Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Bíbélì Máa Ń Sọni Dèèyàn Rere

Kí ló jẹ́ kí Ọ̀gbẹ́ni kan tó máa ń fi alùpùpù gbafẹ́ kiri, tí oògùn olóró àti eré ìdárayá ti di bárakú fún yàn láti máa fi àkókò tó pọ̀ wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? Kí ló mú kí ògbólógbòó onítẹ́tẹ́ kan jáwọ́ nínú àṣà tó ti di bárakú fún un yìí, tó sì wá ń ṣe iṣẹ́ tó yẹ ọmọlúwàbí láti máa fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀? Kí nìdí tí ọ̀dọ́bìnrin kan tí wọ́n tọ́ dàgbà gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ tó kọ àwọn ìlànà Bíbélì sílẹ̀ fi tún èrò rẹ̀ pa lórí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀? Jẹ́ ká gbọ́ ohun tí wọ́n ní í sọ.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: TERRENCE J. O’BRIEN

ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MẸ́TÀDÍNLỌ́GỌ́TA

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO MÁA Ń LO OÒGÙN OLÓRÓ, MO SÌ MÁA Ń FI ALÙPÙPÙ GBAFẸ́

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ìlú Brisbane tó jẹ́ olú-ìlú Queensland tí èrò pọ̀ sí ni mo ti lo ìgbà ọ̀dọ́ mi. Ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni ìdílé wa, àmọ́ nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́jọ, a ò lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì mọ́, a kò sì sọ̀rọ̀ nípa ìsìn mọ́. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́wàá, ìdílé wa kó lọ sí ìlú Gold Coast ní orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ìtòsí etíkun là ń gbé, torí náà lílúwẹ̀ẹ́ àti fífi pátákó sáré lórí omi ni mo fi bẹ̀rẹ̀ ìgbà èwe mi.

Pẹ̀lú gbogbo ìyẹn náà, mi ò láyọ̀ nígbà ọ̀dọ́ mi. Látìgbà tí mo ti wà lọ́mọ ọdún mẹ́jọ ni bàbá mi ti fi ìdílé wa sílẹ̀. Màmá mi fẹ́ ẹ̀lòmíì, ojoojúmọ́ ni ọtí mímu àti àríyànjiyàn máa ń wáyé nílé wa. Lẹ́yìn àríyànjiyàn kan tó gbóná janjan láàárín àwọn òbí mi ní alẹ́ ọjọ́ kan, mo jókòó lórí ibùsùn mi, mo sì jẹ́jẹ̀ẹ́ pé tí mo bá gbéyàwó, mi ò ní bá ìyàwó mi jiyàn láéláé. Láìka àwọn ìṣòro tá a ní sí, ìdílé wa tó jẹ́ ẹlẹ́ni mẹ́fà, ìyẹn màmá mi, àwa ọmọ àti ọkọ màmá mi ṣì ń gbé pa pọ̀.

Nígbà tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún [20] ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn tá a jọ jẹ́ ẹgbẹ́ ni wọ́n rú òfin ìjọba. Wọ́n ń mu igbó, tábà àti ọtí lámujù, wọ́n sì tún ń lo oògùn olóró. Bí èmi náà ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í bá wọn gbé ìgbésí ayé ta-ló-máa-mú-mi nìyẹn. Mo tún fẹ́ràn láti máa fi alùpùpù gbafẹ́ kiri. Bo tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo ti ṣubú lórí alùpùpù, síbẹ̀ mo ṣì fẹ́ràn láti máa gùn ún, mo tún wá pinnu pé mo máa gùn ún jákèjádò orílẹ̀-èdè Ọsirélíà.

