À Ń Wàásù A sì Ń Kọ́ni Kárí Ayé
KÁRÍ AYÉ
-
ILẸ̀ 240
-
IYE AKÉDE 8,220,105
-
ÀRÒPỌ̀ WÁKÀTÍ TÁ A FI WÀÁSÙ 1,933,473,727
-
IYE ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ 9,708,968
NÍ APÁ YÌÍ
Áfíríkà
Àwọn ọ̀nà tó mọ́gbọ́n dání wo làwọn Ẹlẹ́rìí ń lò láti wàásù ìhìn rere?
Àwọn Ilẹ̀ Amẹ́ríkà
Kí nìdí tí ọmọbìnrin kan fi ń lo iná àbẹ́là láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú igbó? Kí nìdí tí baálẹ̀ kan tí kò gba gbẹ̀rẹ́ fi ń retí àtirí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Kí ló fà á tí ẹnì kan tó ti máa ń ṣenúnibíni sí wa fi bú sẹ́kún?
Éṣíà àti Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn Ayé
Kò sóhun náà tó lè di àwọn ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run, yálà ààbọ̀ ara ni o tàbí wọ́n fàṣẹ ọba mú wọn.
Yúróòpù
Ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹ̀yà Roma, ẹlẹ́wọ̀n kan àti obìnrin kan tó fẹ́ pa ara rẹ̀ láyọ̀ gan-an nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Àgbègbè Oceania
À ń lo àwọn tábìlì àti kẹ̀kẹ́ tá a fi ń pàtẹ àwọn ìwé wa, Ìkànnì jw.org àtàwọn fídíò ètò Ọlọ́run láti kọ́ ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́!