Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Olùṣọ́ Àgùntàn

Bí Ìgbésí Ayé Ṣe Rí Lákòókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì—Olùṣọ́ Àgùntàn

“Bí olùṣọ́ àgùntàn ni yóò ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo ẹran ọ̀sìn rẹ̀. Apá rẹ̀ ni yóò fi kó àwọn ọ̀dọ́ àgùntàn jọpọ̀; oókan àyà rẹ̀ sì ni yóò gbé wọn sí.”—AÍSÁYÀ 40:11.

Ọ̀PỌ̀LỌPỌ̀ ìgbà ni Bíbélì mẹ́nu ba àwọn olùṣọ́ àgùntàn, bẹ̀rẹ̀ láti inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì títí dé Ìṣípayá. (Jẹ́nẹ́sísì 4:2; Ìṣípayá 12:5) Olùṣọ́ àgùntàn ni àwọn ẹni pàtàkì bíi Ábúráhámù, Mósè àti Dáfídì Ọba. Dáfídì sọ ojúṣe olùṣọ́ àgùntàn rere àti bí ọ̀rọ̀ àwọn àgùntàn ṣe máa ń jẹ ẹ́ lógún tó lọ́nà tó wúni lórí. Ásáfù sọ nínú sáàmù kan tó kọ nínú Bíbélì pé Dáfídì jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn lórí àwọn ènìyàn Ọlọ́run láyé àtijọ́.—Sáàmù 78:70-72.

Nígbà tí Jésù wà láyé, iṣẹ́ gidi ni àwọn èèyàn ṣì ka iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn sí. Jésù sọ pé òun ni “olùṣọ́ àgùntàn àtàtà,” ó sì sábà máa ń fi ìwà dáadáa tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ pàtàkì. (Jòhánù 10:2-4, 11) Kódà, Bíbélì fi Jèhófà Ọlọ́run Olódùmarè wé “olùṣọ́ àgùntàn.”—Aísáyà 40:10, 11; Sáàmù 23:1-4.

Irú àwọn ẹran ọ̀sìn wo ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń bójú tó? Báwo ni iṣẹ́ wọn ṣe rí? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ lára àwọn òṣìṣẹ́ aláápọn yìí?

Àwọn Àgùntàn àti Ewúrẹ́

Ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì àtijọ́, ó jọ pé irú àgùntàn tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn sábà máa ń dà ni àwọn àgùntàn ilẹ̀ Síríà tí ìrù wọn máa ń fẹ̀, tí irun ara wọn sì máa ń pọ̀. Àgbò àwọn àgùntàn náà ló máa ń ní ìwo, abo wọn kì í ní. Àwọn ẹran ọ̀sìn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ yìí rọrùn láti dà, àmọ́ wọn kì í lè dáàbò bo ara wọn lọ́wọ́ ewu àti àwọn ẹranko tó bá fẹ́ pa wọ́n jẹ.

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn tún máa ń da àwọn ewúrẹ́. Àwọn ewúrẹ́ náà sábà máa ń jẹ́ dúdú tàbí aláwọ̀ ilẹ̀. Torí pé etí wọn gùn, tí wọ́n sì máa ń gbọ̀n ọ́n lébélébé, ẹ̀gún sábà máa ń fà á ya nígbà tí wọ́n bá ń gun òkè tó dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ tàbí tí wọ́n bá ń jẹko láàárín àwọn igi kéékèèké ẹlẹ́gùn-ún.

Ìgbà gbogbo ni olùṣọ́ àgùntàn ní láti máa sapá gan-an láti tọ́ àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ rẹ̀ sọ́nà kí wọ́n lè máa tẹ̀ lé ohun tí ó bá sọ. Síbẹ̀síbẹ̀, olùṣọ́ àgùntàn rere kì í yéé fọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ tó ń dà kiri, kódà á tún ní orúkọ tó fi ń pè wọ́n tí wọ́n á sì gbọ́.—Jòhánù 10:14, 16.

Iṣẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn ní Àsìkò Kọ̀ọ̀kan Láàárín Ọdún

Nígbà ìrúwé, ojoojúmọ́ ni olùṣọ́ àgùntàn sábà máa ń da àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ láti ọgbà ẹran tó wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé rẹ̀ lọ sí pápá ìjẹko tí ewéko tútù yọ̀yọ̀ wà nítòsí abúlé rẹ̀. Láàárín àsìkò yìí àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ̀ máa ń bímọ, èyí sì máa ń mú kí agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ sí i. Ìgbà yìí kan náà ni àwọn òṣìṣẹ́ máa ń rẹ́ irun púpọ̀ tí àwọn àgùntàn hù nígbà òtútù, ìgbà àjọyọ̀ ló sì máa ń jẹ́!

Ẹnì kan ní abúlé lè ní ìwọ̀nba àgùntàn díẹ̀. Torí náà, ó lè gba olùṣọ́ àgùntàn kan tó máa da àwọn ẹran rẹ̀ yẹn pọ̀ mọ́ agbo ẹran míì. Ìwà kan tí àwọn èèyàn mọ̀ mọ́ àwọn olùṣọ́ àgùntàn tí wọ́n bá háyà ni pé wọn kì í sábà mójú tó ẹran ọ̀sìn ti àwọn ẹlòmíì bí ẹran ọ̀sìn tiwọn fúnra wọn.—Jòhánù 10:12, 13.

Lẹ́yìn tí àwọn èèyàn bá ti kórè àwọn oko tó wà nítòsí abúlé, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń kó agbo ẹran wọn lọ síbẹ̀, kí wọ́n lè jẹ èéhù tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọ jáde àti àwọn ọkà tó bá ṣẹ́ kù sára pòròpórò tó wà níbẹ̀. Tó bá ti wá di ìgbà ẹ̀rùn, wọ́n á da ẹran ọ̀sìn wọn lọ sí àwọn ilẹ̀ olókè tó tutù kí wọ́n lè rí ewéko jẹ. Ìta nínú pápá ni àwọn olùṣọ́ àgùntàn yìí máa wà fúngbà pípẹ́ láìlọ sílé, tí wọ́n á máa da ẹran ọ̀sìn wọn káàkiri, kí wọ́n lè máa jẹko ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè tó ní koríko tútù. Tó bá wá di alẹ́, wọ́n á máa ṣọ́ agbo ẹran wọn nínú pápá lóru mọ́jú. Nígbà míì, ó lè jẹ́ inú ihò àpáta ló máa kó ẹran ọ̀sìn rẹ̀ sí mọ́jú, láti lè dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn akátá àti ìkookò. Tí igbe ìkookò bá dẹ́rù ba agbo àgùntàn lóru, olùṣọ́ àgùntàn yóò fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ̀rọ̀ láti fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀, wọ́n á sì gbé jẹ́ẹ́.

Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, olùṣọ́ àgùntàn máa ń ka iye àgùntàn rẹ̀, yóò sì yẹ̀ wọ́n wò láti wo èyí tí ara rẹ̀ kò bá le. Tó bá di àárọ̀, yóò pè wọ́n, gbogbo wọn á sì tẹ̀ lé e lọ sí ibi tí wọ́n ti máa jẹko. (Jòhánù 10:3, 4) Ní ọ̀sán, àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń da ẹran wọn lọ sí ibi ìsun omi tó tutù kí wọ́n lè mu omi. Tí àwọn ìsun omi bá ti gbẹ, olùṣọ́ àgùntàn máa ń da ẹran rẹ̀ lọ sí ìdí kànga, yóò sì pọn omi fún wọn láti mu.

Tó bá ti ń di ọwọ́ ìparí ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, olùṣọ́ àgùntàn lè kó agbo ẹran rẹ̀ lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ etíkun tàbí ibi àfonífojì kan. Tí òjò ìgbà òtútù bá sì ti ń bẹ̀rẹ̀, yóò kó wọn pa dà wálé, ibẹ̀ ni wọn yóò sì wà ní gbogbo ìgbà òtútù. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, eji wọwọ àti òjò yìnyín àti yìnyín tó máa ń bolẹ̀ nígbà òtútù ni yóò pa wọ́n dà nù. Láti oṣù November títí di ìgbà ìrúwé, àwọn olùṣọ́ àgùntàn kì í da ẹran wọn lọ jẹko ní pápá.

