Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run?

Ǹjẹ́ Èèyàn Lè Mọ Orúkọ Ọlọ́run?

Kò sí àní-àní pé àpọ́nlé ńlá ló jẹ́ tó o bá láǹfààní láti fi orúkọ tí ẹni pàtàkì kan ń jẹ́ pè é nígbà tó nawọ́ sí ẹ pé kí o kí òun. Ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé orúkọ oyè bí “Ààrẹ,”  “Kábíyèsí,” tàbí  “Olóyè” la máa fi ń ṣáájú orúkọ àwọn ẹni pàtàkì. Torí náà, bí ẹnì kan tó wà ní ipò ọlá bá dìídì sọ fún ọ pé kó o máa fi orúkọ tóun ń jẹ́ gan-an pe òun tó o bá fẹ́ bá òun sọ̀rọ̀, wàá mọyì àǹfààní yìí gan-an.

ỌLỌ́RUN tòótọ́ sọ fún wa nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tún ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, irú bí “Ẹlẹ́dàá,” “Olódùmarè” àti “Olúwa Ọba Aláṣẹ,” síbẹ̀, ó fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láǹfààní láti máa fi orúkọ tó ń jẹ́ gan-an pè é.

Bí àpẹẹrẹ, lákòókò kan tí wòlíì Mósè ń bẹ Ọlọ́run, ó bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí pé: “Dákun, Jèhófà.” (Ẹ́kísódù 4:10) Nígbà ìyàsímímọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, Sólómọ́nì Ọba bẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ pé: “Ìwọ Jèhófà.” (1 Àwọn Ọba 8:22, 23) Nígbà tí wòlíì Aísáyà ń gbàdúrà nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Ìwọ, Jèhófà, ni Baba wa.” (Aísáyà 63:16) Kò sí iyè méjì pé, Bàbá wa ọ̀run ń fẹ́ ká máa fi orúkọ òun pe òun.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe pàtàkì láti máa pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, ìyẹn Jèhófà, ọ̀pọ̀ nǹkan ló rọ̀ mọ́ mímọ orúkọ yẹn. Nígbà tí Jèhófà ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e, ó ṣèlérí pé: “Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.” (Sáàmù 91:14) Ó ṣe kedere pé àwọn nǹkan kan wà tó rọ̀ mọ́ mímọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe pàtàkì téèyàn bá fẹ́ rí ààbò Ọlọ́run. Kí ló wá yẹ kó o ṣe kó o tó lè mọ ẹni tó ń jẹ́ Jèhófà?