Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára?

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Gbígba Ẹ̀jẹ̀ Sára?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Àṣẹ Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ni pé a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ gba ògidì ẹ̀jẹ̀ sára tàbí èyíkéyìí lára àwọn èròjà tó pilẹ̀ ẹ̀jẹ̀, a kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ́ bí oúnjẹ tàbí ká fà á sára. Kíyè sí ohun tí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ:

  •   Jẹ́nẹ́sísì 9:4. Lẹ́yìn ìkún omi, Ọlọ́run gba Nóà àti ìdílé rẹ̀ láyè láti máa jẹ ẹran, àmọ́ Ọlọ́run pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran. Ọlọ́run sọ fún Nóà pé: “Kìkì ẹran pẹ̀lú ọkàn rẹ̀—ẹ̀jẹ̀ rẹ̀—ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ jẹ.” Àṣẹ yìí kan gbogbo èèyàn láti ìgbà ayé Nóà títí di ìsinsìnyí torí pé àtọmọdọ́mọ rẹ̀ ni gbogbo wa.

  •   Léfítíkù 17:14. “Ẹ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran ara èyíkéyìí, nítorí pé ọkàn gbogbo onírúurú ẹran ara ni ẹ̀jẹ̀ rẹ̀. Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ẹ́ ni a óò ké kúrò.” Lójú Ọlọ́run, ọkàn tàbí ẹ̀mí wà nínú ẹ̀jẹ̀, Ọlọ́run ló sì ni ẹ̀mí náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nìkan ni Ọlọ́run fún ní òfin yìí, síbẹ̀ ó jẹ́ ká mọ irú ojú tí Ọlọ́run fi wo òfin tó ka jíjẹ ẹ̀jẹ̀ léèwọ̀.

  •   Ìṣe 15:20. “Ta kété . . . sí ẹ̀jẹ̀.” Àṣẹ kan náà tí Ọlọ́run pa fún Nóà ló wà fún àwọn Kristẹni. Ìtàn àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi hàn pé wọn kò jẹ ògidì ẹ̀jẹ̀ tàbí kí wọ́n fi wo àìsàn.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi pàṣẹ pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀?

 Ẹ̀rí láti agbo ìṣègùn fi hàn pé gbígba ẹ̀jẹ̀ sára léwu fún ìlera ara wa. Èyí tó tiẹ̀ ṣe pàtàkì jù ni pé Ọlọ́run ló pa á láṣẹ fún wa pé ká ta kété sí ẹ̀jẹ̀ torí pé ohun tí ẹ̀jẹ̀ dúró fún jẹ́ mímọ́ lójú rẹ̀.—Léfítíkù 17:11; Kólósè 1:20.