Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìbínú?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Bíbélì kọ́ wa pé téèyàn bá ń bínú, tí kò sì ṣẹ́pá ìbínú yẹn, ó léwu fún onítọ̀hún àtàwọn tó yí i ká. (Òwe 29:22) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì, ó tọ́ kéèyàn bínú, Bíbélì sọ pé àwọn tí ò bá yéé ‘bínú fùfù’ ò ní rígbàlà. (Gálátíà 5:19-​21) Àwọn ìlànà wà nínú Bíbélì tó lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti ṣẹ́pá inú tó ń bí i.

 Ṣé gbogbo ìgbà ló burú láti bínú?

 Rárá. Ó tọ́ kéèyàn bínú nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin olódodo tó ń jẹ́ Nehemáyà “bínú gidigidi” nígbà tó gbọ́ pé àwọn kan ń fìyà jẹ àwọn tó jẹ́ olùjọ́sìn Ọlọ́run bíi tiẹ̀.​—Nehemáyà 5:6.

 Àwọn ìgbà kan wà tí inú bí Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn èèyàn rẹ̀ láyé àtijọ́ da májẹ̀mú tí wọ́n bá a dá pé òun nìkan làwọn á máa jọ́sìn, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sin àwọn ọlọ́run èké, “ìbínú Jèhófà ru sí” wọn. (Onídàájọ́ 2:13, 14) Àmọ́ Jèhófà Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run onínú fùfù o. Gbogbo ìgbà tó bá bínú ni ìbínú ẹ̀ máa ń tọ̀nà, ó sì máa ń kápá ìbínú rẹ̀.​—Ẹ́kísódù 34:6; Aísáyà 48:9.

 Ìgbà wo ló burú láti bínú?

 Téèyàn bá ń bínú láìnídìí, tí kò sì ṣẹ́pá ìbínú náà, kò tọ̀nà. Bí ìbínú àwa èèyàn aláìpé ṣe sábà máa ń rí nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ:

  •   “Ìbínú Kéènì . . . gbóná gidigidi” nígbà tí Ọlọ́run ò gba ẹbọ rẹ̀. Kéènì ò sì ṣẹ́pá ìbínú rẹ̀ yìí títí ó fi pa àbúrò rẹ̀.​—Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8.

  •   Inú wòlíì Jónà “ru fún ìbínú” nígbà tí Ọlọ́run ṣàánú àwọn ará Nínéfè. Ọlọ́run tọ Jónà sọ́nà, ó jẹ́ kó rí i pé “ríru tí inú [rẹ̀] ru fún ìbínú” kì í ṣe “lọ́nà ẹ̀tọ́”, ó sì yẹ kó ṣàánú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà yẹn.​—Jónà 3:10–​4:1, 4, 11. a

 Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ ká rí i pé, “ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.”​—Jákọ́bù 1:20.

 Báwo lo ṣe lè ṣẹ́pá inú tó ń bí ẹ?

  •   Mọ ewu tó wà nínú kéèyàn máa bínú sódì. Àwọn kan lè rò pé akin lẹni tó bá ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé inú ń bí òun. Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé tẹ́nì kan ò bá lè kápá inú tó ń bí i, ìṣòro ńlá ló ní yẹn. Bíbélì sọ pé: “Bí ìlú ńlá tí a ya wọ̀, láìní ògiri, bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn tí kò kó ẹ̀mí rẹ̀ níjàánu.” (Òwe 25:28; 29:11) Ṣùgbọ́n tá a bá ń sapá láti ṣẹ́pá ìbínú wa, ìgbà yẹn gangan la lè sọ pé a jẹ́ akin, ó sì fi hàn pé a ní ìfòyemọ̀. (Òwe 14:29) Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó lọ́ra láti bínú sàn ju alágbára ńlá.”​—Òwe 16:32.

  •   Wá nǹkan ṣe sí inú tó ń bí ẹ kó tó mú kó o ṣe ohun tó o máa kábàámọ̀. Sáàmù 37:8 sọ pé, “Jáwọ́ nínú ìbínú, kí o sì fi ìhónú sílẹ̀”, ó wá fi kún un pé: “Má ṣe gbaná jẹ kìkì láti ṣe ibi.” Wàá rí i pé tínú bá ń bí wa, a lè yàn láti gbé ìbínú yẹn kúrò lọ́kàn kó tó di pé á mú ká “ṣe ibi.” Bí Éfésù 4:26 ṣe sọ, ó ní, “ẹ fi ìrunú hàn, síbẹ̀ kí ẹ má ṣẹ̀.”

  •   Tó bá ṣeé ṣe, kúrò níbi tí ọ̀rọ̀ ti ṣẹlẹ̀ kí inú tó ń bí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í pọ̀. Bíbélì sọ pé, “Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ asọ̀ dà bí ẹni tí ń tú omi jáde; nítorí náà, kí aáwọ̀ tó bẹ́, fi ibẹ̀ sílẹ̀.” (Òwe 17:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mu láti tètè máa yanjú aáwọ̀ tó bá wà láàárín àwa àti àwọn míì, síbẹ̀, ó dáa kí ìwọ àti ẹni tẹ́ ẹ jọ ní aáwọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ kí inú yín rọ̀ kẹ́ ẹ tó jọ jókòó sọ ọ̀rọ̀ náà.

  •    Wádìí ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an. Òwe 19:11 sọ pé, “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀.” Ó bọ́gbọ́n mu ká kọ́kọ́ wádìí gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ká tó parí èrò síbì kan. Tá a bá fara balẹ̀ gbọ́ kúlẹ̀kúlẹ̀ ọ̀rọ̀ kàn, ó ṣeé ṣe ká rí i pé kò sídìí láti bínú.​—Jákọ́bù 1:19.

  •    Gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún ẹ ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Àdúrà lè jẹ́ kó o ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:7) Àdúrà wà lára àwọn ọ̀nà pàtàkì tá a fi ń rí ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run gbà, ẹ̀mí mímọ́ sì lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ bí àlàáfíà, sùúrù àti ìkóra-ẹni-níjàánu.​—Lúùkù 11:13; Gálátíà 5:22, 23.

  •   Fara balẹ̀ yan àwọn tó o máa mú lọ́rẹ̀ẹ́. Wọ́n máa ń sọ pé àgùntàn tó bá bájá rìn á jẹ ìgbẹ́. (Òwe 13:20; 1 Kọ́ríńtì 15:33) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi kìlọ̀ fún wa pé: “Má ṣe bá ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ara fún ìbínú kẹ́gbẹ́; má sì bá ènìyàn tí ó máa ń ní ìrufùfù ìhónú wọlé.” Kí nìdí? “Kí ìwọ má bàa mọ àwọn ipa ọ̀nà rẹ̀ dunjú, kí o sì gba ìdẹkùn fún ọkàn rẹ dájúdájú.”​—Òwe 22:24, 25.

a Ó jọ pé Jónà gba ìtọ́sọ́nà yẹn, inú rẹ̀ sì wá rọ̀, torí pé Ọlọ́run lò ó láti kọ ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ orúkọ rẹ̀.