Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojú Ìwòye Bíbélì

Ẹ̀mí Ìmoore

Ẹ̀mí Ìmoore

Ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn lẹ́mìí ìmoore. Ó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ìlera tó jí pépé, kí ìrònú ẹni já geere, kí ọkàn sì balẹ̀. Torí náà, ó yẹ kí gbogbo èèyàn jẹ́ ẹni tó moore.

Báwo ni ẹ̀mí ìmoore ṣe lè mú kéèyàn ní ìlera tó dáa?

OHUN TÁWON DÓKÍTÀ SỌ

Àpilẹ̀kọ kan nínú ìwé ìròyìn Harvard Mental Health Letter, sọ pé: “Ẹ̀mí ìmoore máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀ gan-an. Ẹ̀mí ìmoore ló ń jẹ́ ká ní èrò tí ó tọ́, ká rántí àwọn nǹkan rere tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, kí ìlera wa jí pépé, ká lè fara da ìṣòro ká sì lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì.”

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká jẹ́ ẹni tó moore. Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ fi ara yín hàn ní ẹni tí ó kún fún ọpẹ́.” Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ máa ń dúpẹ́ oore. Nígbà kan, ó ‘dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run láìdabọ̀’ nítorí pé àwọn èèyàn tó wàásù fún gba ọ̀rọ̀ tó sọ gbọ́. (Kólósè 3:15; 1 Tẹsalóníkà 2:13) Àmọ́ kì í ṣe téèyàn bá ń sọ pé “o ṣeun” nìkan lèèyàn máa ń láyọ̀, a tún gbọdọ̀ lẹ́mìí ìmoore. Ìyẹn gan-an ni kì í jẹ́ kéèyàn máa ronú pé òun lẹ́tọ̀ọ́ sí nǹkan, kó máa jowú tàbí kó máa di èèyàn sínú. Torí irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀ máa ń lé àwọn èèyàn sá lọ́dọ̀ ẹni, kì í sì jẹ́ kéèyàn láyọ̀.

Ó wúni lórí gan-an pé Ẹlẹ́dàá wa pàápàá máa ń mọyì oore táwa èdá èèyàn bá ṣe! Abájọ tí Hébérù 6:10 fi sọ pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.” Àbí ẹ ò rí nǹkan, Ẹlẹ́dàá wa kà á sí àìṣòdodo tí kò bá mọyì oore tá a ṣe!

“Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo. Ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ohun gbogbo, ẹ máa dúpẹ́.” 1 Tẹsalóníkà 5:16, 18.

Báwo ni ẹ̀mí ìmoore ṣe lè jẹ́ ká ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú àwọn míì?

OHUN TÓ MÁA Ń ṢẸLẸ̀

Bá a bá ń dúpẹ́ oore tẹ́nì kan ṣe fún wa tàbí fún ẹ̀bùn tó fún wa tàbí ọ̀rọ̀ rere tó sọ fún wa, ńṣe là ń fi hàn pé a mọyì ẹni náà. Kódà bó bá jẹ́ ẹni tá ò mọ̀ rí ló ṣoore fún wa, bóyá ó ṣílẹ̀kùn fún wa nígbà tá a fẹ́ wọlé, tá a bá dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, ó máa mọyì rẹ̀ gan-an.

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Jésù Kristi sọ pé: “Ẹ sọ fífúnni dàṣà, àwọn ènìyàn yóò sì fi fún yín. Wọn yóò da òṣùwọ̀n àtàtà, tí a kì mọ́lẹ̀, tí a mì pọ̀, tí ó sì kún àkúnwọ́sílẹ̀ sórí itan yín.” (Lúùkù 6:38) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí obìnrin adití kan tó ń jẹ́ Rose nìyẹn. Ìlú Vanuatu, tó wà ní erékùṣù South Pacific ló ń gbé.

Rose máa ń lọ sí ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn ìpàdé náà torí èdè adití kọ́ ni wọ́n fi ń ṣe ìpàdé, òun fúnra rẹ̀ kò gbọ́ èdè adití kò sì sẹ́ni tó lè ràn án lọ́wọ́. Nígbà tó yá, tọkọtaya kan tó mọ èdè adití dáadáa ṣèbẹ̀wò sí ìjọ náà, wọ́n sì rí ìṣòro tí Rose ní, ni wọ́n bá dá kíláàsì èdè adití sílẹ̀. Ohun tí wọ́n ṣe yìí wú Rose lórí gan-an. Ó ní: “Mo dúpẹ́ pé mo ní àwọn ọ̀rẹ́ púpọ̀ tó nífẹ̀ẹ́ mi.” Bí àwọn èèyàn ṣe ń gbọ́ ọ̀rọ̀ ìdúpẹ́ rẹ̀ tí wọ́n sì rí i bó ṣe ń kópa nínú ìpàdé ti tó ẹ̀bùn fún tọkọtaya tó ràn án lọ́wọ́. Rose tún mọyì ìsapá àwọn míì tó kọ́ èdè adití kí wọ́n lè máa bá a sọ̀rọ̀.Ìṣe 20:35.

“Ẹni tí ń rú ìdúpẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ rẹ̀ ni ó ń yìn [Ọlọ́run] lógo.”Sáàmù 50:23.

Báwo lo ṣe lè ní ẹ̀mí ìmoore?

OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ

Ohun tá a bá ń rò máa ń hàn nínú bí nǹkan ṣe rí lára wa. Èyí hàn nínú àdúrà tí Dáfídì gbà sí Ọlọ́run, ó ní: “Mo ti ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ; tinútinú ni mo ń fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ ṣe ìdàníyàn mi.” (Sáàmù 143:5) Èyí jẹ́ ká rí i pé Dáfídì jẹ́ ẹni tó mọnúúrò, ó sì mọpẹ́ dá. Ìdí nìyẹn tó fi máa ń ṣàṣàrò déédéé lórí gbogbo ohun tí Ọlọ́run ń ṣe fún un, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ní ẹ̀mí ìmoore jálẹ̀ ọjọ́ ayé rẹ̀.Sáàmù 71:5, 17.

Abájọ tí Bíbélì fi fún wa nímọ̀ràn pé: ‘Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.’ (Fílípì 4:8) Tá a bá ń “bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò,” àá jẹ́ ẹni tó máa ń ronú jinlẹ̀, ìyẹn ló lè jẹ́ ká ní ẹ̀mí ìmoore.

“Àṣàrò inú ọkàn-àyà mi yóò sì jẹ́ ti àwọn ohun òye.”Sáàmù 49:3.