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ní àǹfààní láti ṣe ohun tó wù mí, síbẹ̀ ìbànújẹ́ sábà máa ń bá mi nígbà tí mo bá ronú nípa ipò tí ayé wà àti bí ọ̀pọ̀ kò ṣe ka àwọn ìṣòro tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀dá èèyàn sí. Ó wù mí gan-an láti mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ìsìn àti ipò ayé. Àmọ́ nígbà tí mo bi àwọn àlùfáà Kátólíìkì méjì ni àwọn ìbéèrè mi, ṣe ni ìdáhùn wọn tún dá kún ìṣòro mi. Mo tún béèrè ìbéèrè kan náà lọ́wọ́ onírúurú àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì, síbẹ̀ náà àwọn ìdáhùn wọn kò lójú. Lẹ́yìn náà, ọ̀rẹ́ mi kan mu mi lọ bá Eddie, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹ̀ẹ̀mẹrin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni mo ní ìjíròrò pẹ̀lú Eddie, gbogbo àsìkò yìí ló sì máa ń lo Bíbélì láti dáhùn àwọn ìbéèrè mi. Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tá a ti jọ sọ̀rọ̀ ni mo ti mọ̀ pé mo ti rí ohun kan tó yàtọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, mi ò rí ìdí kankan tó fi yẹ kí n yí ọ̀nà ìgbésí ayé mi pa dà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lákòókò tí mò ń rìnrìn àjò jákèjádò orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, èmi àti Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tún jọ sọ̀rọ̀. Àmọ́ nígbà tí mo pa dà sí ìpínlẹ̀ Queensland, mi ò ní ìjíròrò kankan pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún odindi oṣù mẹ́fà.

Ó ṣẹlẹ̀ pé lọ́jọ́ kan, nígbà tí mò ń bọ̀ láti ibiṣẹ́, mo rí àwọn ọkùnrin méjì kan tí wọ́n múra dáadáa tí wọ́n gbé báàgì dání, wọ́n ń rìn lọ lójú pópó, mo fura pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n. Torí náà, mo sún mọ́ wọn, mo sì wá rí i pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n lóòótọ́, ni mo bá ní kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ tí mo fi bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé níbi tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn, mo tún lọ sí àpéjọ kan tí wọ́n ṣe ní Sydney lọ́dún 1973, èrò púpọ̀ ló wá síbẹ̀. Àmọ́ nígbà tí àwọn ìdílé mi, àgàgà màmá mi, gbọ́ nípa ohun tí mò ń ṣe, inú wọn kò dùn rárá. Nítorí èyí àti àwọn nǹkan míì, mi ò bá àwọn Ẹlẹ́rìí da nǹkan pọ̀ mọ́. Odindi ọdún kan ni mo fi fara mi jìn fún nǹkan míì tí mo nífẹ̀ẹ́ sí gan-an, ìyẹn bọ́ọ̀lù àfigigbá ìyẹn cricket.

Àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo wá rí i pé ìgbà tí mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni mo ní ayọ̀ tòótọ́. Ni mo bá tún wá wọn rí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí àwọn ìpàdé wọn. Mo tún pa àwọn ọ̀rẹ́ mi tó máa ń lo oògùn olóró tì.

Ohun tó mú kí n ṣe ìyípadà yìí ni ohun tí mo kọ́ nínú Bíbélì nípa Jóòbù. Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Bill ló ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́, bàbá yìí jẹ́ onínúure àmọ́ kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ. Lẹ́yìn tá a jíròrò nípa ìgbésí ayé Jóòbù, Bíll béèrè lọ́wọ́ mi pé, ta tún ni Sátánì fẹ̀sùn kàn pé kò fi tọkàntọkàn sin Ọlọ́run? (Jóòbù 2:3-5) Mo dárúkọ gbogbo àwọn tí mo mọ̀ pé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, Bill wá dáhùn, ó ní “Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, àwọn yẹn náà wà níbẹ̀.” Lẹ́yìn náà, ó wo ojú mi, ó wá sọ pé, “Sátánì ń sọ ohun kan náà nípa ìwọ náà!” Ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lára débi pé mo fẹ́rẹ̀ẹ́ ṣubú lórí àga tí mo jókòó lé. Kó tó di ọjọ́ yẹn, ó dá mi lójú pé òtítọ́ ni ohun tí mò ń kọ́. Àmọ́, ìsinsìnyí ló ṣẹ̀ṣẹ̀ wá yé mi pé ó yẹ kí n gbé ìgbésẹ̀ lórí ohun tí mò ń kọ́. Oṣù mẹ́rin lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mi ò mọ bí ìgbésí ayé mi ì bá ṣe rí báyìí, ká ní mi ò kọ́ láti máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà Bíbélì. Ó ṣeé ṣe kí n ti kú. Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ ni wọ́n ti kú torí oògùn olóró tàbí ọtí àmujù. Yàtọ̀ síyẹn, ìdílé wọn kò láyọ̀. Mo ronú pé bí ìgbésí ayé tèmi náà ì bá ṣe rí nìyẹn.

