Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ àti Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Yìí

Lára àwọn ọ̀rọ̀ Jésù táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ ni èyí tó sọ lórí òkè kan nítòsí ìlú Kápánáúmù, tó wà létí Òkun Gálílì. Ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ọ̀rọ̀ náà sí Ìwàásù Orí Òkè, ó sì wà ní orí 5 sí 7 nínú ìwé Mátíù tó wà nínú Bíbélì. Ìwé yìí á jẹ́ kó o mọ àwọn ọ̀rọ̀ yẹn, kí ìwọ náà lè jàǹfààní látinú ọgbọ́n Jésù.

  • ORÍ 5

    • Jésù bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ni lórí òkè (1, 2)

    • Ohun mẹ́sàn-án tó ń múni láyọ̀ (3-12)

    • Iyọ̀ àti ìmọ́lẹ̀ (13-16)

    • Jésù máa mú Òfin ṣẹ (17-20)

    • Ìmọ̀ràn lórí ìbínú (21-26), àgbèrè (27-30), ìkọ̀sílẹ̀ (31, 32), ìbúra (33-37), ẹ̀san (38-42), nínífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá (43-48)

  • ORÍ 6

    • Má ṣe òdodo àṣehàn (1-4)

    • Bí o ṣe lè gbàdúrà (5-15)

      • Àdúrà àwòkọ́ṣe (9-13)

    • Ààwẹ̀ (16-18)

    • Ìṣúra ní ayé àti ọ̀run (19-24)

    • Ẹ má ṣàníyàn mọ́ (25-34)

      • Ẹ máa wá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́ (33)

  • ORÍ 7

    • Ẹ yéé dáni lẹ́jọ́ (1-6)

    • Ẹ máa béèrè, ẹ máa wá kiri, ẹ máa kan ilẹ̀kùn (7-11)

    • Òfin Oníwúrà (12)

    • Ẹnubodè tóóró (13, 14)

    • Àwọn èso wọn la máa fi mọ̀ wọ́n (15-23)

    • Ilé orí àpáta, ilé orí iyanrìn (24-27)

    • Bí Jésù ṣe ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ya àwọn èrò lẹ́nu (28, 29)