Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ Ọ̀RỌ̀

Àwòrán Oníhòòhò​—Ó Léwu Àbí Kò Léwu?

Àwòrán Oníhòòhò​—Ó Léwu Àbí Kò Léwu?

Àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe kún inú ayé fọ́fọ́ lóde òní. * Wọ́n sábà máa ń wà nínú àwọn fíìmù, orin, ìwé ìròyìn àti ìpolówó ọjà, ó máa ń hàn nínú bí àwọn èèyàn ṣe ń múra. Wọ́n tún máa ń wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, tẹlifíṣọ̀n, géèmù, fóònù, àti àwọn ẹ̀rọ alágbèéká. Àwọn èèyàn tiẹ̀ tún ti ń wò ó báyìí ní àwọn ìkànnì tí àwọn èèyàn ti máa ń fi fọ́tò ránṣẹ́ sí àwọn míì lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kódà, àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ti wá gbòde kan débi pé, ó fẹ́rẹ̀ máà sí ibi tí ọ̀làjú dé tí òun náà ò dé. Ju ti ìgbàkígbà rí lọ, ọ̀pọ̀ èèyàn ní ọ̀pọ̀ ibi láyé ló ń wo oríṣiríṣi àwòrán tó ń mú kí ọkàn fà sí ìṣekúṣe.—Wo àpótí náà,  “Ǹjẹ́ O Mọ̀ Pé . . . ”

Èrò àwọn èèyàn nípa àwòrán oníhòòhò ti tún yàtọ̀ gan-an. Ọ̀jọ̀gbọ́n Gail Dines kọ̀wé pé: “Àwọn àwòrán tó wà lóde báyìí ti burú débi pé ohun táwọn èèyàn kà sí àwòrán oníhòòhò tó burú jáì tẹ́lẹ̀ ti wá di ohun tí wọ́n fi ń najú.”

Kí ni èrò tìẹ nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí? Ṣé ìwọ náà gbà pé àwọn àwòrán oníhòòhò kò léwu? Àbí májèlé olóró lo kà á sí? Àbí kẹ̀, èrò tìẹ ni pé bó ṣe léwu náà ló tún níbi tó dáa sí? Jésù sọ pé: “Gbogbo igi rere a máa mú eso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde.” (Mátíù 7:17) Tá a bá fi àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe wé igi, èso wo ló ń mú jáde? Ká lè rí ìdáhùn, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìbéèrè pàtàkì kan nípa àwòrán oníhòòhò.

Ọṣẹ́ wo ni àwòrán oníhòòhò máa ń ṣe fún ẹni tó bá ń wò ó?

OHUN TÁWỌN Ọ̀MỌ̀RÀN SỌ: Ó máa ń ṣòro gan-an kí ẹni tó bá ń wo àwòrán oníhòòhò tó lè jáwọ́ nínú àṣà yìí, kódà àwọn tó ń ṣèwádìí àti àwọn oníṣègùn kan sọ pé ṣe ló dà bí ẹni tí oògùn olóró ti mọ́ lára.

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brian, * tó ti mọ́ lára láti máa wo àwòrán oníhòòhò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì sọ pé: “Mi ò lè ṣe kí n má wò ó. Á máa ṣe mí bíi pé mo wà lójú ìran. Ṣe ni gbogbo ara mi á máa gbọ̀n, tí orí á sì máa fọ́ mi. Mo sapá kí n lè jáwọ́, àmọ́ kò rọrùn, kódà ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, mo ṣì ń wo àwòrán oníhòòhò nígbà gbogbo.”

Àwọn tó ń wo àwòrán oníhòòhò sábà máa ń bo àṣà yìí mọ́ra. Wọ́n máa ń ṣe é láṣìírí, wọ́n sì máa ń díbọ́n. Abájọ tó fi máa ń ṣe ọ̀pọ̀ lára wọn bíi pé wọ́n dá wà, ojú máa ń tì wọ́n, wọ́n máa ń ṣàníyàn, wọ́n máa ń ní ìdààmú ọkàn, wọ́n sì tètè máa ń bínú. Nígbà míì, wọ́n tiẹ̀ máa ń fẹ́ gbẹ̀mí ara wọn. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Serge sábà máa ń wa àwòrán oníhòòhò sórí fóònù rẹ̀ látorí Íńtánẹ́ẹ̀tì lójoojúmọ́, ohun tó sọ ni pé: “Tara mi nìkan ni mo máa ń rò, ohun tó bá sì ti wù mí ni mo máa ń fẹ́ ṣe ṣáá. Ṣe ló dà bíi pé mi ò já mọ́ nǹkan kan, mi ò ní alábàárò, mo máa ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá, àfi bí ẹni pé mi ò lè bọ́ nínú ẹ̀ mọ́. Ojú ń tì mí, ẹ̀rù sì ń bà mí débi pé mi ò lè sọ ohun tó ń ṣe mí síta kí àwọn míì lè ràn mí lọ́wọ́.”