Mo ti gbéyàwó báyìí, èmi àti Margaret ìyàwó mi sì ń gbádùn iṣẹ́ ìyọ̀ǹda ara ẹni tí à ń ṣe ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Títí di báyìí, kò tíì sí ẹnì kankan nínú ìdílé mi tó ń sin Jèhófà pẹ̀lú mi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ọdún ni èmi àti Margaret ti ń láyọ̀ lẹ́nu kíkọ́ onírúurú èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, títí kan àwọn tọkọtaya, àwọn èèyàn yìí sì ti ṣe ìyípadà nínú ìgbésí ayé wọn bíi tèmi. Èyí sì ti jẹ́ ká ní ọ̀pọ̀ ọ̀rẹ́ gidi. Síwájú sí i, ìyàwó mi tó jẹ́ pé ìdílé Ẹlẹ́rìí ló ti wá ràn mí lọ́wọ́ láti mú ẹ̀jẹ́ tí mo jẹ́ ní nǹkan bí ogójì [40] ọdún sẹ́yìn ṣẹ. Ohun tó lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25] ni a ti jọ ń fayọ̀ gbé gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya. Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ni èrò wa máa ń dọ́gba, síbẹ̀ kò sí èdèkòyédè. A dúpẹ́ fún àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: MASAHIRO OKABAYASHI

ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MỌ́KÀNDÍNLÓGÓJÌ

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JAPAN

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MO MÁ A Ń TA TẸ́TẸ́

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Iwakura ni mo dàgbà sí, nǹkan bíi wákàtí kan ni sí ìlú Nagoya tí èèyàn bá wọ ọkọ̀ ojú irin. Mo rántí pé ẹni jẹ́jẹ́ ni bàbá àti màmá mi. Àmọ́ nígbà tó yá, mo wá mọ̀ pé yakuza tàbí ọ̀daràn ni bàbá mi, owó tó sì ń rí nídìí jìbìtì ló fi ń gbọ́ bùkátà ìdílé wa tó jẹ́ ẹlẹ́ni márùn-ún. Ojoojúmọ́ ló máa ń mu ọtí lámujù, nígbà tí mo wà ní ọmọ ogún [20] ọdún, àìsàn ìsúnkì ẹ̀dọ̀ pa á.

Ọmọ orílẹ̀-èdè Korea ni bàbá mi, torí ìdí èyí, àwọn aládùúgbò wa sábà máa ń ṣe ẹ̀tanú sí wa. Èyí àti àwọn ìṣòro míì mú kí ipò nǹkan nira fún mi nígbà tí mo wà ní ọmọdé. Mo lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga, àmọ́ ẹ̀ẹ̀kọ̀ọ̀kan ni mo máa ń lọ, lẹ́yìn ọdún kan mi ò lọ mọ́. Kò rọrùn fún mi láti rí iṣẹ́, torí pé ọlọ́pàá ti mú mi rí àti pé bàbá mi nìkan ni ọmọ orílẹ̀-èdè Korea. Nígbà tó yá mo rí iṣẹ́ kan, àmọ́ mo fi orúnkún mi ṣèṣe, bí mi ò ṣe lè ṣiṣẹ́ agbára mọ́ nìyẹn.

Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fi owó tí mò ń rí nídìí tẹ́tẹ́ tí wọ́n máa ń fi bọ́ọ̀lù kékeré kan gbá tí wọ́n ń pè ní pachinko gbọ́ bùkátà ara mi nìyẹn. Lákòókò yẹn, èmi àti ọmọbìnrin kan la jọ ń gbé, ó fẹ́ kí n wá iṣẹ́ gidi kan, kí n sì gbé òun ní ìyàwó. Àmọ́ owó tí mò ń rí nídìí tẹ́tẹ́ yìí kì í ṣe kékeré, torí náà kò wù mí láti yí ọ̀nà ìgbésí ayé mi pa dà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lọ́jọ́ kan, Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan wá sílé wa ó sì fún mi ní ìwé Life—How Did It Get Here? By Evolution or by Creation? Mi ò tíì ronú lórí ìbéèré yìí rí. Nígbà tí mo ka ìwé yìí, mo gbà láti mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì. Ó ti pẹ́ tí mo ti máa ń ronú lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí ẹni tó ti kú. Ìdáhùn Bíbélì tó ṣe kedere tí mo rí sí ìbéèrè yìí àti àwọn ìbéèrè míì ṣe mí bíi pé ìpẹ́ ṣí kúrò lójú mi.

