Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

AspctStyle/stock.adobe.com

ÌRÁNTÍ IKÚ JÉSÙ

Jésù Máa Fòpin sí Ogun

Jésù Máa Fòpin sí Ogun

 Jésù fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn gan-an nígbà tó wà láyé. Kódà, ó nífẹ̀ẹ́ wa débi pé ó fi ẹ̀mí ẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Mátíù 20:28; Jòhánù 15:13) Láìpẹ́, Jésù tún máa fi ìfẹ́ tó ní sí wa hàn ní ti pé ó máa lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run láti “fòpin sí ogun kárí ayé.”​—Sáàmù 46:9.

 Ẹ gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ pé Jésù máa ṣe:

  •   “Yóò gba àwọn aláìní tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ sílẹ̀, yóò sì gba tálákà àti ẹni tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Yóò ṣàánú aláìní àti tálákà, yóò sì gba ẹ̀mí àwọn tálákà là. Yóò gbà wọ́n lọ́wọ́ ìnira àti ìwà ipá.”​—Sáàmù 72:12-14.

 Báwo la ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ohun tí Jésù ti ṣe fún wa àtohun tó ṣì máa ṣe fún wa? Ní Lúùkù 22:19, Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ pé kí wọ́n máa rántí ikú òun. Lọ́dọọdún, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń pàdé pọ̀ láti rántí ikú ẹ̀ ní àyájọ́ ọjọ́ tó kú. Torí náà, a fẹ́ kó o dára pọ̀ mọ́ wa láti rántí ikú Jésù lọ́jọ́ Sunday, March 24, 2024.

Wá Ibi Tá A Ti Máa Ṣe Ìrántí Ikú Jésù