Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ohun Ṣíṣeyebíye Tó Wà Ní Adágún Títóbi Jù Lọ Ní Amẹ́ríkà Àárín

Àwọn Ohun Ṣíṣeyebíye Tó Wà Ní Adágún Títóbi Jù Lọ Ní Amẹ́ríkà Àárín

Àwọn Ohun Ṣíṣeyebíye Tó Wà Ní Adágún Títóbi Jù Lọ Ní Amẹ́ríkà Àárín

ÒÓTỌ́ ni pé orílẹ̀-èdè Nicaragua ò fi bẹ́ẹ̀ tóbi, ibẹ̀ ni adágún tó tóbi jù lọ ní Amẹ́ríkà Àárín wà, ìyẹn Adágún Nicaragua. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Adágún Nicaragua nìkan ni adágún omi tí kò ní iyọ̀ téèyàn ti lè rí oríṣi àwọn ẹja tó wà nínú òkun, irú bí ẹja ekurá, swordfish àti tarpon. Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì gbà pé omi òkun Pàsífíìkì ló ya wá sórí ilẹ̀, tí òkè ayọnáyèéfín kan sì wá pààlà sáàárín omi náà àti òkun. Bí iyọ̀ inú omi náà ti ń dín kù, omi náà bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ẹja tó wà níbẹ̀ lára mu.

Adágún náà tó ọgọ́jọ [160] kìlómítà ní gígùn, ó fẹ̀ tó àádọ́rin [70] kìlómítà níbùú, ó sì lè gba nǹkan bí òpó ìná mẹ́ta ní jíjìn. Ó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin [400] erékùṣù tó wà ní Adágún Nicaragua, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] lára àwọn erékùṣù yìí ló sì wà ní àgbègbè Asese tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po nítòsí Granada lápá àríwá adágún náà. Wọ́n máa ń pe àwọn erékùṣù yìí ní àwọn erékùṣù kéékèèké ti Granada.

Erékùṣù Ometepe ló tóbi jù lọ nínú àwọn erékùṣù tó wà ní adágún náà, àárín ló sì wà. Erékùṣù yìí tó kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ní gígùn, ó sì tó kìlómítà mẹ́tàlá [13] ní fífẹ̀, àwọn òkè ayọnáyèéfín méjì tí ilẹ̀ tóóró so pọ̀ láàárín ló wà ní erékùṣù yìí. Èyí tó ga jù lọ lára àwọn òkè méjì yìí ni òkè aboríṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Concepción, ó ga tó ẹgbẹ̀rin-dín-lọ́gbọ̀n àti ọgọ́rin-lé-méjì [5,282] ẹsẹ̀ bàtà. Òkè yìí máa ń yọ iná àti èéfín, ó sì rọrùn láti rí lápá àríwá erékùṣù náà. Òkè kejì ni wọ́n ń pè ní Madera, kì í sábà yọ iná àti èéfín, ó sì ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́rin, ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti àádọ́rin lé mẹ́ta [4,573] ẹsẹ̀ bàtà. Ewéko wà láyìíká òkè yìí, omi dárogún sínú kòtò kékeré kan tó wà lórí òkè náà, omi náà sì máa ń tutù.

Adágún Nicaragua wà lára àwọn ohun tó máa ń mú káwọn arìnrìn-àjò afẹ́ wá sí àgbègbè yìí. Wọ́n máa ń wá wo bí àgbègbè náà ṣe rẹwà tó àti ọ̀pọ̀ nǹkan àtijọ́ táwọn tó gbé níbẹ̀ nígbà kan rí lò. Àmọ́ àwọn nǹkan ṣíṣeyebíye míì ṣì wà ní Adágún Nicaragua tó tún yẹ ká mọ̀ nípa rẹ̀.

