa àwọn ohun tá a gbà gbọ́. Lọ́dún 1951 nígbà tí wọ́n dá àwa Ẹlẹ́rìí sílẹ̀, wọ́n dá òun náà sílẹ̀. Nígbà tó yá, ó ṣèrìbọmi, ó sì di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.

ỌMỌ OGUN KRISTI ṢÌ NI MÍ

Èmi àti Janette ìyàwó mi

Nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀, mo pa dà sọ́dọ̀ ìdílé mi ní Karítsa. Bíi tàwọn kan, èmi náà ṣí lọ sílùú Melbourne, lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ibẹ̀ ni mo ti pàdé arábìnrin onítara kan tó ń jẹ́ Janette, a sì ṣègbéyàwó. A bí ọmọ mẹ́rin, ọkùnrin kan àti obìnrin mẹ́ta, gbogbo wọn ló sì ń ṣe dáadáa nínú ìjọsìn Ọlọ́run.

Ní báyìí, mo ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún, alàgbà ni mí nínú ìjọ, mo sì ń ṣe ojúṣe mi dáadáa. Àmọ́ torí ìyà tí mo ti jẹ sẹ́yìn, gbogbo ara ló máa ń dùn mí, títí kan ẹsẹ̀ mi, pàápàá tí mo bá ṣẹ̀ṣẹ̀ ti òde ẹ̀rí dé. Síbẹ̀, ìpinnu mi ò yí pa dà pé “ọmọ ogun Kristi” ni màá jẹ́ lọ́jọ́kọ́jọ́.​—2 Tím. 2:3.