Jèhófà Wà Pẹ̀lú Mi
Wà á jáde:
1. Mo wọ̀tún mo wòsì,
Kò sálábàárò kan,
Ó jọ pé kò sírètí,
Ìdààmú ti wá gbọkàn mi.
Wọ́n ṣàìdáa sí mi,
Kò s’olùrànlọ́wọ́,
Ta ló máa tù mí nínú?
Ta ló máa bá mi gbẹ́rù mi?
(ÈGBÈ)
Ọpẹ́lọpẹ́
Ọlọ́run mi
Tó gbóhùn mi
Tó ṣàánú mi,
Kò sóhun tí
Baba kò rí.
Ó ń gbọ́ tèmi;
Kò fi mí lẹ̀.
Bí ‘ṣòro tilẹ̀ pọ̀,
Jáà wà pẹ̀lú mi.
2. Bí mo tilẹ̀ ń jìyà
Torí mo jẹ́ tìrẹ,
Báwọn èèyàn pa mí tì,
Ìwọ kò ní fi mí sílẹ̀.
O kì í jáni kulẹ̀.
Olùtùnú ni ọ́.
Mo gbẹ́kẹ̀ lé ọ pátá.
Ọkàn mi balẹ̀ lọ́dọ̀ rẹ.
(ÈGBÈ)
Ọpẹ́lọpẹ́
Ọlọ́run mi
Tó gbóhùn mi
Tó ṣàánú mi,
Kò sóhun tí
Baba kò rí.
Ó ń gbọ́ tèmi;
Kò fi mí lẹ̀.
Bí ‘ṣòro tilẹ̀ pọ̀,
Jáà wà pẹ̀lú mi.
Ọlọ́run mi
Ló gbóhùn mi
Tó ṣàánú mi
Kò sóhun tí
Baba kò rí.
Ó ń gbọ́ tèmi;
Kò fi mí lẹ̀.
Bí ‘ṣòro tilẹ̀ pọ̀,
Jáà wà pẹ̀lú mi.