Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀ gbà pé ọkàn èèyàn kì í kú

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | KÍ NI BÍBÉLÌ SỌ NÍPA ÌYÈ ÀTI IKÚ?

Ìbéèrè Tó Ń Rúni Lójú

Ìbéèrè Tó Ń Rúni Lójú

ONÍRÚURÚ èrò làwọn èèyàn ní nípa ìyè àti ikú. Àwọn kan ronú pé tí èèyàn bá kú, ẹ̀mí ẹni tó kú náà á lọ máa gbé ní ibòmíì tàbí kó di nǹkan míì. Àwọn kan gbà pé wọ́n máa ń tún ẹni tó kú bí, ìdí nìyẹn táwọn kan fi máa ń sọ ọmọ ní Ìyábọ̀ tàbí Babatúndé. Síbẹ̀ àwọn kan gbà pé ikú ni òpin ẹ̀dá.

Àṣà ìbílẹ̀ tàbí ilé tó o ti jáde lè nípa lórí ohun tó o gbà gbọ́ lórí ọ̀rọ̀ yìí. Èrò àwọn èèyàn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà téèyàn bá kú yàtọ̀ síra, àmọ́ ṣé ibì kankan tiẹ̀ wà tá a ti lè rí ìdáhùn tó jẹ́ òótọ́ tó sì ṣe é gbára lé sí ìbéèrè tó ń rúni lójú yìí?

Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ti ń kọ́ àwọn èèyàn pé ẹ̀mí tàbí ọkàn èèyàn kì í kú. Gbogbo àwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tó gbajúmọ̀, bí ẹ̀sìn Kristẹni, Híńdù, Júù, Mùsùlùmí àtàwọn ẹ̀sìn míì gbà pé ọkàn èèyàn kì í kú, wọ́n sọ pé tí èèyàn bá kú, ọkàn rẹ̀ á jáde lára rẹ̀, á sì lọ máa gbé ìlú àwọn òkú. Ní ti àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, ìgbàgbọ́ wọn ni pé wọ́n máa ń tún ẹni tó kú bí láìmọye ìgbà, títí tí ẹni náà á fi dé ipò ìdẹ̀ra tí wọ́n ń pè ní Nirvana.

Ẹ̀kọ́ yìí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé gbà pé ńṣe ni ikú máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún èèyàn láti lọ máa gbé ní ayé míì. Lójú wọn, ńṣe ni ikú jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì kan nínú bí ẹ̀mí èèyàn ṣe ń yípo àti pé ó jẹ́ ara ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó máa ṣẹlẹ̀ sí àwa èèyàn. Àmọ́, kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí? Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó kàn láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè yìí. Ohun tí Bíbélì sọ máa yà ẹ́ lẹ́nu.