Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 2 2018 | Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

Ohun Méjìlá Tó Ń Mú Kí Ìdílé Láyọ̀

A máa ń gbọ́ nípa ohun tó fà á táwọn ìdílé kan fi tú ká. Àmọ́ àwọn ìdílé tó ń láyọ̀ ńkọ́, kí ló ń ràn wọ́n lọ́wọ́?

  • Láàárín ọdún 1990 sí 2015, iye àwọn tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún [50] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti fi ìlọ́po méjì ju ti tẹ́lẹ̀, nígbà tí àwọn tó jẹ́ ẹni ọdún márùnlélọ́gọ́ta [65] tó kọ ara wọn sílẹ̀ lọ sókè ní ìlọ́po mẹ́ta.

  • Àwọn òbí ò mọ ohun tí wọ́n máa ṣe mọ́: Àwọn kan sọ pé kí wọ́n máa gbóríyìn fáwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà, àwọn míì sọ pé kí wọ́n má ṣe gba gbẹ̀rẹ́ fún wọn rárá.

  • Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ni kò mọ àwọn nǹkan tó lè mú kí wọ́n ṣàṣeyọrí bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Àmọ́, òótọ́ ibẹ̀ ni pé . . .

  • Ìdílé lè láyọ̀, kó sì wà pẹ́ títí.

  • Àwọn òbí lè kọ́ bí wọ́n ṣe lè fi ìfẹ́ bá àwọn ọmọ wọn wí.

  • Àwọn ọ̀dọ́ sì lè kọ́ àwọn nǹkan tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà.

Àmọ́ báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe? Ẹ̀dà Jí! yìí máa sọ̀rọ̀ nípa ohun méjìlá tó máa jẹ́ kí ìdílé rẹ láyọ̀.

 

1: Jẹ́ Olóòótọ́

Ohun pàtàkì mẹ́ta tó lè mú kí àwọn tọkọtaya ṣe ara wọn lọ́kan.

2: Ìfọwọ́sowọ́pọ̀

Ǹjẹ́ ó ń ṣe ẹ́ bíi pé alájọgbé lásán ni ìwọ àti ẹnì kejì rẹ?

3: Ọ̀wọ̀

Mọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ àti ìwà tó máa jẹ́ kí ẹ̀yin méjéèjì lè máa bọ̀wọ̀ fún ara yín.

4: Ìdáríjì

Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má gbójú fo àìpé ẹnì kejì rẹ?

5: Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀

Ohun mẹ́ta tó o lè ṣe kí ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ lè sún mọ́ra.

6: Ìbáwí

Ṣé ìbáwí kì í jẹ́ kí ọmọ mọyì ara rẹ̀?

7: Ìwà Rere

Àwọn ìlànà wo ló yẹ kó o kọ́ àwọn ọmọ rẹ?

8: Àpẹẹrẹ Rere

Tó o bá fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu, o gbọ́dọ̀ máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fún wọn.

9: Ẹni Tó O Jẹ́

Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ ṣe lè dúró lórí ohun tí wọ́n gbà gbọ́?

10: Jẹ́ Ẹni Tó Ṣeé Gbọ́kàn Lé

Táwọn òbí rẹ bá gbọ́kàn lé ẹ, ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ṣe túbọ̀ ń dàgbà.

11: Máa Ṣiṣẹ́ Kára

Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè máa ṣiṣẹ́ kára ní báyìí tó o ṣì jẹ́ ọ̀dọ́, o máa ṣe àṣeyọrí nínú gbogbo nǹkan tó o bá ń ṣe.

12: Àfojúsùn

Tí ọwọ́ rẹ bá tẹ àfojúsùn kan, wàá gbà pé o lè ṣe òmí ì, àwọn èèyàn máa nífẹ̀ẹ́ rẹ, inú rẹ á sì máa dùn sí i.

Ohun Mí ì Tó Máa Ran Ìdílé Lọ́wọ́

Àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì lè ran ìdílé rẹ lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀.