Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

À Ń Ran Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́wọ́ Láti Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

À Ń Ran Àwọn Èèyàn Kárí Ayé Lọ́wọ́ Láti Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

 Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Agostinho tó sì ń gbé lórílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Oko kan tó wà lórílẹ̀-èdè wa ni mo dàgbà sí. Tálákà paraku ni wá. Ṣe ni mo ní láti fi ilé ìwé sílẹ̀ torí àtiṣiṣẹ́ kí n lè gbọ́ bùkátà ìdílé wa.” Ìgbà tí Agostinho pé ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33) ló tó mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ó sọ pé: “Bí mo ṣe mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà ló mú kí n di ẹni iyì àti ẹni àpọ́nlé.”

 Ọ̀kan péré ni Agostinho jẹ́ lára ọgọ́rùn-ún méjì ààbọ̀ (250) mílíọ̀nù èèyàn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti kọ́ bá a ṣe ń kọ̀wé àti bá a ṣe ń kà á láti ohun tó lé ní àádọ́rin (70) ọdún sẹ́yìn. Kí nìdí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń kọ́ àwọn èèyàn láti mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà? Àǹfààní wo làwọn èèyàn ti rí látinú irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀?

Àìmọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà Ń Mú Kó Ṣòro Láti Kẹ́kọ̀ọ́

 Ní nǹkan bí ọdún 1935, ilẹ̀ márùndínlọ́gọ́fà (115) ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù. Kí àwọn míṣọ́nnárì lè wàásù fún àwọn tó ń sọ onírúurú èdè, wọ́n máa ń lo kásẹ́ẹ̀tì tá a ti gbohùn àsọyé Bíbélì tá a túmọ̀ sínú rẹ̀. Wọ́n á wá gbé kásẹ́ẹ̀tì náà sí i, ìgbà míì sì wà tí wọ́n á fún àwọn èèyàn ní ìwé tá a túmọ̀ sí èdè wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn fẹ́ mọ ohun tí Bíbélì sọ, àìmọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà mú kó ṣòro fún ọ̀pọ̀ lára wọn láti kẹ́kọ̀ọ́.

 Táwọn èèyàn ò bá lè dá ka Bíbélì fúnra wọn, ó máa ń ṣòro fún wọn láti fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò. (Jóṣúà 1:8; Sáàmù 1:​2, 3) Ó tún máa ń nira fún wọn láti ṣe ojúṣe wọn nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, tí àwọn òbí ò bá mọ ìwé kà, ó máa ń gba pé kí wọ́n sapá gan-an kí wọ́n tó lè tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà. (Diutarónómì 6:​6, 7) Tí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di Ẹlẹ́rìí ò bá sì mọ̀wéé kà, wọn ò ní lè lo Bíbélì tí wọ́n bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

A Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Kọ́ Àwọn Èèyàn Láti Mọ̀ọ́kọ Mọ̀ọ́kà

 Láàárín ọdún 1940 sí ọdún 1959, méjì lára àwọn tó ń múpò iwájú láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ sí onírúurú ilẹ̀ kí wọ́n lè ṣètò iṣẹ́ ìwàásù níbẹ̀. Àwọn méjì náà ni Nathan H. Knorr àti Milton G. Henschel. Láwọn ilẹ̀ táwọn èèyàn ò ti fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, wọ́n gba àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì níyànjú láti dá àwọn kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà sílẹ̀ ní àwọn ìjọ ibẹ̀.

Àwọn ará kan rèé tí wọ́n mú ìwé téèyàn lè fi kọ́ ìwé kíkà dání ní àpéjọ kan tó wáyé ní Chingola lọ́dún 1954, lórílẹ̀-èdè Sáńbíà.

 Àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì fi àwọn ìtọ́ni ránṣẹ́ sáwọn ìjọ lórí bí wọ́n ṣe máa darí kíláàsì náà. Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìjọba ìbílẹ̀ ti ní àwọn ètò kan nílẹ̀ tí wọ́n lè lò. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Brazil, ẹ̀ka ọ́fíìsì rí àwọn ohun èèlò àtàwọn ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ni gbà lọ́dọ̀ ìjọba, wọ́n sì kó wọn ránṣẹ́ sí àwọn ìjọ. Ní àwọn ilẹ̀ míì, àwọn Ẹlẹ́rìí fúnra wọn ló ṣètò kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà tiwọn.

 Tọkùnrin tobìnrin, tọmọdé tàgbà ló lè lọ sí kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ohun tí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ náà wà fún ni pé kí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lè mọ èdè àbínibí wọn kà, bó bá tiẹ̀ túmọ̀ sí pé kí ìjọ kan máa kọ́ni ní èdè tó ju ẹyọ kan lọ.

Ìdálẹ́kọ̀ọ́ Náà Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́ Gan-an

 Àǹfààní wo làwọn èèyàn ti rí nínú ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà yìí? Ẹlẹ́rìí kan láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Mo ti wá lóye ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì báyìí, èyí sì ń jẹ́ kó wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Bí mo ṣe mọ̀wéé kà ti mú kí n lè bá àwọn aládùúgbò mi sọ̀rọ̀ fàlàlà, mo sì ti wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún àwọn èèyàn púpọ̀ sí i.”

 Àǹfààní ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà kọjá pé ká kàn ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì. Isaac tó wá láti orílẹ̀-èdè Bùrúńdì sọ pé: “Bí mo ṣe mọ̀ọ́kọ tí mo sì mọ̀ọ́kà ti jẹ́ kí n ní òye iṣẹ́ ìkọ́lé. Iṣẹ́ ìkọ́lé ni mò ń ṣe jẹun báyìí, mo sì ń bójú tó àwọn iṣẹ́ ìkọ́lé ńláńlá.”

Wọ́n ń kọ́ èdè Chichewa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan ní ìlú Lilongwe, lórílẹ̀-èdè Màláwì lọ́dún 2014

 Ẹni ọdún mọ́kàndínláàádọ́ta (49) ni Jesusa tó wá láti orílẹ̀-èdè Peru nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Ó sọ pé: “Ìyàwó ilé ni mí, mo sì gbọ́dọ̀ rí iye owó àti orúkọ ọjà tí mo fẹ́ rà lọ́jà. Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, kì í rọrùn fún mi rárá. Ọpẹ́lọpẹ́ kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà tó ti wá fi mí lọ́kàn balẹ̀ báyìí tí mo bá lọ ra ohun tí ìdílé mi nílò.”

 Fún ọ̀pọ̀ ọdún, àwọn aláṣẹ ní onírúurú orílẹ̀-èdè ti gbóríyìn fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí iṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe láti mú káwọn èèyàn mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà. Títí di báyìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ń darí kíláàsì mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, wọ́n ń lo ọgbọ́n ìkọ́ni àtàwọn ìwé ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ti tún ṣe láti àwọn ọdún yìí wá. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n ti kọ àwọn ìwé tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó igba ó lé mẹ́rìnlélógún (224) mílíọ̀nù, wọ́n sì ti tẹ̀ ẹ́ jáde ní ọgọ́rùn-ún méje ó lé ogún (720) èdè láti ran àwọn tí kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé lọ́wọ́ àtàwọn tí kò mọ̀wéé kà. a

a Bí àpẹẹrẹ, ìwé pẹlẹbẹ Apply Yourself to Reading and Writing wà ní èdè mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123), ìwé Tẹ́tí sí Ọlọ́run sì wà ní ọgọ́rùn-ún mẹ́fà ó lé mẹ́wàá (610) èdè.