Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

ORIN 62

Orin Tuntun

Orin Tuntun

(Sáàmù 98)

  1. 1. Kọ orin tuntun, orin ìyìn s’Ọ́lọ́run wa

    Sọ àwọn nǹkan tó ṣe, àtèyí tó máa ṣe.

    Ní gbogbo ọ̀nà, Onídàájọ́ òdodo ni.

    Yin Olódùmarè,

    Ọlọ́run aṣẹ́gun.

    (ÈGBÈ)

    Kọ orin!

    Gbé ohùn rẹ sókè.

    Kọrin pé:

    Jèhófà lọba wa!

  2. 2. Bú sórin ayọ̀, fayọ̀ kọrin sí Ọlọ́run!

    Gbé orúkọ rẹ̀ ga, kó o sì máa fògo fúnun.

    Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kọrin ìyìn sí Ọlọ́run

    Ìwọ náà, dara pọ̀,

    Kí gbogbo wa jọ yìn ín.

    (ÈGBÈ)

    Kọ orin!

    Gbé ohùn rẹ sókè.

    Kọrin pé:

    Jèhófà lọba wa!

  3. 3. Kí omi òkun àtàwọn ẹ̀dá inú rẹ̀

    Fìyìn f’Ọ́lọ́run wa, kí wọ́n sì fò fáyọ̀.

    Kí ilẹ̀ ayé àti àwọn òkè máa yọ̀.

    Jẹ́ kí gbogbo odò

    Máa fìyìn f’Ọ́lọ́run.

    (ÈGBÈ)

    Kọ orin!

    Gbé ohùn rẹ sókè.

    Kọrin pé:

    Jèhófà lọba wa!