Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

OHUN TÓ JẸ́ ÌṢÒRO

Kò Sí Ààbò àti Ìfọ̀kànbalẹ̀

Kò Sí Ààbò àti Ìfọ̀kànbalẹ̀

“Kò tíì sí àkókò kankan nínú ìtàn ẹ̀dá èèyàn tí ìtẹ̀síwájú bá ìmọ̀ ẹ̀rọ, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ètò ọrọ̀ ajé bíi ti àkókò wa yìí. . . . Síbẹ̀, àkókò yìí ni nǹkan burú jù lọ nínú ètò ìṣèlú àti ètò ọrọ̀ ajé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, àyíká wa tó ń bà jẹ́ sí i ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pa ayé run.”​—The Global Risks Report 2018, World Economic Forum.

KÍ NÌDÍ TÍ Ọ̀PỌ̀ ÀWỌN OLÓYE ÈÈYÀN FI Ń ṢÀNÍYÀN NÍPA AYÉ YÌÍ ÀTI ỌJỌ́ IWÁJÚ Ẹ̀DÁ ÈÈYÀN? JẸ́ KÁ WO DÍẸ̀ LÁRA ÀWỌN ÌṢÒRO TÁ À Ń KOJÚ.

  • FÍFI ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ LU JÌBÌTÌ: Ìwé ìròyìn The Australian sọ pé: “Ewu túbọ̀ ń pọ̀ sí i lórí íńtánẹ́ẹ̀tì lónìí torí pé oríṣiríṣi àwọn èèyàn burúkú ló ń ṣọṣẹ́ níbẹ̀, lára wọn ni àwọn tó ń bá ọmọdé ṣèṣekúṣe, àwọn tó ń halẹ̀ mọ́ni, àti àwọn tó ń dá wàhálà sílẹ̀ lórí íńtánẹ́ẹ̀tì. Èyí tó tiẹ̀ wá burú jù báyìí ni àwọn tó ń jí ìsọfúnni àwọn èèyàn kárí ayé. . . . Íńtánẹ́ẹ̀tì ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti máa hu àwọn ìwà tó burú jáì.”

  • OLÓWÓ Ń NÍ OWÓ SÍ I, TÁLÁKÀ Ń TÒṢÌ SÍ I: Ìròyìn kan tí àjọ Oxfam gbé jáde jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn olówó mẹ́jọ kan wà láyé yìí tó jẹ́ pé àpapọ̀ iye owó táwọn nìkan ní jẹ́ ìye kan náà pẹ̀lú àpapọ̀ owó tí ìdajì gbogbo èèyàn tó wà láyé yìí ní. Ó tún sọ pé: “Ètò ọrọ̀ ajé wa tó dẹnu kọlẹ̀ ń mú kí àwọn olówó máa lówó sí i, kí àwọn òtòṣì sì máa pọ̀ sí i.” Ẹ̀rù ń ba àwọn kan pé tí nǹkan bá ń bá a lọ báyìí, wàhálà lè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ kan.

  • ÌJÀ ÀTI INÚNIBÍNI: Lọ́dún 2018, àjọ United Nations Refugee Agency sọ pé: “Kò tíì sí àkókò kan tí àwọn èèyàn ń sá kúrò nílùú wọn bíi ti àkókò yìí.” Ohun tó ju mílíọ̀nù méjìdínláàádọ́rin (68,000,000) èèyàn ló ti fi ilé wọn sílẹ̀ nítorí ìjà tàbí inúnibíni. Ìròyìn yẹn tún sọ pé: “Kárí ayé, láàárín ìṣẹ́jú àáyá méjì-méjì, ó kéré tán, ẹnì kọ̀ọ̀kan ń sá kúrò nílùú rẹ̀ lójoojúmọ́.”

  • ÀYÍKÁ WA Ń BÀ JẸ́ SÍ I: Lọ́dún 2018, The Global Risks Report sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ewéko àti ẹranko ń dàwátì, àwọn èèyàn ń tú nǹkan olóró sínú afẹ́fẹ́ àti sínú òkun, èyí sì ń ṣàkóbá fún ìlera àwọn èèyàn. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn kòkòrò ni kò sí mọ́ ní àwọn ibì kan. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn kòkòrò yìí ló ń mú kí àwọn ewéko àti òdòdó gbèrú sí i. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ńsì fi kún un pé tí kò bá sí àwọn kòkòrò mọ́, wàhálà ńlá gbáà nìyẹn.” Bákan náà, àwọn òkìtì iyùn abẹ́ omi náà ti ń tán lọ. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tiẹ̀ sọ pé ó tó ìdajì àwọn òkìtì iyùn tó wà láyé tó ṣègbé láàárín ọgbọ̀n (30) ọdún sẹ́yìn.

Ǹjẹ́ nǹkan kan wà tá a lè ṣe láti mú kí ààbò àti ìfọ̀kànbalẹ̀ wà láyé? Àwọn kan rò pé ó yẹ kí ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kan wà fún àwọn èèyàn. Tó bá ri bẹ́ẹ̀, irú ẹ̀kọ́ wo ló yẹ kí wọ́n kọ́ àwọn èèyàn? Àpilẹ̀kọ tó kàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí.