Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Se Jesu Lo Ye Ka Maa Gbadura Si?

Se Jesu Lo Ye Ka Maa Gbadura Si?

LẸ́NU àìpẹ́ yìí, ẹnì kan ṣe ìwádìí lọ́wọ́ àwọn ọ̀dọ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rin [800] láti onírúurú ẹ̀sìn pé, ṣé Jésù ló yẹ ká máa gbàdúrà sí. Nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] nínú wọn gbà pé Jésù ni. Àmọ́ ọ̀kan nínú wọn wọ́gi lé orúkọ Jésù, ó sì fi “Ọlọ́run” rọ́pò rẹ̀.

Kí ni èrò tìẹ? Ṣé Jésù ló yẹ ká máa gbàdúrà sí ni àbí Ọlọ́run? * Ká lè rí ìdáhùn, ẹ jẹ́ ká wo ẹni tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí.

ẸNI TÍ JÉSÙ KỌ́ WA LÁTI MÁA GBÀDÚRÀ SÍ

Jésù kọ́ wa ní ẹni tó yẹ ká gbàdúrà sí, ó sì tún fi àpẹẹrẹ bí a ṣe lè máa bá a ṣọ̀rọ̀ hàn wá.

ésù fi hàn wá pé Baba wa ọ̀rún nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí

Ẹ̀KỌ́ JÉSÙ: Nígbà tí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ bi í pé, “Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà,” Jésù fèsì pé: “Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, ‘Baba.’” (Lúùkù 11:1, 2) Bákan náà, nínú Ìwàásù tó ṣe Lórí Òkè, Jésù sọ ẹni tó yẹ kí wọ́n máa gbàdúrà sí, ó ní: “Gbàdúrà sí Baba rẹ.” Ó tún wá fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé: “Baba yín mọ àwọn ohun tí ẹ ṣe aláìní kí ẹ tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá.” (Mátíù 6:6, 8) Ní alẹ́ ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn láyé, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá béèrè fún ohunkóhun lọ́wọ́ Baba, yóò fi í fún yín ní orúkọ mi.” (Jòhánù 16:23) Jésù kọ́ wa láti máa gbàdúrà sí Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ àti Bàbá wa.—Jòhánù 20:17.

ÀPẸẸRẸ JÉSÙ: Ẹni tí Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà sí ni òun alára gbàdúrà sí. Nínú àdúrà kan tó gbà, ó sọ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé.” (Lúùkù 10:21) Ó tiẹ̀ níjọ́ kan tí “Jésù gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run, ó sì wí pé: ‘Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé o ti gbọ́ tèmi.’” (John 11:41) Nígbà tí Jésù ń kú lọ, ó gbàdúrà pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” (Lúùkù 23:46) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn wá pé Baba wa ọ̀rún tó jẹ́ “Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé” nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. (Mátíù 11:25; 26:41, 42; 1 Jòhánù 2:6) Ǹjẹ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ìgbàanì tẹ̀ lé ìlànà tí Jésù fún wọ́n?

ẸNI TÍ ÀWỌN KRISTẸNI ÌGBÀANÌ GBÀDÚRÀ SÍ

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀ tí Jésù pa dà sí ọ̀run, àwọn alátakò bẹ̀rẹ̀ sí í halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Ìṣe 4:18) Ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà bá bẹ̀rẹ̀ àdúrà, ta lẹ rò pé wọ́n gbàdúrà sí? Bíbélì sọ pé: “Wọ́n gbé ohùn wọn sókè sí Ọlọ́run pẹ̀lú ìfìmọ̀ṣọ̀kan,” wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé kó ran àwọn lọ́wọ́ “nípasẹ̀ orúkọ Jésù ìránṣẹ́ [rẹ̀] mímọ́.” (Ìṣe 4:24, 30) Èyí fi hàn pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tẹ̀ lé ìlànà tó fún wọn nípa àdúrà. Ọlọ́run ni wọ́n gbàdúrà sí, kì í ṣe Jésù.

Ní ọdún díẹ̀ lẹ́yìn náà, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ bí òun àtàwọn ẹlẹgbẹ́ òun ṣe máa ń gbàdúrà. Nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni bíi tiẹ̀, ó ní: “Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jésù Kristi nígbà gbogbo tí a bá ń gbàdúrà fún yín.” (Kólósè 1:3) Pọ́ọ̀lù tún sọ fún àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “ní orúkọ Olúwa wa Jésù Kristi kí ẹ máa fi ọpẹ́ fún Baba àti Ọlọ́run wa nígbà gbogbo nítorí ohun gbogbo.” (Éfésù 5:20) Àwọn ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Pọ́ọ̀lù fún àwọn èèyàn níṣìírí pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí Ọlọ́run, ní orúkọ Jésù.—Kólósè 3:17.

Bíi tàwọn Kristẹni ìgbàanì, àwa náà lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jésù tí a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó fún wa nípa àdúrà. (Jòhánù 14:15) Bí a bá ń gbàdúrà sí Bàbá wa ọ̀run nìkan, nígbà náà ni ọ̀rọ̀ inú ìwé Sáàmù 116:1, 2 máa túbọ̀ nítumọ̀ sí wa, èyí tó sọ pé, èmi nífẹ̀ẹ́ Jèhófà nítorí pé ó ń gbọ́ ohùn mi, èmi yóò sì máa pè é jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ mi. *

^ ìpínrọ̀ 3 Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jésù àti Ọlọ́run ò dọ́gba. Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 4 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ ìpínrọ̀ 11 Kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa, a gbọ́dọ̀ máa sapá láti máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i, wo orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?