Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀: ǸJẸ́ Ó YẸ KÍ O GBÁRA LÉ Ẹ̀SÌN?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí O Yẹ Ẹ̀sìn Rẹ Wò Dáadáa?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kí O Yẹ Ẹ̀sìn Rẹ Wò Dáadáa?

Ká sọ pé wọ́n fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ fún ẹnì kan nítorí àìsàn kan tó fẹ́ gba ẹ̀mí rẹ̀. Ó dájú pé ẹni náà máa ní láti fọkàn tán dókítà tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ náà fún un, torí pé ẹ̀mí rẹ̀ dọwọ́ dókítà yẹn. Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu nígbà náà kí ẹni náà lọ wádìí nípa bí dókítà yẹn ṣe mọṣẹ́ tó?

Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì pé kí o fara balẹ̀ yẹ ẹ̀sìn tó ò ń ṣe wò dáadáa. Ìdí sì ni pé, bí àárín ìwọ àti Ọlọ́run ṣe máa rí wà lọ́wọ́ ẹ̀sìn tí o bá ń ṣe. Bíi tẹni tó fẹ́ ṣe iṣẹ́ abẹ yẹn, ìgbàlà rẹ lọ́jọ́ iwájú sinmi lórí irú ẹ̀sìn tí o bá ń ṣe.

Jésù sọ ìlànà tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀sìn tòótọ́ ni à ń ṣe. Ó sọ pé: “Igi kọ̀ọ̀kan ni a ń mọ̀ nípasẹ̀ èso tirẹ̀.” (Lúùkù 6:44) Bí àpẹẹrẹ, tí o bá wo ẹ̀sìn tàbí ìjọ kan, irú èso wo ni ó ń so? Ṣé kì í ṣe ìwàásù lórí owó ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọn máa ń ṣe ṣáá? Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ìjọ wọn ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ ogun àti ìwà rere? Ǹjẹ́ ó tiẹ̀ yẹ kéèyàn gbára lé ẹ̀sìn èyíkéyìí? Ní báyìí, jẹ́ ká jọ ṣàyẹ̀wò àwọn àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.

“Igi kọ̀ọ̀kan ni a ń mọ̀ nípasẹ̀ èso tirẹ̀.”—Lúùkù 6:44