Àdúgbò Kan Tó Wà Lórí Omi

Àwọn ewéko, ẹyẹ àtàwọn ẹranko tó wà láwọn erékùṣù kéékèèké tó wà ní Granada ò lóǹkà. Àwọn òdòdó tó rẹwà pọ̀ lọ jàra láàárín igbó kìjikìji tó wà ní èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn erékùṣù náà. Àwọn ẹyẹ rírẹwà tó máa ń gbé nítòsí omi, irú bí ẹyẹ wádòwádò tó láwọ̀ búlúù, àwọn ẹyẹ lékeléke ńláńlá, idì ajẹja, anhinga àti ẹyẹ àgò ń gbé nítòsí adágún náà. Àwọn ìtẹ́ táwọn ẹyẹ ńlá tí wọ́n ń pè ní Montezuma oropendolas kọ́ máa ń fì dirọdirọ lórí àwọn igi ńláńlá tó wà léteetí igbó bí afẹ́fẹ́ tó ń wá látinú adágún náà ti ń fẹ́ lù wọ́n.

Àwọn èèyàn ń gbé láwọn kan nínú àwọn erékùṣù náà. Ilé àwọn apẹja wà níbẹ̀ àtàwọn ilé kéékèèké táwọn olówó máa ń dé sí lákòókò ìsinmi. Iléèwé, itẹ́ òkú, ilé oúnjẹ àti ilé ọtí sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú. Àwọn erékùṣù náà dà bí abúlé tàbí àdúgbò tó wà lórí omi.

Láràárọ̀, ọkọ̀ ojú omi kan tó láwọ̀ funfun àti àwọ̀ búlúù máa ń lọ láti erékùṣù kan sí òmíràn láti lọ gbé àwọn ọmọléèwé lọ síléèwé wọn. Ọkọ̀ ojú omi kan tó gbé àwọn tó ń ta èso àti ẹ̀fọ́ sì máa ń lọ láti erékùṣù kan sí òmíràn. Ojoojúmọ́ làwọn ọkùnrin tó ń ta àwọ̀n ìpẹja àtàwọn obìnrin tó ń fọ aṣọ máa ń wà láwọn erékùṣù náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ń wàásù láwọn erékùṣù yìí. Wọ́n máa ń wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn láti lọ sọ ìhìn rere Ìjọba Ọlọrun fún wọn. (Mátíù 24:14) Àmọ́, báwọn àdúgbò yìí ṣe rí síra ò jẹ́ kó rọrùn láti ní ibi tí wọ́n á ti máa pàdé pọ̀ láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Kí wọ́n lè ṣègbọràn sí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé “kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀,” àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ dá ọgbọ́n kan, wọ́n kọ́ ilé ìpàdé àkọ́kọ́, ìyẹn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó ń léfòó lórí omi!—Hébérù 10:25.

Gbọ̀ngàn Ìjọba Tó Ń Léfòó Lórí Omi

Lóṣù November ọdún 2005, tọkọtaya Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n máa ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù kó lọ sí ọ̀kan lára àwọn erékùṣù kéékèèké tó wà ní Granada. Lóṣù bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà yẹn, wọ́n pe àwọn èèyàn wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an pé èèyàn mẹ́rìndínlọ́gọ́rin [76] ló wá. Ìyẹn jẹ́ kí tọkọtaya yẹn rí i kedere pé ó yẹ káwọn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé Kristẹni déédéé ládùúgbò náà. Torí pé ó ṣòro láti rí ibi tó máa rọ̀ wọ́n lọ́rùn tí wọ́n á ti máa ṣèpàdé, tọkọtaya yìí dá ọgbọ́n kan. Wọ́n ronú láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan tó máa léfòó lórí omi, tí wọ́n á sì máa gbé káàkiri lọ sáwọn ibi tó bá ti rọrùn fáwọn èèyàn láti máa pàdé pọ̀.

