Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run àti Kristi

Ohun Tó Jẹ́ Òtítọ́ Nípa Ọlọ́run àti Kristi

Ọ̀pọ̀ ọlọ́run làwọn èèyàn ń jọ́sìn, àmọ́ Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo ló wà. (Jòhánù 17:3) Òun ni “Onípò Àjùlọ,” Ẹlẹ́dàá ohun gbogbo àti Ẹni tó fún gbogbo alààyè lẹ́mìí. Òun nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn.​—Dáníẹ́lì 7:18; Ìfihàn 4:11.

Ta ni Ọlọ́run?

Orúkọ Ọlọ́run fara hàn nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ní NǸKAN BÍI 7,000 ÌGBÀ

JÈHÓFÀ ni orúkọ Ọlọ́run

OLÚWA, ỌLỌ́RUN, BABA​—Díẹ̀ lára àwọn orúkọ oyè tí Jèhófà ní

Kí Ni Orúkọ Ọlọ́run? Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Orúkọ mi nìyẹn.” (Àìsáyà 42:8) Orúkọ Ọlọ́run yìí fara hàn nínú Bíbélì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ìgbà. Àmọ́, nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì, wọ́n ti fi àwọn orúkọ oyè bí “Olúwa” rọ́pò orúkọ rẹ̀. Ọlọ́run fẹ́ kó o di ọ̀rẹ́ òun, ìdí nìyẹn tó fi ń rọ̀ ẹ́ pé kó o ‘ké pe orúkọ òun.’​—Sáàmù 105:1.

Àwọn Orúkọ Oyè Tí Jèhófà Ní. Bíbélì tún máa ń lo àwọn orúkọ oyè míì fún Jèhófà bíi “Ọlọ́run,” “Olódùmarè,” “Ẹlẹ́dàá,” “Baba,” “Olúwa,” àti “Oba Aláṣẹ.” Nínú ọ̀pọ̀ àdúrà tó wà nínú Bíbélì, orúkọ náà Jèhófà wà níbẹ̀, àwọn orúkọ oyè rẹ̀ náà sì wà níbẹ̀.​—Dáníẹ́lì 9:4.

Báwo Ni Ọlọ́run Ṣe Rí? Ẹ̀mí ni Ọlọ́run, a ò sì lè rí i. (Jòhánù 4:24) Bíbélì tiẹ̀ sọ pé “kò sí èèyàn tó rí Ọlọ́run rí.” (Jòhánù 1:18) Bíbélì jẹ́ ká mọ bí nǹkan ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run. Ohun tá a bá ṣe lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá a tàbí kó “mú inú rẹ̀ dùn.”​—Òwe 11:20; Sáàmù 78:40, 41.

Àwọn Ànímọ́ Ọlọ́run Tó Ta Yọ. Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ẹnikẹ́ni, ó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn láìka ibi tí wọ́n ti wá àti ipò wọn sí. (Ìṣe 10:34, 35) Ó tún jẹ́ “Ọlọ́run aláàánú, tó ń gba tẹni rò, tí kì í tètè bínú, tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi.” (Ẹ́kísódù 34:6, 7) Àmọ́, ó ní àwọn ànímọ́ mẹ́rin tó ta yọ.

Agbára. Torí pé òun ni “Ọlọ́run Olódùmarè,” agbára rẹ̀ kò ní ààlà, kò sì sí ohun tó lè dí i lọ́wọ́ láti mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ.​—Jẹ́nẹ́sísì 17:1.

Ọgbọ́n. Ọlọ́run ló gbọ́n jù láyé àti lọ́run. Abájọ tí Bíbélì fi sọ pé òun ni “ẹnì kan ṣoṣo tí ó gbọ́n.”​—Róòmù 16:27.

Ìdájọ́ Òdodo. Gbogbo ìgbà ni Ọlọ́run máa ń ṣe ohun tó tọ́. “Pípé” ni àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, “kì í ṣe ojúsàájú.”​—Diutarónómì 32:4.

