Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

AYÉ DOJÚ RÚ

1 | Tọ́jú Ara Rẹ

1 | Tọ́jú Ara Rẹ

ÌDÍ TÍ Ọ̀RỌ̀ YÌÍ FI ṢE PÀTÀKÌ

Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí wàhálà bá wà nílùú, onírúurú ọ̀nà nìyẹn máa ń gbà ṣàkóbá fún ìlera àwọn èèyàn.

  • Bí àpẹẹrẹ, àyà àwọn èèyàn sábà máa ń já tí wàhálà bá ṣẹlẹ̀, tí wọn ò bá sì tètè gbé ọ̀rọ̀ náà kúrò lọ́kàn, ìyẹn lè mú kí wọ́n ṣàìsàn.

  • Tí nǹkan ò bá rí bó ṣe yẹ kó rí nílùú, ìyẹn lè ṣàkóbá fún ètò ìlera débi pé kò ní rọrùn láti tọ́jú àwọn aláìsàn.

  • Tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, ìyẹn lè má jẹ́ káwọn èèyàn rówó ra oúnjẹ aṣaralóore, oògùn àtàwọn nǹkan pàtàkì míì.

Ohun Tó Yẹ Kó O Mọ̀

  • Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tó le gan-an tàbí tí ọkàn ẹ̀ ò balẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò ní lè ronú bó ṣe tọ́, ó sì lè máa ṣe àwọn nǹkan táá ṣàkóbá fún ìlera ẹ̀. Ìyẹn sì lè mú kí àìsàn tó ń ṣe é burú sí i.

  • Tẹ́nì kan bá ń ṣàìsàn tí kò sì tọ́jú ara ẹ̀, ńṣe ni àìsàn náà á máa burú sí i, ó sì lè gbẹ̀mí ẹ̀.

  • Tára ẹ bá le dáadáa, wàá lè ronú lọ́nà tó tọ́, wàá sì lè ṣèpinnu tó dáa nígbà ìṣòro.

  • Tó ò bá tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ lówó lọ́wọ́ àwọn nǹkan kan wà tó o lè ṣe láti tọ́jú ara ẹ.

Ohun To O Lè Ṣe Ní Báyìí

Tí ọlọ́gbọ́n bá rí ohun kan tó lè pa á lára, á tètè wá nǹkan ṣe sí i. Ohun tó yẹ ká ṣe nìyẹn tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera wa. Tá a bá ń ṣe ìmọ́tótó bó ṣe yẹ, a ò ní tètè máa ṣàìsàn, tá a bá sì ṣàìsàn, kò ní le jù. Ó ṣe tán, wọ́n sọ pé ìmọ́tótó borí àrùn mọ́lẹ̀.

“A máa ń tọ́jú ara wa dáadáa a sì máa ń jẹ́ kí àyíká wa wà ní mímọ́ tónítóní. Ìyẹn jẹ́ ká dín iye tá à ń ná lórí ọ̀rọ̀ ìtọ́jú ara wa kù.”​—Andreas. *

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú ìwé yìí.