Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Marek M. Berezowski/Anadolu Agency via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Ó Ti Lé Lọ́dún Kan Tí Ogun Ti Ń Jà ní Ukraine​—Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ọlọ́run Máa Ṣe?

Ó Ti Lé Lọ́dún Kan Tí Ogun Ti Ń Jà ní Ukraine​—Kí Ni Bíbélì Sọ Pé Ọlọ́run Máa Ṣe?

 Friday, February 24, 2023, ló máa pé ọdún kan tí ogun tó ń jà ní Ukraine ti bẹ̀rẹ̀. Báwọn ìròyìn kan ṣe sọ, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300,000) àwọn ọmọ ogun Ukraine àti Rọ́ṣíà ló ti kú tàbí fara pa nínú ogun yìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n (30,000) àwọn ará ìlú ló sì ti kú. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí iye náà jùyẹn lọ.

 Ó bani nínú jẹ́ pé kò sí ẹ̀rí tó fi hàn pé ogun náà máa dáwọ́ dúró láìpẹ́.

  •   “Ní báyìí tó ti lé lọ́dún kan táwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà ti gbógun wọ Ukraine, kò tíì sí ẹ̀rí pé rògbòdìyàn náà máa tó dáwọ́ dúró. Kódà, a ò lè sọ èyí tó lè borí lára àwọn orílẹ̀-èdè méjèèjì tó ń bára wọn ja ogun náà, kò sì dájú pé wọ́n jọ máa wá àlááfíà láàárín ara wọn.”​—NPR (National Public Radio), February 19, 2023.

 Ogun yìí àtàwọn ogun míì tó ń jà káàkiri ti fa ìnira fáwọn èèyàn tí ò mọwọ́ mẹsẹ̀ kárí ayé, ìyẹn ò sì múnú ọ̀pọ̀ èèyàn dùn. Kí ni Bíbélì sọ pé Ọlọ́run máa ṣe? Ṣé ìgbà kan ń bọ̀ tí ogun ò ní sí mọ́?

Ogun tó máa fòpin sí gbogbo ogun

 Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ogun kan. Ogun yìí máa gba aráyé sílẹ̀ dípò kó pa wọ́n run. Ogun yìí ni ogun Amágẹ́dọ́nì, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìfihàn 16:14, 16) Ọlọ́run máa lo ogun yìí láti fòpin sí ìjọba èèyàn tó ti fa ọ̀pọ̀ ogun runlé-rùnnà. Tó o bá fẹ́ mọ bí ogun Amágẹ́dọ́nì ṣe máa mú àlááfíà wá, ka àwọn àpilẹ̀kọ yìí: