Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ | ṢÉ ÀWỌN TÓ TI KÚ LÈ JÍǸDE?

Bó Ṣe Lè Dá Ẹ Lójú Pé—Àjíǹde Àwọn Òkú Máa Wà?

Bó Ṣe Lè Dá Ẹ Lójú Pé—Àjíǹde Àwọn Òkú Máa Wà?

Ṣé àsọdùn ni kéèyàn sọ pé àwọn òkú máa jíǹde? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kò gbà pé àsọdùn ni ọ̀rọ̀ yẹn. Ọlọ́run mí sí i láti sọ pé: “Bí ó bá jẹ́ pé nínú ìgbésí ayé yìí nìkan ni a ti ní ìrètí nínú Kristi, àwa ni ó yẹ láti káàánú jù lọ nínú gbogbo ènìyàn. Àmọ́ ṣá o, nísinsìnyí a ti gbé Kristi dìde kúrò nínú òkú, àkọ́so nínú àwọn tí ó ti sùn nínú ikú.” (1 Kọ́ríńtì 15:19, 20) Jésù fúnra rẹ̀ jíǹde, èyí sì mù kó dá Pọ́ọ̀lù lójú pé àjíǹde àwọn òkú máa wáyé. * (Ìṣe 17:31) Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi pe Jésù ní “àkọ́so”—nítorí pé òun lẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ìyè ayérayé. Tí Jésù bá jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ tó jíǹde sí ọ̀run, á jẹ́ pé àwọn míì ṣì wà tó máa jíǹde.

Jóòbù sọ fún Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.”Jóòbù 14:14,15

Ẹ̀rí míì tún wà tá á mú kó dáwa lójú pé àwọn òkú máa jíǹde. Ìyẹn ni pé Ọlọ́run òtítọ́ ni Jèhófà. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run . . . kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Jèhófà kò purọ́ ri, kò sì le purọ́ láé. Ó tiẹ̀ tún fi hàn wá pé òun lágbára láti jí àwọn òkú dìde. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ṣé Ọlọ́run máa wá ṣe ìlérí pé òun máa jí àwọn òkú dìde, kó má sì mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ? Ó dájú pé kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!

Kí nìdí tí Jèhófà fi pinnu láti jí àwọn òkú dìde? Ó jẹ́ nítorí ìfẹ́ tó ní fún wa. Jóòbù béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Jóòbù fúnra rẹ̀ wá dáhùn pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn. Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:14, 15) Ó dá Jóòbù lójú pé ó wu Bàbá wa ọ̀run láti jí òun dìde. Ṣé Ọlọ́run ti wá yí pa dà ni? Ọlọ́run sọ pé: “Èmi ni Jèhófà; èmi kò yí padà.” (Málákì 3:6) Ọlọ́run fẹ́ kí àwọn òkú jíǹde, kí wọ́n ní ìlera tó dáa, kí wọ́n sì láyọ̀. Bó ṣe máa wu òbí tó pàdánù ọmọ rẹ̀ láti rí ọmọ náà pa dà, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ń wu Ọlọ́run láti jí àwọn tó ti kú dìde. Ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé Ọlọ́run ní agbára láti ṣe ohunkóhun tó bá fẹ́.Sáàmù 135:6.

Ikú ń hàn wá léèmọ̀, àmọ́ Ọlọ́run máa tó mú un kúrò

Jèhófà máa fún Jésù lágbára láti mú ayọ̀ wá fún gbogbo àwọn tó ti pàdánù èèyàn wọn. Báwo ni ọ̀rọ̀ àjíǹde ṣe rí lára Jésù? Ṣáájú kó tó jí Lásárù dìde, ó rí ìbànújẹ́ tó bá àwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ Lásárù, èyí sì mú kó sunkún. (Jòhánù 11:35) Nígbà kan, Jésù pàdé opó Náínì tó pàdánù ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí. “Àánú rẹ̀ ṣe [Jésù], ó sì wí fún un pé: ‘Dẹ́kun sísunkún.’” Lẹ́yìn náà, ó jí ọmọ rẹ̀ dìde. (Lúùkù 7:13) Èyí fi hàn pé ó máa ń dun Jésù láti rí ìbànújẹ́ tí ikú ń fà. Ẹ ò rí i pé inú rẹ̀ máa dùn púpọ̀ nígbà tó bá sọ ìbànújẹ́ ọ̀pọ̀ èèyàn di ayọ̀!

Ǹjẹ́ o ti pàdánù èèyàn rẹ kan rí? Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o kò ní rí ẹni náà mọ́. Ṣùgbọ́n jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa lo Ọmọ rẹ̀ láti jí àwọn òkú dìde. Ó fẹ́ kó o àwọn èèyàn rẹ tó ti kú, kó o sì wà níbẹ̀ láti kí wọn nígbà tí wọ́n bá jíǹde. Fojú inú wo bí ìgbà yẹn ṣe máa dùn tó fún ìwọ àtàwọn èèyàn rẹ láìbẹ̀rù pé ikú lè mú ẹnikẹ́ni lọ!

Lionel, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àpilẹ̀kọ tó ṣáájú sọ pé: “Nígbà tó yá, mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa àjíǹde. Mi ò kọ́kọ́ gbà gbọ́ pé àjíǹde máa wà, mo tiẹ̀ rò pé ẹni tó ń kọ́ mi fẹ́ ṣì mí lọ́nà ni. Àmọ́, ìgbà tí mo rí i nínú Bíbélì ni mo tó gbà pé òótọ́ ni. Ní báyìí, mò ń fojú sọ́nà láti rí bàbá ìyá mi lẹ́ẹ̀kan sí i.”

Ṣé wàá fẹ́ mọ̀ sí i? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti fi hàn ẹ́ nínú Bíbélì rẹ ìdí tá a fi gbà pé àjíǹde máa wà lọ́jọ́ iwájú. *

^ ìpínrọ̀ 3 Fún àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù jíǹde, wo Ilé Ìṣọ́ March 1, 2013, ojú ìwé 3-6. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.