Kódà, tí ẹnì kan bá wo àwòrán oníhòòhò díẹ̀ tàbí tó ṣèèṣì rí i fìrí, ó ṣì lè ní ipa tí kò dáa lórí rẹ̀. Dókítà kan tó ń jẹ́ Judith Reisman ti ṣe ìwádìí jinlẹ̀ gan-an lórí àwòrán oníhòòhò. Ó sọ níwájú àwọn kan ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin Àgbà ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “Àwòrán oníhòòhò máa ń gbé ìgbékúgbèé sí èèyàn lọ́pọlọ, ó máa ń yí bí ọpọlọ ṣe ń ṣiṣẹ́ pa dà, léraléra ni á máa rántí ohun tó ti rí sẹ́yìn bí onítọ̀hún ò tiẹ̀ ronú nípa rẹ̀ mọ́, kò sì rọrùn láti gbé e kúrò lọ́pọlọ, kódà ó lè máà kúrò níbẹ̀ mọ́ láé.” Ọmọbìnrin ọlọ́dún mọ́kàndínlógún kan tó ń jẹ́ Susan sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lẹ́yìn tó ṣèèṣì já lu àwòrán oníhòòhò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ó ní: “Àwọn àwòrán yẹn ò kúrò lọ́pọlọ mi. Ṣe ni wọ́n máa ń dédé sọ sí mi lọ́kàn. Ó máa ń ṣe mí bíi pé mi ò ní lè gbé wọn kúrò lọ́kàn tán pátápátá.”

ÒÓTỌ́ IBẸ̀ NI PÉ: Àwòrán oníhòòhò máa ń sọ àwọn tó ń wò ó di ẹrú, ó sì máa ń bà wọ́n láyé jẹ́.—2 Pétérù 2:19.

Ọṣẹ́ wo ni àwòrán oníhòòhò máa ń ṣe fáwọn ìdílé?

OHUN TÁWỌN Ọ̀MỌ̀RÀN SỌ: “Àwọn tọkọtaya àti àwọn ìdílé míì máa ń tú ká torí àwòrán oníhòòhò.”—Ìwé The Porn Trap, látọwọ́ Wendy àti Larry Maltz.

Àwòrán oníhòòhò máa ń da àárín tọkọtaya rú, ó sì máa ń tú ìdílé ká torí pé

  • Kì í jẹ́ kí wọ́n lè fọkàn tán ara wọn, wọn ò ní mọwọ́ ara wọn mọ́, ó sì máa ń dín ìfẹ́ tí wọ́n ní sí ara wọn kù.—Òwe 2:12-17.

  • Á mú kí wọ́n máa ro tara wọn nìkan, wọn ò ní máa sọ tọkàn wọn jáde, ọkọ tàbí aya wọn ò sì ní tẹ́ wọn lọ́rùn mọ́.—Éfésù 5:28, 29.

  • Ó máa jẹ́ kí wọ́n máa fọkàn yàwòrán ìṣekúṣe, ọkàn wọn á sì máa fà sí ìbálòpọ̀ lọ́nà òdì.—2 Pétérù 2:14.

  • Ó máa ń jẹ́ kí wọ́n máa fipá mú kí ọkọ tàbí aya wọn lọ́wọ́ nínú àwọn àṣà ìbálópọ̀ kan tí kò bójú mu.—Éfésù 5:3, 4.

  • Ó máa ń mú kí ọkàn wọn bẹ̀rẹ̀ sí í fà sí ẹlòmíì tàbí kí wọ́n tiẹ̀ lọ ṣe ìṣekúṣe.—Mátíù 5:28.

Bíbélì sọ fún àwọn tọkọtaya pé kí wọ́n má ṣe “hùwà ẹ̀tàn” sí ara wọn. (Málákì 2:16, Bíbélì Mímọ́) Ìwà ẹ̀tàn ni kí ẹnì kan hùwà àìṣòótọ́ sí ọkọ tàbí aya rẹ̀, èyí sì lè yọrí sí ìpínyà tàbí ìkọ̀sílẹ̀. Tí irú ìdílé bẹ́ẹ̀ bá sì tú ká, ó máa ṣàkóbá fún àwọn ọmọ wọn.

Àwòrán oníhòòhò tún lè ṣàkóbá fún àwọn ọmọ lọ́nà míì tó burú jáì. Brian, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ọdún mẹ́wàá, à ń ṣe eré bojúbojú nínú ilé lọ́jọ́ kan, ibi tí mo sá pa mọ́ sí ni mo ti ṣàdédé rí ìwé kan. Bàbá mi ló ni ín, àwòrán oníhòòhò ló kúnnú rẹ̀. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ jí i wò, láìmọ ohun tó mú kí n fẹ́ láti máa wo irú àwòrán bẹ́ẹ̀. Bí mo ṣe rawọ́ lé àṣà burúkú tó wá bá mi dàgbà nìyẹn o.” Ìwádìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwòrán oníhòòhò lè jẹ́ kí ojú àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà là sí ìbálòpọ̀ láti kékeré, táá sì wá sọ wọ́n di oníṣekúṣe, wọ́n á máa ní ìbálòpọ̀ lọ́nà ipá. Ìwà wọn ò ní jọ téèyàn gidi, ọpọlọ wọn ò sì ní lè ṣiṣẹ́ bó ṣe yẹ.

