Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NÌDÍ TÓ FI YẸ KÁ JẸ́ OLÓÒÓTỌ́?

Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ

Àkóbá Tí Ìwà Àìṣòótọ́ Lè Ṣe fún Ẹ

“Èèyàn máa ń kó sí àwọn wàhálà kan tó jẹ́ pé àfi kéèyàn hùwà àìṣòótọ́ díẹ̀ kó tó bọ́ nínú wàhálà náà.”—Samantha, South Africa.

Ṣé o fara mọ́ ohun tí ẹni yìí sọ? Bíi ti Samantha, gbogbo wa la máa ń dojú kọ ìṣòro lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn ìṣòro yìí lè fẹ́ mú ká hùwà àìṣòótọ́. Ohun tá a bá ṣe láti yanjú ìṣòro náà máa fi hàn bóyá olóòótọ́ èèyàn ni wá tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó bá jẹ́ pé ńṣe la ò fẹ́ kí ojú tì wá, a lè wò ó pé ó máa dáa ká kúkú parọ́ ká lè fi yọ ara wa. Tí òótọ́ bá wá jáde lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ohun tó máa ń tìdí ẹ̀ yọ kì í bára dé. Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó sábà máa ń jẹ́ àbájáde ìwà àìṣòótọ́.

ÀÌṢÒÓTỌ́ KÌ Í JẸ́ KÍ WỌ́N FỌKÀN TÁNNI

Kí àárín ọ̀rẹ́ méjì tó lè wọ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ fọkàn tán ara wọn. Tí àwọn méjì bá fọkàn tán ara wọn, wọn ò ní máa fura òdì sí ara wọn. Àmọ́, àwọn èèyàn ò kàn lè ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí í fọkàn tán wa. Ohun tó lè mú káwọn èèyàn fọkàn tán wa ni pé ká máa sọ òótọ́, ká má sì figbá kan bọ̀kan nínú. Àmọ́ téèyàn bá hùwà àìṣòótọ́ lẹ́ẹ̀kan péré, àwọn èèyàn lè má fọkàn tán wa mọ́ rárá. Tọ́rọ̀ bá sì rí bẹ́ẹ̀, ó máa ṣòro gan-an ká tó lè mú káwọn èèyàn pa dà máa fọkàn tán wa.

Ṣé ẹnì kan tó o kà sí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ti parọ́ fún ẹ rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo ló ṣe rí lára rẹ? Ó ṣeé ṣe kó dùn ẹ́ wọra, wàá sì ka ẹni náà sí ọ̀rẹ́ ọ̀dàlẹ̀. Bó ṣe máa ń rí fún ọ̀pọ̀ èèyàn nìyẹn. Kò sí àní-àní pé ńṣe ni ìwà àìṣòótọ́ máa ń ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn èèyàn jẹ́.

ÌWÀ ÀÌṢÒÓTỌ́ MÁA Ń RANNI

Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Innes, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò ọrọ̀ ajé ní yunifásítì California ṣe ìwádìí kan. Ìwádìí náà fi hàn pé “ìwà àìṣòótọ́ máa ń ran àwọn ẹlòmíì.” Torí náà, a lè fi ìwà àìṣòótọ́ wé àrùn tó máa ń ranni. Èyí fi hàn pé tó o bá ń bá ẹlẹ́tàn èèyàn rìn, kò ní pẹ́ tí ìwọ náà á fi máa hùwà ẹ̀tàn. Ó ṣe tán, àgùntàn tó bá ń bá ajá rìn máa jẹ ìgbẹ́.

Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní di aláìṣòótọ́? Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. Jẹ́ ká wo díẹ̀ nínú àwọn ìlànà Bíbélì yìí.