Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | IBO LO TI LÈ RÍ ÌTÙNÚ?

Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú

Gbogbo Wa La Nílò Ìtùnú

Ṣé o rántí ìgbà kan tó o ṣubú ní kékeré? Bóyá tápá rẹ tiẹ̀ kán tàbí tó o fi ojúgun gbá. Ṣé o ṣì lè rántí bí ìyá rẹ ṣe rẹ̀ ẹ́ lẹ́kún? Ó ṣeé ṣe kí màmá rẹ bá ẹ nu ojú ọgbẹ́ náà, kí wọ́n sì fi nǹkan dè é. Bó o ṣe ń ké ni wọ́n á máa kí ẹ pẹ̀lẹ́, tí wọ́n á sì máa gbá ẹ mọ́ra títí tọ́kàn rẹ á fi balẹ̀ pẹ̀sẹ̀. Nígbà yẹn, kò ṣòro fún ẹ láti rẹ́ni tù ẹ́ nínú.

Àmọ́ ńṣe ni gbogbo nǹkan ń le sí i bá a ṣe ń dàgbà. Bí ìṣòro ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ló ṣe ń nira sí i láti rẹ́ni tù wá nínú. Ìṣòro táwọn ọ̀dọ́ ń bá fínra kọjá ká de ojú ọgbẹ́ àti ká gbáni mọ́ra lọ. Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

  • Ǹjẹ́ iṣé ti bọ́ lọ́wọ́ rẹ rí? Julian sọ pé ńṣe lòun ń kanra lódìlódì nígbà tí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ òun. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé: ‘Báwo ni máa ṣe tọ́jú ìdílé mi? Lẹ́yìn gbogbo ọdún tí mo fi ṣiṣẹ́ àṣekára ní ilé-iṣé yìí, kí ló dé tí wọ́n fi ronú pé mi ò wúlò fún àwọn mọ́?’

  • Lóòótọ́, ọkàn rẹ lè gbọgbẹ́ torí pé ìdílé rẹ ti tú ká. Raque sọ pé: “Nígbà tí ọkọ mi kàn ṣàdédé kúrò nílé ní oṣù méjìdínlógún [18] sẹ́yìn, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n da aṣọ ìbànújẹ́ bò mí. Àfi bíi pé ọkàn mi ya sí méjì. Mò ń jẹ̀rora nínú lọ́hùn, ó sì ń hàn nínú gbogbo ohun tí mò ń ṣe. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn bà mí lẹ́rù gan-an.”

  • Ó lè jẹ́ àìsàn burúkú kan ló ń ṣe ẹ́ tí kò sì sí àmì pé ó máa lọ rárá. Láwọn ìgbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi Jóòbù tó kérora pé: “Mo kọ̀ ọ́; èmi kì yóò wà láàyè fún àkókò tí ó lọ kánrin.” (Jóòbù 7:16) Luis tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún sọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Nígbà míì, ó máa ń ṣe mí bíi pé kí n kú kíá jàre.”

  • Ó sì lè jẹ́ pé ikú ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ ló ń mú kó o máa wá ìtùnú. Robert sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé ọmọkùnrin mi kú nínú jàǹbá ọkọ̀ òfuurufú, ó kọ́kọ́ ṣe mí bíi pé irọ́ ni, kò pẹ́ sásìkò yẹn ni ọgbẹ́ ọkàn ńlá dé bá mi, irú èyí tí Bíbélì fi wé idà gígùn tó ń gúnni lọ́kàn.”​—Lúùkù 2:⁠35.

Robert, Luis, Raquel àti Julian rí ìtùnú gbà, kódà nínú ipò ìbànújẹ́ tí wọ́n wà yẹn. Wọ́n rí Ẹnì kan tó lè fún wọn ní ìtùnú ìyẹn Ọlọ́run Olódùmarè. Báwo ló ṣe ń tù wá nínú? Ǹjẹ́ ó máa tu ìwọ náà nínú?