Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 125

“Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”

“Aláyọ̀ Ni Àwọn Aláàánú”

(Mátíù 5:7)

  1. 1. Aláàánú ni Ọlọ́run wa,

    Ó ń yọ́nú síni látọkàn,

    Ó nífẹ̀ẹ́ láti máa ṣoore;

    Kì í fi ohun tá a fẹ́ dù wá.

    Ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá yí pa dà

    Mọ̀ pé Ó máa yọ́nú sáwọn.

    Tor’ó mọ̀ páláìpé ni wá,

    Olóore ni, olóòótọ́ ni.

  2. 2. Bàbá, gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ wa;

    Ẹ̀ṣẹ̀ mú ọkàn wa gbọgbẹ́.

    K’Ọ́lọ́run lè dárí jì wá,

    Kristi kọ́ wa lóhun tá ó ṣe:

    Pé ká bẹ̀bẹ̀ fún àánú rẹ̀,

    Ká sì lẹ́mìí ìdáríjì.

    Tá a kò bá dira wa sínú,

    A ó máa ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

  3. 3. Ká jẹ́ ẹlẹ́mìí ọ̀làwọ́,

    Kí àánú jẹ́ ká máa fúnni,

    Kì í ṣe lọ́nà ṣekárími;

    Ìyẹn máa jẹ́ ká lè láyọ̀.

    Ọlọ́run ń rí wa kedere,

    Yóò san wá lẹ́san ní gbangba.

    Aláyọ̀ làwọn aláàánú;

    Wọ́n lẹ́wà lójú Ọlọ́run.