Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye

Ewu Tó Wà Nínú Kéèyàn Ṣi Bíbélì Lóye

Ọmọdébìnrin kan rí èéfín tí ó ń rú yọ látinú ilé iṣẹ́ kan, èéfín náà sì wá dà bíi kùrukùru lójú ọ̀run. Ọmọdébìnrin náà wá ronú pé ilé iṣẹ́ yẹn ni wọ́n ti ń ṣe kùrukùru tó máa ń wà lójú sánmà. Bí ọmọ yìí kò ṣe lóye ohun tí wọ́n ń ṣe nílé iṣẹ́ yẹn kò jọni lójú. Àmọ́, àwọn àṣìlóye kan wà tó lè ṣe ìpalára fún wa. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ṣi ìtọ́ni tó wà lára páálí oògùn lóye, ó lè fa ìpalára tó lékenkà.

Tó bá wá jẹ́ àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run là ṣì lóye, ìpalára tó burú jáì ló máa yọrí sí. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan ṣi ẹ̀kọ́ Jésù lóye. (Jòhánù 6:48-68) Dípò tí wọ́n á fi kẹ́kọ̀ọ́ sí i lọ́dọ̀ Jésù, ńṣe ni wọ́n kọ gbogbo ohun tí Jésù kọ́ wọn. Ẹ ò rí i pé wọ́n pàdánù gan-an!

Ǹjẹ́ o máa ń ka Bíbélì kó lè tọ́ ẹ sọ́nà? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a gbóríyìn fún ẹ. Àmọ́, ṣé ó ṣeé ṣe kó o ṣi àwọn nǹkan kan lóye nínú ohun tó o kà? Ó máa ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn kan. Wo mẹ́ta lára àwọn nǹkan táwọn èèyàn sábà máa ń ṣì lóye.

  • Àwọn kan máa ń ṣi àṣẹ inú Bíbélì tó sọ pé “bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́” lóye. Wọ́n gbà pé ńṣe ni ẹsẹ yẹn ń sọ pé ká máa gbọ̀n jìnnìjìnnì níwájú Ọlọ́run. (Oníwàásù 12:13) Àmọ́ Ọlọ́run kò fẹ́ kí àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ máa gbọ̀n jìnnìjìnnì fún un. Ó sọ pé: “Má fòyà, nítorí mo wà pẹ̀lú rẹ. Má wò yí ká, nítorí èmi ni Ọlọ́run rẹ. Dájúdájú, èmi yóò fi okun fún ọ. Èmi yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ ní ti tòótọ́.” (Aísáyà 41:10) Ohun tó túmọ̀ sí láti bẹ̀rù Ọlọ́run ni pé ká ní ọ̀wọ̀ tó jinlẹ̀ fún un.

  • Ṣé Ọlọ́run máa dáná sun ayé yìí?

    Àwọn kan máa ń ṣi ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí lóye: “Ohun gbogbo ni ìgbà tí a yàn kalẹ̀ wà fún, . . . ìgbà bíbímọ àti ìgbà kíkú.” Wọ́n gbà pé Ọlọ́run ti pinnu ìgbà tí ẹnì kọ̀ọ̀kan máa kú. (Oníwàásù 3:1, 2) Ṣùgbọ́n, ohun tí ẹsẹ Bíbélì yẹn kàn ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni ìwàláàyè àwa èèyàn àti pé kò sẹ́ni tíkú ò lè pa. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ wa pé àwọn ìpinnu tá a bá ṣe lè nípa lórí bí ẹ̀mí wa ṣe máa gùn sí. Bí àpẹẹrẹ, a kà nínú Bíbélì pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà yóò fi kún àwọn ọjọ́.” (Òwe 10:27; Sáàmù 90:10; Aísáyà 55:3) Lọ́nà wo? Tá a bá bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ó máa sún wa láti yẹra fún àwọn àṣà tó lè pa wá lára bí ọtí àmupara àti ìṣekúṣe.1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.

  • Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀run àti ilẹ̀ ayé ni a “tò jọ pa mọ́ fún iná.” Àwọn kan ronú pé ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run máa pa ayé yìí run. (2 Pétérù 3:7) Ṣùgbọ́n Ọlọ́run ṣèlérí pé òun kò ní jẹ́ kí àgbáálá ayé wa yìí pa run láé. Ọlọ́run ti “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀; a kì yóò mú kí ó ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5; Aísáyà 45:18) Ipò ayé tó ti bàjẹ́ yìí ni kò ní sí mọ́, àfi bí ìgbá tí iná bá jó nǹkan run, kì í ṣe ayé tí à ń gbénú rẹ̀ lódindi. Àmọ́ ọ̀run ńkọ́? Nígbà míì ọ̀run lè tọ́ka sí ojú sánmà tàbí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì lè tọ́ka sí ibi tí Ọlọ́run ń gbé. Kò sì sí èyíkéyìí lára àwọn nǹkan yìí tó máa pa run.

KÍ NÌDÍ TÍ WỌ́N FI MÁA Ń ṢI BÍBÉLÌ LÓYE NÍGBÀ MÍÌ?

Bí àwọn àpẹẹrẹ yẹn ṣe fi hàn, àwọn èèyàn sábà máa ń ṣi ohun tí wọ́n kà nínú Bíbélì lóye. Àmọ́ kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà kírú nǹkan bẹ́ẹ̀ máa ṣẹlẹ̀? Àwọn kan lè ronú pé: ‘Tó bá jẹ́ pé ọlọ́gbọ́n ni Ọlọ́run lóòótọ́, tó sì mọ gbogbo nǹkan, ó yẹ kó fún wa ní ìwé tí wọ́n kọ lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì máa rọrùn fún gbogbo èèyàn láti lóye rẹ̀. Kì nìdí tí kò fi ṣe bẹ́ẹ̀?’ Wo ìdí mẹ́ta táwọn èèyàn fi sábà máa ń ṣi Bíbélì lóye.

  1. Onírẹ̀lẹ̀ àti ẹni tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ ló máa ń lóye Bíbélì. Jésù sọ fún Bàbá rẹ̀ pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti rọra fi ohun wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Lúùkù 10:21) Ńṣe ni wọ́n ṣe Bíbélì lọ́nà tó fi jẹ́ pé àwọn tó bá ní ọkàn tó dáa nìkan ló máa lè lóye rẹ̀. Àwọn tó bá gbà pé àwọn mọ̀ tán, tí wọ́n ń ṣe bí “ọlọ́gbọ́n àti amòye” ló máa ń ṣòro fún láti lóye Bíbélì. Ṣùgbọ́n àwọn tó bá ń ka Bíbélì pẹ̀lú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, tí wọ́n sì ń háragàgà láti ní ìmọ̀ sí i bíi ti “ìkókó” ló máa ń lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. Bí Ọlọ́run ṣe ṣe Bíbélì fi hàn pé ó mọ ohun tó ń sẹ!

  2. Bíbélì rọrùn láti lóye fún ẹni tó bá béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run. Jésù fi hàn pé àwọn èèyàn máa nílò ìrànlọ́wọ́, kí wọ́n tó lè lóye ẹ̀kọ́ òun dáadáa. Ibo ni ìrànlọ́wọ́ náà ti máa wá? Jésù ṣàlàyé pé: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo.” (Jòhánù 14:26) Torí náà, Ọlọ́run ló máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ tí a bá béèrè, kí a lè lóye Bíbélì. Àmọ́ Ọlọ́run kì í fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ fún àwọn tí kò bá gbẹ́kẹ̀ lé e fún ìrànlọ́wọ́, torí náà Bíbélì kì í yé wọn. Ẹ̀mí mímọ́ ló ń darí àwọn Kristẹni tó mọ Bíbélì lọ sọ́dọ̀ àwọn tó ń wá ọ̀nà láti túbọ̀ lóye Bíbélì.Ìṣe 8:26-35.

  3. Ó di àkókó kan pàtó ká tó lè lóye àwọn apá kan nínú Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, áńgẹ́lì kan sọ fún wòlíì Dáníẹ́lì pé kó kọ àwọn ọ̀rọ̀ kan tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú sílẹ̀. Áńgẹ́lì náà sọ fún un pé: “Dáníẹ́lì, ṣe àwọn ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, kí o sì fi èdìdì di ìwé náà, títí di àkókò òpin.” Láti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn lọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ka ìwé Dáníẹ́lì nínú Bíbélì, àmọ́ wọn ò mọ ohun tó túmọ̀ sí. Kódà, Dáníẹ́lì fúnra rẹ̀ kò lóye ọ̀pọ̀ lára ohun tó kọ. Ó sọ pé: “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n èmi kò lóye.” Nígbà tó bá yá, àwọn èèyàn máa lóye àsọtẹ́lẹ̀ Ọlọ́run tí wòlíì Dáníẹ́lì kọ sílẹ̀, àmọ́ ó máa jẹ́ ní àkókò tí Ọlọ́run fẹ́. Áńgẹ́lì náà wá ṣàlàyé pé: “Máa lọ, Dáníẹ́lì, nítorí pé a ṣe ọ̀rọ̀ náà ní àṣírí, a sì fi èdìdì dì í títí di àkókò òpin.” Àwọn wo ló máa lóye ọ̀rọ̀ Ọlọ́run? “Àwọn ẹni burúkú kankan kì yóò sì lóye; ṣùgbọ́n àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.” (Dáníẹ́lì 12:4, 8-10) Torí náà, Ọlọ́run kò ní jẹ́ ká mọ ìtúmọ̀ àwọn ẹsẹ Bíbélì kan àfi tó bá tó àkókò tó fẹ́ ká mọ̀ ọ́n.

Ṣé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣi Bíbélì lóye rí nítorí pé kò tíì tó àkókò láti mọ ìtúmọ̀ rẹ̀? Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n nígbà tí àkókò tó lójú Ọlọ́run, ó mú kí ọ̀rọ̀ náà ṣe kedere, wọ́n sì ṣe ìyípadà tó yẹ. Wọ́n gbà pé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì Kristi làwọn ń tẹ̀lé. Àwọn àpọ́sítélì máa ń tún èrò wọn ṣe nígbàkigbà tí Jésù bá tọ́ wọn sọ́nà.Ìṣe 1:6, 7.

Èrò tí ọmọdébìnrin kan ní nípa ibi tí kùrukùru ti wá lè jẹ́ àṣìlóye tí kò fi bẹ́ẹ̀ tó nǹkan. Àmọ́, ohun pàtàkì ni ẹ̀kọ́ tí Bíbélì kọ́ni jẹ́ fún ẹ. Àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe pàtàkì gan-an débí pé ó kọjá ohun téèyàn kàn lè sọ pé òun fẹ́ dá lóye nípa dídá ka Bíbélì láyè ara rẹ̀. Torí náà, jẹ́ kí ẹni tó mọ Bíbélì dáadáa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè lóye ohun tí ò ń kà. Ìyẹn àwọn onírẹ̀lẹ̀, tí wọ́n gbára lé ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run láti lóye Bíbélì, tí wọ́n sì gbà pé àkókò tí Ọlọ́run fẹ́ ká lóye Bíbélì ju ti ìgbàkígbà rí lọ là ń gbé yìí. Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ̀rọ̀ tàbí kó o lọ sí ìkànnì wa, ìyẹn jw.org/yo láti ka àwọn ìwádìí tá a fara balẹ̀ ṣe. Bíbélì ṣèlérí pé: “Bí o bá ké pe òye . . . , ìwọ yóò sì rí ìmọ̀ Ọlọ́run gan-an.”Òwe 2:3-5.