Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

Àárẹ̀ Ọpọlọ​—Ìṣòro Tó Kárí Ayé

“Gbogbo ìgbà ni mo máa ń ṣàníyàn, kódà tí mo bá dá nìkan wà nínú yàrá.”

“Tí ara mi bá ti yá gágá jù, ṣe ni ẹ̀rù máa ń bà mí, torí mo mọ̀ pé tínú mi bá ti dùn ládùnjù, ìsoríkọ́ ló máa ń gbẹ̀yìn ẹ̀.”

“Mo máa ń gbìyànjú kí n má da àníyàn tọ̀la mọ́ tòní, àmọ́ nígbà míì, ṣe ni mo kàn máa ń dédé rí i pé mo ti ń ṣàníyàn nípa ọ̀pọ̀ nǹkan.”

Ṣé ìwọ tàbí ẹnì kan tó o mọ̀ nírú ìṣòro táwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn yìí ní?

Fọkàn balẹ̀, ìwọ nìkan kọ́ lo nírú ìṣòro yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí náà ni ọkàn wọn kì í balẹ̀ tí wọ́n sì máa ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ. Tí ìwọ ò bá tiẹ̀ níṣòro yìí, ó lè máa ṣe ẹnì kan tó o mọ̀.

Ká sòótọ́, “àkókò tí nǹkan máa le gan-an tó sì máa nira” tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ la wà yìí, èyí sì ń kó oríṣiríṣi ìdààmú bá gbogbo èèyàn. (2 Tímótì 3:1) Ìwádìí kan fi hàn pé kárí ayé, nínú èèyàn mẹ́jọ, ó kéré tán, ẹnì kan ní àárẹ̀ ọpọlọ. Lọ́dún 2020, àrùn kòrónà mú káwọn tó níṣòro àìbalẹ̀ ọkàn àti ìsoríkọ́ tó lágbára pọ̀ sí i, wọ́n fi nǹkan bíi mílíọ̀nù méjìdínlọ́gọ́rin (78,000,000) pọ̀ ju ti ọdún 2019.

Ẹ̀rí fi hàn pé ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló níṣòro àìbalẹ̀ ọkàn àti ìsoríkọ́. Síbẹ̀, ó ṣe pàtàkì kí ìwọ àtàwọn èèyàn ẹ mọ bẹ́ ẹ ṣe lè máa tọ́jú ara yín, kẹ́ ẹ sì máa gbádùn ayé yín.

Ọpọlọ tó jí pépé

Tí ọpọlọ ẹnì kan bá jí pépé, ara ẹ̀ á yá gágá, á sì máa ṣe nǹkan bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. Nǹkan ò ní tètè máa sú u, á máa jára mọ́ṣẹ́ ẹ̀, ọkàn ẹ̀ á sì balẹ̀.

Àárẹ̀ ọpọlọ . . .

  • KÌ Í ṢE ohun tẹ́nì kan fọwọ́ ara ẹ̀ fà.

  • Ó JẸ́ àìlera tó máa ń dani láàmú, tí kì í jẹ́ kéèyàn ronú dáadáa, kára ẹ̀ balẹ̀, kó sì hùwà tó yẹ.

  • Ó máa ń jẹ́ kó ṣòro láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn míì àti láti bójú tó àwọn nǹkan pàtàkì lójoojúmọ́.

  • Kò sẹ́ni tí ò lè níṣòro yìí, ẹ̀yà yòówù kéèyàn ti wá, èdè yòówù kéèyàn máa sọ, bóyá ọmọdé ni tàbí àgbà, bóyá ó kàwé tàbí kò kàwé, bóyá olówó ni tàbí tálákà.

Ìrànwọ́ fáwọn tó ní àárẹ̀ ọpọlọ

Tó o bá kíyè sí i pé ìṣesí ẹ ṣàdédé yí pa dà, bóyá o kì í sùn dáadáa, o kì í jẹun dáadáa, nǹkan máa ń tètè sú ẹ, o máa ń ṣàníyàn ju bó ṣe yẹ lọ tàbí inú ẹ máa ń dédé bà jẹ́, ó sì lè jẹ́ èèyàn ẹ kan nirú ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ sí, á dáa kí ìwọ tàbí ẹni náà lọ rí àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ kí wọ́n lè ṣàyẹ̀wò ohun tó fa ìṣòro yìí, kí wọ́n sì fún yín ní ìtọ́jú tó yẹ. Àmọ́ irú ìtọ́jú wo ló yẹ kẹ́ ẹ gbà?

Jésù Kristi, ẹni tó gbọ́n jù lọ lára àwọn tó ti gbé ayé sọ pé: “Àwọn tí ara wọn lè kò nílò oníṣègùn, àmọ́ àwọn tó ń ṣàìsàn nílò rẹ̀.” (Mátíù 9:12) Táwọn tó ń ṣàìsàn bá gba irú ìtọ́jú tí wọ́n nílò gangan, èyí á dín ìrora wọn kù, wọ́n á sì máa gbádùn ayé wọn. Torí náà, ó yẹ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ tètè lọ gba ìtọ́jú, ní pàtàkì tí àìsàn náà bá lágbára tàbí tí kò lọ bọ̀rọ̀. a

Òótọ́ ni pé Bíbélì kì í ṣe ìwé ìṣègùn, àmọ́ ohun tó wà níbẹ̀ ṣàǹfààní púpọ̀ fáwọn tó ní ìdààmú ọkàn tàbí àárẹ̀ ọpọlọ. A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tí Bíbélì sọ pé èèyàn lè ṣe tó bá ní àárẹ̀ ọpọlọ.

a Ìwé yìí kò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dáa jù. Ẹnì kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó fara balẹ̀ gbé oríṣiríṣi ìtọ́jú tó wà yẹ̀ wò kó tó yan irú ìtọ́jú tó máa gbà.