Mo rí ìdí tó fi yẹ kí ń fi ohun tí mò ń kọ́ látinú Bíbélì sílò. Torí náà, mo fi orúkọ ìgbéyàwó mi sílẹ̀ lábẹ́ òfin, mi ò mu sìgá mọ́, mo gé irun mi tó gùn tí mo pa láró, mo sì tún ara mi ṣe. Mo tún jáwọ́ nínú tẹ́tẹ́ títa.

Kò sí èyí tó rọrùn nínú àwọn àyípadà yìí. Bí àpẹẹrẹ, agbára èmi nìkan kò gbé e láti fi tábà mímu sílẹ̀. Àmọ́ pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá àti ìtìlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run, mo jáwọ́ nínú rẹ̀. Kò tán síbẹ̀ o, iṣẹ́ tí mo rí lẹ́yìn tí mo fi tẹ́tẹ́ títa sílẹ̀ kò rọrùn rárá. Iye owó tí mò ń rí níbẹ̀ kò ju ìlàjì iye tí mò ń rí nídìí tẹ́tẹ́ títa lọ, iṣẹ́ náà le, ó sì ń tánni lókun. Ohun tó wà nínú ìwé Fílípì 4:6, 7 ló ràn mí lọ́wọ́ ní àwọn àkókò tó nira yìí. Ó ní: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì ti rí i pé òótọ́ ni ìlérí yìí.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Inú ìyàwó mi kò dùn nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tó rí àwọn ìyípadà tó lágbára tí mò ń ṣe nígbèésí ayé mi, lòun náà bá bẹ̀rẹ̀ sí i kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wa, ó sì ń bá mi lọ sí àwọn ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ní báyìí, Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni àwa méjèèjì. Àǹfààní ló jẹ́ láti máa sin Ọlọ́run pa pọ̀!

Kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo rò pé mo láyọ̀. Àmọ́ ìsinsìnyí ni mo mọ ohun tí ayọ̀ tòótọ́ jẹ́. Lóòótọ́, kò rọrùn láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò, àmọ́ ó dá mi lójú pé èyí gan-an lọ̀nà tó dáa jù lọ láti gbé ìgbésí ayé ẹni.

ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ

ORÚKỌ: ELIZABETH JANE SCHOFIELD

ỌJỌ́ ORÍ: ỌDÚN MÁRÙNDÍNLÓGÓJÌ

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ILẸ̀ GẸ̀Ẹ́SÌ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ÀRÍYÁ NI MO MÁA Ń FI GBOGBO ÒPIN Ọ̀SẸ̀ ṢE

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Abúlé kékeré kan tó ń jẹ́ Hardgate nítòsí ìlú Glasgow ni mo dàgbà sí. Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún méje, màmá mi ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17], fàájì ló gbà mí lọ́kàn nígbà yẹn, èmi àti àwọn ọ̀rẹ́ mi tá a jọ ń lọ síléèwé máa ń lọ ṣe fàájì ní alaalẹ́, a máa ń gbọ́ àwọn orin ọlọ́rọ̀ wótòwótò, a sì máa ń mu ọtí líle. Kò sí ìfẹ́ Ọlọ́run lọ́kàn mi nígbà yẹn. Àríyá ni mo máa ń lọ ní gbogbo òpin ọ̀sẹ̀. Àmọ́ ṣá o, gbogbo èyí yí pa dà nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mọ́kànlélógún [21].

