Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Aráyé

Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Aráyé

Ohun Tá A Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Nípa Ọjọ́ Ọ̀la Aráyé

Ṣé Jésù ṣèlérí pé àwọn kan máa lọ sọ́run?

Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe bẹ́ẹ̀! Jésù alára jíǹde, ó sì lọ sọ́dọ̀ Bàbá rẹ̀ lọ́run. Àmọ́, ṣáájú ikú àti àjíǹde rẹ̀, ó sọ fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ mọ́kànlá pé: “Nínú ilé Baba mi, ọ̀pọ̀ ibùjókòó ni ń bẹ. . . . Mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín.” (Jòhánù 14:2) Àmọ́, àwọn díẹ̀ ló máa láǹfààní yìí. Jésù jẹ́ kí èyí ṣe kedere nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Má bẹ̀rù, agbo kékeré, nítorí pé Baba yín ti tẹ́wọ́ gba fífi ìjọba náà fún yín.”—Lúùkù 12:32.

Kí làwọn “agbo kékeré” máa ṣe lọ́run?

Ọlọ́run fẹ́ kí àwùjọ kékeré yìí wá bá Jésù jọba lọ́run. Báwo la ṣe mọ̀? Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó fi han àpọ́sítélì Jòhánù lójú ìran pé àwọn olóòótọ́ kan máa “ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 1:1; 5:9, 10) Ìròyìn ayọ̀ lèyí jẹ́. Ọ̀kan lára ohun tí ẹ̀dá èèyàn nílò jù lọ ni ìṣàkóso rere. Kí ni ìṣàkóso Jésù máa gbé ṣe? Jésù sọ pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá.” (Mátíù 19:28) Ìṣàkóso Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ máa yọrí sí “àtúndá,” tàbí dídá àwọn nǹkan pa dà sí ipò pípé irú èyí tí tọkọtaya àkọ́kọ́ gbádùn kí wọ́n tó dẹ́ṣẹ̀.

Kí ni ìlérí tí Jésù ṣe fáwọn èèyàn tó kù?

Ayé ni Ọlọ́run dá pé káwa èèyàn máa gbé, àmọ́ ọ̀run ni Ọlọ́run dá Jésù sí láti máa gbé. (Sáàmù 115:16) Torí náà ni Jésù fi sọ pé: “Ẹ̀yin wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso ìsàlẹ̀; èmi wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso òkè.” (Jòhánù 8:23) Jésù sọ nípa ọjọ́ ọ̀la àgbàyanu fáwọn èèyàn lórí ilẹ̀ ayé. Ó sọ nígbà kan pé: “Aláyọ̀ ni àwọn onínú tútù, níwọ̀n bí wọn yóò ti jogún ilẹ̀ ayé.” (Mátíù 5:5) Ohun tó wà nínú Sáàmù tí Ọlọ́run mí sí ni Jésù ń tọ́ka sí, ìyẹn ni pé: “Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:11, 29.

Torí náà, kì í ṣe àwọn “agbo kékeré,” tó ń lọ sọ́run nìkan ló máa ní ìyè àìnípẹ̀kun. Jésù tún sọ nípa ìrètí tó wà fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn. Ó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.

Báwo ni Ọlọ́run ṣe máa mú ìnira aráyé kúrò?

Jésù sọ pé aráyé máa rí ìdáǹdè kúrò lọ́wọ́ àwọn nǹkan méjì tó ń fa ìnira nígbà tó sọ pé: “Nísinsìnyí ni ṣíṣèdájọ́ ayé yìí; nísinsìnyí, olùṣàkóso ayé yìí ni a óò lé jáde.” (Jòhánù 12:31) Lákọ̀ọ́kọ́, Jèhófà máa ṣèdájọ́ àwọn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run tó ń fa ìnira, á sì pa wọ́n run. Ìkejì, Ọlọ́run máa lé Sátánì jáde, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kó ṣi aráyé lọ́nà mọ́.

Àwọn tó ti gbáyé rí, tí wọ́n ti kú láìní àǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run àti Kristi ńkọ́? Jésù sọ fún aṣebi tó ń kú lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.” (Lúùkù 23:43) Ọkùnrin yẹn àtàwọn ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn míì máa láǹfààní láti kọ́ nípa Ọlọ́run nígbà tí Jésù bá jí wọn dìde sínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Ó máa láǹfààní láti wà lára àwọn ọlọ́kàn tútù àtàwọn olóòótọ́ tó máa ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé.—Ìṣe 24:15.

Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 3 àti 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

“Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29