Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 13

Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

Kristi, Àwòkọ́ṣe Wa

(1 Pétérù 2:21)

  1. 1. Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa,

    Ó ṣoore ńlá fún wa.

    Ó fọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n r’aráyé pa dà.

    Nígbà tó wá sáyé,

    Àpẹẹrẹ rere ni.

    Ìwà rẹ̀ gbórúkọ Ọlọ́run ga.

  2. 2. Ọ̀rọ̀ Jèhófà yè;

    Ó fún Jésù nímọ̀,

    Ó sì fún un lóye, ó gbé ẹ̀mí rẹ̀ ró.

    Bó ṣe j’ónírẹ̀lẹ̀

    Jẹ́ àpẹẹrẹ fún wa.

    Ó máa ń wù ú láti ṣèfẹ́ Jèhófà.

  3. 3. Bíi ti Jésù Kristi,

    Kígbèésí ayé wa

    Máa mú ìyìn bá Jèhófà Bàbá wa.

    Ká fìwà jọ Jésù

    Lójoojúmọ́ ayé,

    Ká lè máa rójú rere Jèhófà.