Bí tọkọtaya tó jẹ́ akínkanjú, tí wọn ò sì tíì ṣe ohunkóhun tó ń léfòó lórí omi rí ṣe bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìkọ́lé náà nìyẹn. Odindi oṣù kan gbáko làwọn àtàwọn èèyàn mẹ́fà míì fi ṣiṣẹ́ náà. Ilé ìpàdé tó máa lè léfòó lórí omi ni wọ́n fẹ́ kọ́. Ó máa ní àwọn òpó onírin tí wọ́n jó pọ̀ lọ́nà tó máa lè gba dúrọ́ọ̀mù méjìlá nísàlẹ̀, wọ́n máa rọ atẹ́gùn sínú àwọn dúrọ́ọ̀mù náà kó bàa lè máa léfòó lórí omi. Pákó pẹlẹbẹ ni wọ́n máa tẹ́ sínú ilé ìpàdé náà, rọ́bà tarpaulin ni wọ́n á sì fi borí ilé náà. Alaalẹ́ làwọn tó ń kọ́ ilé yìí máa ń gbàdúrà nípa ilé náà torí kò dá wọn lójú pé gbọ̀ngàn náà máa léfòó. Àmọ́ ó léfòó!

June 10, ọdún 2006 ni wọ́n kọ́kọ́ ṣe Ìpàdé fún Gbogbo Ènìyàn nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n wọ́ ilé náà lọ sí apá ibòmíì lórí omi ní erékùṣù náà, káwọn tó wà lápá ibẹ̀ lè ṣe irú ìpàdé kan náà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ní láti rìn gba inú igbó kọjá fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú, èèyàn méjìdínláàádọ́ta [48] ló wá síbi ìpàdé méjèèjì. Inú gbogbo wọn ló sì dùn pé àwọn ti ní ibi táwọn ti lè máa jọ́sìn Ọlọ́run.

Àwọn nǹkan kan sábà máa ń wáyé nígbà tí wọ́n bá ń ṣèpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí. Bí ẹni tó ń sọ̀rọ̀ bá ṣe ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, àwọn tó wà láwùjọ máa ń gbọ́ ìró omi tó ń kọlu àwọn àpáta tàbí àwọn ọ̀bọ tó sábà máa ń ké láti ọ̀nà jíjìn. Nígbà tó yá àwọn èèyàn tó ń gbé ní erékùṣù yìí ti wá mọ gbọ̀ngàn yìí dáadáa. Wọ́n sábà máa ń juwọ́ nígbà tí wọ́n bá rí i tí wọ́n ń wọ́ ilé náà láti erékùṣù kan lọ sí òmíràn. Ó lé ní ogún [20] èèyàn tó máa ń pé jọ sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà lórí omi yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti wá ṣèpàdé, kí wọ́n sì lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ẹ ò rí i pé ohun ṣíṣeyebíye gbáà ni Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí!

Ní Erékùṣù Ometepe

Erékùṣù Ometepe wà ní nǹkan bí àádọ́ta [50] kìlómítà lápá gúúsù Granada. Torí pé erékùṣù yìí lẹ́wà tí ilẹ̀ ibẹ̀ sì jẹ́ ilẹ̀ ọlọ́ràá, ìyẹn jẹ́ kó wu ọ̀pọ̀ èèyàn láti máa gbé níbẹ̀ látìgbà pípẹ́ wá. Kódà, ibẹ̀ ni wọ́n ti rí ẹ̀rí pé ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti máa ń ṣiṣẹ́ àgbẹ̀ lórílẹ̀-èdè Nicaragua. Lónìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìlélógójì [42,000] èèyàn ló ń gbé ní erékùṣù Ometepe. Wọ́n máa ń pẹja, wọ́n sì ń ṣọ̀gbìn àgbàdo, ọ̀gẹ̀dẹ̀, kọfí àtàwọn ohun ọ̀gbìn míì. Àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko ìgbẹ́ tó wà ní erékùṣù yìí pàápàá tún kàmàmà. Lára wọn ni àwọn ẹyẹ ayékòótọ́ tí wọ́n máa ń kọ lálá, àwọn ẹyẹ magpie-jay tí wọ́n máa ń na ìyẹ́ wọn aláwọ̀ búlúù àti aláwọ̀ funfun bí wọ́n ti ń fò láti orí igi kan sí òmíràn àtàwọn ọ̀bọ capuchin olójú funfun, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì fẹ́ràn àwọn ọ̀bọ yìí dáadáa.