Ìfẹ́. Bíbélì sọ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Kì í ṣe pé Ọlọ́run máa ń fìfẹ́ hàn nìkan ni, àmọ́ òun gangan ni ìfẹ́. Ìfẹ́ rẹ̀ tó ta yọ jù lọ ló máa ń mú kó ṣe gbogbo ohun tó bá ń ṣe, ìyẹn sì máa ń ṣe wá láǹfààní ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà.

Àwa Èèyàn Lè Di Ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Ọlọ́run jẹ́ Baba wa ọ̀run, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa. (Mátíù 6:9) Tá a bá gba Ọlọ́run gbọ́, a lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀. (Sáàmù 25:14) Kódà, Ọlọ́run fìfẹ́ rọ̀ ẹ́ pé kó o sún mọ́ òun nínú àdúrà, kó o sì ‘kó gbogbo àníyàn rẹ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, torí ó ń bójú tó ẹ.’​—1 Pétérù 5:7; Jémíìsì 4:8.

Ìyàtọ̀ Wo Ló Wà Láàárín Ọlọ́run àti Kristi?

Jésù Kọ́ Ni Ọlọ́run. Jésù ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé òun nìkan ni Ọlọ́run dá ní tààràtà. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pè é ní Ọmọ Ọlọ́run. (Jòhánù 1:14) Lẹ́yìn tí Jèhófà dá Jésù tán, ó wá lo àkọ́bí rẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí “àgbà òṣìṣẹ́” láti dá gbogbo ohun tó kù, títí kan àwa èèyàn.​—Òwe 8:30, 31; Kólósè 1:15, 16.

Jésù kò pe ara rẹ̀ ní Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Aṣojú látọ̀dọ̀ [Ọlọ́run] ni mí, Ẹni yẹn ló sì rán mi jáde.” (Jòhánù 7:29) Nígbà tí Jésù ń bá àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ó pe Jèhófà ní “Baba mi àti Baba yín,” ó tún pè é ní “Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” (Jòhánù 20:17) Lẹ́yìn tí Jésù kú, Jèhófà jí i dìde sí ọ̀run, ó fún un ní àṣẹ tó pọ̀, ó sì ní kó wà ní ọwọ́ ọ̀tún òun.​—Mátíù 28:18; Ìṣe 2:32, 33.

Jésù Kristi Lè Mú Kó O Sún Mọ́ Ọlọ́run

Jésù wá sí ayé kó lè kọ́ wa nípa Baba rẹ̀. Jèhófà fúnra rẹ̀ sọ nípa Jésù pé: “Èyí ni Ọmọ mi, àyànfẹ́. Ẹ fetí sí i.” (Máàkù 9:7) Jésù mọ Ọlọ́run ju ẹnikẹ́ni lọ. Ó ní: “Kò sì sẹ́ni tó mọ ẹni tí Baba jẹ́, àfi Ọmọ àti ẹnikẹ́ni tí Ọmọ bá fẹ́ ṣí i payá fún.”​—Lúùkù 10:22.

Jésù gbé ìwà Ọlọ́run yọ láìkù síbì kan. Jésù fi ìwà jọ Baba rẹ̀ láìkù síbì kan, ìdí nìyẹn tó fi lè sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tó bá ti rí mi ti rí Baba náà.” (Jòhánù 14:9) Bí Jésù ṣe fìfẹ́ hàn bíi ti Baba rẹ̀ nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ mú kí àwọn èèyàn sún mọ́ Ọlọ́run. Ó sọ pé: “Èmi ni ọ̀nà àti òtítọ́ àti ìyè. Kò sí ẹni tó ń wá sọ́dọ̀ Baba àfi nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Ó tún sọ pé: “Àwọn olùjọ́sìn tòótọ́ á máa jọ́sìn Baba ní ẹ̀mí àti òtítọ́, torí ní tòótọ́, irú àwọn ẹni yìí ni Baba ń wá pé kí wọ́n máa jọ́sìn òun.” (Jòhánù 4:23) Ìyẹn mà dáa o! Jèhófà fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ òtítọ́ nípa òun, títí kan ìwọ náà.