Ohun Tí Wọ́n Máa Ń Lò

Aṣọ tí àwọn olùṣọ́ àgùntàn máa ń wọ̀ kì í ṣe aṣọ aláràbarà, ṣùgbọ́n ó máa ń nípọn dáadáa. Wọ́n máa ń wọ ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ kan tó gùn. Wọ́n lè wá wọ ẹ̀wù àwọ̀lékè tí wọ́n fi awọ àgùntàn ṣe, tí wọ́n ti yí ibi tó nírun lára rẹ̀ sínú, nítorí òjò àti atẹ́gùn tó tútù nini lóru. Wọ́n máa ń wọ sálúbàtà kí òkúta àti ẹ̀gún má bàa gún wọn lẹ́sẹ̀, wọ́n á sì fi aṣọ tí wọ́n fi òwú ṣe wé orí.

Àwọn nǹkan tí olùṣọ́ àgùntàn sábà máa ń lò nìyí: Àpò awọ tí ó máa ń kó oúnjẹ sí, irú bíi búrẹ́dì, èso ólífì, àwọn èso gbígbẹ àti wàràkàṣì (1); kùmọ̀ tí ó máa ń lò bí ohun ìjà, èyí tí wọ́n ti gbá àwọn nǹkan pẹlẹbẹ-pẹlẹbẹ tí ẹnu wọn mú wọ̀ ní orí, ó sábà máa ń gùn tó mítà kan (2); ọ̀bẹ (3); ọ̀pá tí ó máa fi ń tilẹ̀ tí ó bá ń rìn tàbí tí ó bá ń gun òkè (4); ohun tí ó máa ń fi rọ omi tó máa mu dání (5); ohun ìfami tó ṣeé ká pa pọ̀ tí ó máa fi ń pọnmi nínú kànga tó jìn (6); kànnàkànnà tí ó fi ń ju òkúta sí ẹ̀gbẹ́ àgùntàn tàbí ewúrẹ́ tó bá fẹ́ jẹ̀ lọ kúrò láàárín agbo, láti fi dẹ́rù bà á kó lè pa dà tàbí kí ó fi lé ẹranko tó bá ń dọdẹ ẹran ọ̀sìn rẹ̀ jìnnà (7); fèrè tí wọ́n fi esùsú ṣe tí yóò máa fọn láti fi dára yá tàbí láti tu agbo ẹran rẹ̀ lára (8).

Bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe ń tọ́jú àwọn ẹran ọ̀sìn yìí, wọ́n máa ń rí àwọn nǹkan téèyàn nílò lára wọn, irú bíi wàrà àti ẹran jíjẹ. Wọ́n máa ń fi irun àti awọ àgùntàn ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn nǹkan míì, wọ́n sì tún máa ń fi ṣe aṣọ àti ìgò awọ. Wọ́n máa ń fi irun ewúrẹ́ hun aṣọ, wọ́n sì máa ń fi àgùntàn àti ewúrẹ́ rúbọ.

Wọ́n Jẹ́ Àpẹẹrẹ Tó Yẹ Ká Tẹ̀ Lé

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn rere máa ń jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, ẹni tó ṣeé fọkàn tẹ̀ àti onígboyà. Wọ́n tiẹ̀ máa ń fẹ̀mí wọn wewu kí wọ́n lè dáàbò bo àwọn àgùntàn.—1 Sámúẹ́lì 17:34-36.

Abájọ tí Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe fi iṣẹ́ olùṣọ́ àgùntàn ṣàpèjúwe bó ṣe yẹ kí àwọn alábòójútó máa ṣe nínú ìjọ Kristẹni. (Jòhánù 21:15-17; Ìṣe 20:28) Bíi ti àwọn olùṣọ́ àgùntàn ayé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni lóde òní ‘máa ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run tí ń bẹ lábẹ́ àbójútó wọn, kì í ṣe lábẹ́ àfipáṣe, bí kò ṣe tinútinú; bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe nítorí ìfẹ́ fún èrè àbòsí, bí kò ṣe pẹ̀lú ìháragàgà.’—1 Pétérù 5:2.