ÒÓTỌ́ IBẸ̀ NI PÉ: Àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe máa ń ba àjọṣe tó wà láàárín àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn jẹ́, ó sì lè fa ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ ńláǹlà.—Òwe 6:27.

Kí ni ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe?

Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SỌ PÉ: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín . . . di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.”—Kólósè 3:5.

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé Jèhófà * Ọlọ́run kórìíra àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe. Kì í ṣe pé Jèhófà ka ìbálòpọ̀ sí ohun tó lòdì. Òun ṣáà ló dá wa lọ́nà tí a fi lè ní ìbálòpọ̀, àmọ́ ṣe ló fẹ́ kí àwọn tọkọtaya máa fi gbádùn ara wọn, kí ìfẹ́ tó wà láàárín wọn lè túbọ̀ lágbára sí i àti pé kí wọ́n lè bímọ.—Jákọ́bù 1:17.

Kí wá nìdí tí a fi lè sọ pé Jèhófà kórìíra àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe? Jẹ́ ká fara balẹ̀ ronú lórí àwọn ohun tó tẹ̀ lé e yìí.

  • Jèhófà mọ̀ pé àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe lè bani láyé jẹ́.—Éfésù 4:17-19.

  • Ó nífẹ̀ẹ́ wa, kò sì fẹ́ ká kó sínú ewu.—Aísáyà 48:17, 18.

  • Jèhófà ò fẹ́ káwọn tọkọtaya tú ká, kò sì fẹ́ kí ìdílé dà rú.—Mátíù 19:4-6.

  • Ó fẹ́ kí a jẹ́ oníwà mímọ́, ká sì máa ro ti àwọn míì mọ́ ti ara wa.—1 Tẹsalóníkà 4:3-6.

  • Ó fẹ́ ká mọyì ẹ̀bùn ìbálòpọ̀ tó fún wa, ká sì máa lò ó lọ́nà tí ó tọ́.—Hébérù 13:4.

  • Jèhófà mọ̀ pé irú ojú tí Sátánì fi ń wo ìbálòpọ̀ ni àwòrán oníhòòhò máa ń gbé síni lọ́kàn. Àwòrán oníhòòhò kì í jẹ́ kéèyàn mọ̀ ju tara rẹ̀ nìkan.—Jẹ́nẹ́sísì 6:2; Júúdà 6, 7.

ÒÓTỌ́ IBẸ̀ NI PÉ: Àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe máa ń ba àjọṣe tẹ́nì kan ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́.—Róòmù 1:24.

Àmọ́ Jèhófà máa ń káàánú àwọn tó bá fẹ́ jáwọ́ nínú àṣà burúkú yìí. Bíbélì sọ pé: “Jèhófà jẹ́ aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́. Nítorí tí òun fúnra rẹ̀ mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé ekuru ni wá.” (Sáàmù 103:8, 14) Ó ń pe àwọn onírẹ̀lẹ̀ pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun kí wọ́n lè “rí àánú gbà, kí [wọ́n] sì rí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún ìrànlọ́wọ́ ní àkókò tí ó tọ́.”—Hébérù 4:16; wo àpótí náà,  “Kí Lo Lè Ṣe Tó Ò Fi Ní Máa Wo Àwòrán Oníhòòhò Mọ́?”

Àìmọye èèyàn ló ti gbà kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́. Ǹjẹ́ wọ́n rí ìyàtọ̀? Kíyè sí ohun tí Bíbélì sọ nípa àwọn kan tí wọ́n ti jáwọ́ nínú àṣà burúkú, ó ní: “A ti wẹ̀ yín mọ́, . . . a ti sọ yín di mímọ́, . . . a ti polongo yín ní olódodo ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi àti pẹ̀lú ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” (1 Kọ́ríńtì 6:11) Irú àwọn bẹ́ẹ̀ lè sọ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.

Susan tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan pa dà jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò, ó sọ pé: “Jèhófà nìkan ló lè gba èèyàn sílẹ̀ lọ́wọ́ àṣà burúkú yìí. Tó o bá bẹ̀ ẹ́ pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó sì tọ́ ẹ sọ́nà, wàá rí ojú rere rẹ̀. Kò sì ní já ẹ kulẹ̀.”

^ ìpínrọ̀ 3 Tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe, ó lè jẹ́ àwòrán tàbí ìwé tàbí orin tó dá lórí ìbálòpọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ yìí “àwòrán oníhòòhò” ni a máa lò jù, àmọ́ ó ṣì kan àwọn ohun mìíràn, yálà èyí tí èèyàn ń kà tàbí tó ń gbọ́ tó ń mú kí ó máa wu onítọ̀hún láti ní ìbálòpọ̀.

^ ìpínrọ̀ 8 A ti yí àwọn orúkọ inú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.

^ ìpínrọ̀ 25 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.