Nígbà tí mo lọ kí àwọn mọ̀lẹ́bí mi tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Northern Ireland. Mo rí ìwọ́de kan tí àwọn onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì ṣe. Ìkórìíra àti ìtara òdì tí mo rí láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì àti àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì lákòókò yẹn dẹ́rù bà mí. Ó mú kí n ronú jinlẹ̀. Mo rántí àwọn nǹkan tí màmá mi ti kọ́ mi látinú Bíbélì, mo sì mọ̀ pé Ọlọ́run kò lè tẹ́wọ́ gba àwọn tó kọ àwọn ìlànà onífẹ̀ẹ́ rẹ̀ sílẹ̀. Ó wá yé mi pé, ìfẹ́ tara mi ni mò ń lé, mi ò sì gbé ìgbésí ayé mi bí Ọlọ́run ṣe fẹ́. Torí náà, mo pinnu pé tí mo bá ti pa dà dé ilé ní orílẹ̀-èdè Scotland, màá fara balẹ̀ wádìí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ẹsẹ̀ mi kọ́lẹ̀ lọ́jọ́ tí mo kọ́kọ́ pa dà lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú ìbílẹ̀ mi. Àmọ́, gbogbo àwọn tó wà ní ìpàdé náà jẹ́ kára mi balẹ̀. Bí mo ṣe ń fi àwọn ohun tí mò ń kọ́ nínú Bíbélì sílò, obìnrin kan nínú ìjọ fi ìfẹ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ hàn sí mi, obìnrin yìí ṣèèyàn gan-an. Ó ràn mí lọ́wọ́ gan-an kí n lè pa dà rí ara mi bí ara ìjọ náà. Àwọn ọ̀rẹ́ mi àtijọ́ tún ń ké sí mi láti wá sí ibi tá a ti máa ń ṣe fàájì ní alaalẹ́, àmọ́ mo sọ fún wọn pé ní báyìí, mo ti ṣe tán láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò nígbèésí ayé mi. Nígbà tó yá, wọ́n fi mí sílẹ̀.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwé òfin ni mo ka Bíbélì sí. Àmọ́ ní báyìí, èrò mi ti yí pa dà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ó ní bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, àwọn náà sì ní ibi tí wọ́n kù sí bíi ti èmi náà. Àwọn náà ṣàṣìṣe, àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run dárí jì wọ́n nígbà tí wọ́n ronú pìwà dà láti ọkàn wá. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo kọ àwọn ìlànà Ọlọ́run sílẹ̀ nígbà tí mo wà ní ọ̀dọ́, ó dá mi lójú pé á dárí jì mi á sì gbàgbé àṣìṣe tí mo ti ṣe tí mo bá sapá láti ṣe ohun tó fẹ́.

Ìwà màmá mi náà jọ mí lójú gan-an ni. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé, mo fi Ọlọ́run sílẹ̀, màmá mi ń bá ìjọsìn rẹ̀ nìṣó. Àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ màmá mi tó dúró digbí jẹ́ kí n rí i pé ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ láti sin Jèhófà. Nígbà tí mo wà ní kékeré tí mo sì máa ń bá màmá mi lọ wàásù láti ilé-dé-ilé, mi ò kì í gbádùn rẹ̀, mi kì í sì í pẹ́ púpọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àmọ́ ní báyìí, mo fẹ́ wo bí ìlérí tí Jésù ṣe nínú Mátíù 6:31-33 ṣe jẹ́ òótọ́ tó. Ó ní: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ . . . Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo fi iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ mi tó ń gba ọ̀pọ̀ àkókò sílẹ̀, mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àbọ̀ọ̀ṣẹ́, mo sì wá ń fi àkókò tó pọ̀ wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Nígbà tí mo ṣì wà ní ọmọdé, tí mo sì ń fi gbogbo òpin ọ̀sẹ̀ ṣe fàájì, mi ò nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ìgbésí ayé mi kò lójú. Àmọ́, ní báyìí tí mo ti ń fi gbogbo àkókò mi sin Jèhófà, mo nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Ìgbésí ayé mi ti wá nítumọ̀. Mo ti ní ọkọ báyìí, èmi àti ọkọ mi sì ń lọ láti ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan sí òmíràn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti fún wọn níṣìírí. Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ ni mo ka iṣẹ́ yìí sí ní ìgbésí ayé mi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó fún mi láǹfààní lẹ́ẹ̀kan sí i!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

“Láti ọjọ́ àkọ́kọ́ tá a jọ sọ̀rọ̀ ni mo ti mọ̀ pé mo ti rí ohun kan tó yàtọ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn, mi ò rí ìdí kankan tó fi yẹ kí n yí ọ̀nà ìgbésí ayé mi pa dà”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

“Agbára èmi nìkan kò gbé e láti fi tábà mímu sílẹ̀. Àmọ́ pẹ̀lú àdúrà àtọkànwá àti ìtìlẹ́yìn Jèhófà Ọlọ́run, mo jáwọ́ nínú rẹ̀”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, ìwé òfin ni mo ka Bíbélì sí. Àmọ́ ní báyìí, èrò mi ti yí pa dà. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí í rí i pé ó ní bí nǹkan ṣe máa ń rí lára àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn, àwọn náà sì ní ibi tí wọ́n kù sí bíi ti èmi náà”