Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 140

Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín!

Ìyè Àìnípẹ̀kun Nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín!

(Jòhánù 3:16)

  1. 1. Fi ojú inú rẹ wo

    Àwọn tó ń gbé nírẹ̀ẹ́pọ̀.

    Kò sẹ́kún mọ́; wọ́n ń láyọ̀.

    Ìrora kò sí mọ́.

    (ÈGBÈ)

    Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!

    Ayé tuntun dé tán.

    Títí láéláé la ó máa gbé

    Inú ayé tuntun.

  2. 2. A ò ní máa darúgbó mọ́.

    Àlàáfíà ni yóò jọba.

    Wàhálà kò ní sí mọ́.

    Kò ní síbẹ̀rù mọ́.

    (ÈGBÈ)

    Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!

    Ayé tuntun dé tán.

    Títí láéláé la ó máa gbé

    Inú ayé tuntun.

  3. 3. A ó gbádùn Párádísè.

    Ògo Jáà yóò máa tàn yòò.

    Gbogbo ọjọ́ ayé wa

    La ó máa kọrin ìyìn.

    (ÈGBÈ)

    Jẹ́ ká fayọ̀ kọrin!

    Ayé tuntun dé tán.

    Títí láéláé la ó máa gbé

    Inú ayé tuntun.