Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

 KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | OGUN TÓ DA AYÉ RÚ

Ẹni Tó Wà Lẹ́yìn Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé

Ẹni Tó Wà Lẹ́yìn Ogun àti Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé

Ogun Àgbáyé Kìíní parí ní ọjọ́ kọkànlá oṣù November, ọdún 1918. Lọ́jọ́ náà, ọ̀pọ̀ èèyàn pa iṣẹ́ ajé wọn tì, wọ́n bọ́ sójú pópó, wọn ǹ jó, wọ́n sì ń yọ̀. Ṣùgbọ́n, kò pẹ́ tí ayọ̀ wọn fi di ìbànújẹ́, torí pé ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú míì tún ṣẹlẹ̀ kété lẹ́yìn ogun náà, jàǹbá tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà sì fà ju ọṣẹ́ tí àwọn ìbọn arọ̀jò-ọta ṣe, lọ.

Láti oṣù June 1918 ni àrùn gágá ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọlu àwọn sójà ní ilẹ̀ Faransé. Àrùn yìí ṣe àwọn èèyàn bí ọṣẹ ṣe ń ṣojú. Bí àpẹẹrẹ, láàárín oṣù díẹ̀ péré, iye àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Amẹ́ríkà tí àrùn gágá pa ní ilẹ̀ Faransé pọ̀ ju iye àwọn tó bógun lọ. Nígbà tí ogun parí, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ogun tó pa dà wálé ló ti kó àrùn gágá, bí àìsàn náà ṣe gbèèràn karí ayé nìyẹn.

Ìyẹn nìkan kọ́, lẹ́yìn tí ogun parí, ebi àti ìṣẹ́ wá gbòde kan. Nígbà tí rògbòdìyàn yìí dópin ní ọdún 1918, ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lu ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ilẹ̀ Yúróòpù pa. Kódà, nígbà tó fi máa di ọdún 1923, owó tí wọ́n ń ná ní ilẹ̀ Jámánì kò níye lórí mọ́. Ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà ni ọrọ̀ ajé gbogbo àgbáyé dẹnu kọlẹ̀ pátápátá. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, lọdún 1939, ogun àgbáyé kejì bẹ̀rẹ̀ níbi tí ogun àgbáyé kìíní parí sí. Kí ló fà á tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú yìí fi ń ṣẹlẹ̀ léraléra?

ÀMÌ ÀWỌN ỌJỌ́ ÌKẸYÌN

Àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tó ṣe okùnfà Ogun Àgbáyé Kìíní àti àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé míì tó wáyé. Jésù Kristi sọ tẹ́lẹ̀ pé àkókò kan ń bọ̀ tí ‘orílẹ̀-èdè yóò  dìde sí orílẹ̀-èdè,’ tí àìtó oúnjẹ àti àjàkálẹ̀ àrùn yóò sì kárí ayé. (Mátíù 24:3, 7; Lúùkù 21:10, 11) Ó tilẹ̀ sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé àmì àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ni irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ máa jẹ́. Ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì ṣàlàyé nípa bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ láabi tó ṣẹlẹ̀ láyé ṣe tan mọ́ ogun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run.—Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní  “Ogun Tó Wáyé ní Ọ̀run àti Lórí Ilẹ̀ Ayé.”

Bákan náà, Ìwé Ìṣípayá tún ṣàpèjúwe àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin kan, èyí tí wọ́n tún máa ń pè ní àwọn ẹlẹ́ṣin mẹ́rin inú Àpókálíìsì tàbí ìwé Ìṣípayá. Mẹ́ta lára àwọn ẹlẹ́ṣin yìí ṣàpèjúwe àwọn àjálù kan tí Jésù sọ ṣáájú nípa rẹ̀, ìyẹn ogun, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn. (Wo àpótí tá a pe àkòrí rẹ̀ ní  “Ǹjẹ́ Àwọn Ẹlẹ́ṣin Mẹ́rin Náà Ti Ń Gẹṣin Lọ?”) Ó ṣe kedere pé, ogun àgbáyé kìíní ló tanná ran gbogbo wàhálà tá a ṣì ń bá yí títí dòní. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Sátánì gan-an lẹni tó dá gbogbo wàhálà náà sílẹ̀. (1  Jòhánù 5:19) Ìgbà wo gan-an ni agbára rẹ̀ máa dópin?

Ìwé Ìṣípayá jẹ́ kó dá wa lójú pé, “sáà àkókò kúkúrú” ló ṣẹ́ kù fún Sátánì. (Ìṣípayá 12:12) Ìdí nìyẹn tí inú fi ń bíi gan-an, tó sì ń rúná sí onírúurú àjálù tí kò ṣe é fẹnu sọ lórí ilẹ̀ ayé. Lọ́nà kan náà, àwọn àjálù tí à ń rí lọ́tùn lósì nínú ayé fi hàn pé ìwọ̀nba àkókò díẹ̀ ló kù fun Sátánì.

 JÉSÙ MÁA FỌ́ ÀWỌN IṢẸ́ ÈṢÙ TÚÚTÚÚ

Láti ìgbà tí wọ́n ti ja ogun Àgbáyé Kìíní ni gbogbo nǹkan ti dojú rú fún ọmọ aráyé. Láti ìgbà yẹn ni ogun àjàkú-akátá àti rògbòdìyàn òṣèlú ti ń han àwọn èèyàn léèmọ̀, tó sì jẹ́ pé àwọn èèyàn kò fọkàn tán àwọn olóṣèlú mọ́. Ẹ̀rí tí kò ṣe é já ní koro ni èyí tún jẹ́ pé wọ́n ti lé Sátánì kúrò lọ́run. (Ìṣípayá 12:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè fojú rí alákòóso ayé yìí, ohun tó ṣe kò yàtọ̀ sí ti òǹrorò apàṣẹwàá tó mọ̀ pé omi ti tán lẹ́yìn ẹja òun. Nígbà tí àsìkò Sátánì bá pé, gbogbo wàhálà tó ti dá sílẹ̀ látìgbà Ogun Àgbáyé Kìíní ló máa dópin pátápátá.

Pẹ̀lú òye àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tí o ní yìí, ó yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé Jésù Kristi Ọba wa ọ̀run pé láìpẹ́, ó máa “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.” (1 Jòhánù 3:8) Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn ni wọ́n ti ń gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé. Ǹjẹ́ ìwọ náà máa ń gbàdúrà pé kí ìjọba Ọlọ́run dé? Lábẹ́ Ìjọba yìí, àwọn èèyàn kò ní sí lábẹ́ ìdarí Sátánì mọ́, kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ Ọlọ́run ni àwọn olóòótọ́ èèyàn á máa ṣe lórí ilẹ̀ ayé. (Mátíù 6:9, 10) Nínú Ìjọba Ọlọ́run, àwọn èèyàn kò ní jagun mọ́, yálà ogun àgbáyé tàbí ogun èyíkéyìí! (Sáàmù 46:9) Á dáa kó o kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run yìí, kí ìwọ náà lè wà níbẹ̀ nígbà tí àlááfíà máa gbilẹ̀ kárí ayé!—Aísáyà 9:6, 7.