Bákan náà, àwọn tó ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń dé ọ̀dọ̀ àwọn tó ń gbé Erékùṣù Ometepe dáadáa. Látorí ẹni mẹ́jọ péré tó ṣèrìbọmi níbẹ̀ lọ́dún 1966, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ometepe báyìí ti di mẹ́tà-lé-lọ́gọ́sàn-án [183] nínu ìjọ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Ìjọ kọ̀ọ̀kan ló sì ti ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiẹ̀ níbi tó rọ̀ wọ́n lọ́rùn. Ní báyìí, tá a bá kó ọgbọ̀nlérúgba [230] èèyàn jọ ní erékùṣù yìí, a máa rí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan láàárín wọn.

Ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìṣòro ló ti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fínra fún ọ̀pọ̀ ọdún ní Ometepe. Bí àpẹẹrẹ, lọ́dún 1980, àwọn alátakò dáná sun Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní Mérida. Àmọ́, wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba míì lọ́dún 1984. Gbọ̀ngàn yìí ni wọ́n ń lò títí di ọdún 2003, kí wọ́n tó wá kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun tó rẹwà, ìyẹn sì múnú ọgọ́ta [60] èèyàn tó wà ní ìjọ náà dùn jọjọ.

Nílùú Moyogalpa, wọ́n kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan lọ́nà táá fi máa gba ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣàwọn ìpàdé tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá. Ilé náà ní òrùlé tó gùn dáadáa lápá ẹ̀yìn, pèpéle kan sì wà níbẹ̀. Wọ́n to àga sábẹ́ òrùlé náà níwájú pèpéle yìí. Ibẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà láwọn àgbègbè erékùṣù yìí ti máa ń pé jọ láti ṣe àwọn àpéjọ ńlá. Nígbà tí wọ́n bá ń ṣe àwọn àpéjọ yìí, ó máa ń rọrùn gan-an láti ṣèrìbọmi fáwọn tó bá ṣẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi nínú Adágún Nicaragua.—Mátíù 28:19.

Ṣáwọn Ohun Ṣíṣeyebíye Yìí Máa Tọ́jọ́?

Ọjọ́ pẹ́ tó ti ń dà bíi pé mìmì kan ò lè mi Adágún Nicaragua, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ torí pé ó tóbi. Àmọ́ ní báyìí, ó nílò àmójútó. Àwọn omi ìdọ̀tí tó ń ṣàn wọnú adágún náà láti àwọn iléeṣẹ́ ńláńlá, látọ̀dọ̀ àwọn àgbẹ̀ àti látorí àwọn ilẹ̀ táwọn èèyàn ti pa igbó run ti sọ omi adágún náà di ẹlẹ́gbin.

A ò lè sọ bóyá àwọn èèyàn tó ń gbé níbẹ̀ àti ìjọba orílẹ̀-èdè náà máa dáwọ́ sísọ adágún yìí di ẹlẹ́gbin dúró. Bí wọn ò bá tiẹ̀ lè ṣe bẹ́ẹ̀, Ẹlẹ́dàá máa rí i dájú pé gbogbo nǹkan ṣíṣeyebíye tó wà lórí ilẹ̀ ayé, títí kan àwọn adágún omi tó jojú ní gbèsè, àwọn erékùṣù tó fani lọ́kàn mọ́ra, àwọn ẹyẹ àtàwọn ẹranko ńláńlá nínú igbó ṣì wà nípamọ́ káwọn èèyàn onígbọràn lè jogún wọn. Bíbélì sọ pé: “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ.”—Sáàmù 37:29.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Gbọ̀ngàn Ìjọba tó ń léfòó tí wọ́n ń lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì