Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?

Báwo Ni Jésù Ṣe Ń Gbani Là?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

 Jésù gba àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ là nígbà tó fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ láti rà wọ́n pa dà. (Mátíù 20:28) Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi pe Jésù ní “Olùgbàlà ayé.” (1 Jòhánù 4:14) Bíbélì tún sọ pé: “Kò sí ìgbàlà kankan nínú ẹnikẹ́ni mìíràn, nítorí kò sí orúkọ mìíràn lábẹ́ ọ̀run tí a ti fi fúnni láàárín àwọn ènìyàn nípasẹ̀ èyí tí a ó fi gbà wá là.”​—Ìṣe 4:12.

 Jésù “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn” tó gbà á gbọ́. (Hébérù 2:9; Jòhánù 3:16) Lẹ́yìn náà, “Ọlọ́run gbé [Jésù] dìde kúrò nínú òkú,” ó sì pa dà sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí. (Ìṣe 3:15) Ibẹ̀ sì ni Jésù ti ń ‘gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.’​—Hébérù 7:25.

Kí nìdí tá a fi nílò Jésù láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wa?

 Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni gbogbo wa. (Róòmù 3:23) Ẹ̀ṣẹ̀ ló jẹ́ ká jìnnà sí Ọlọ́run, òun náà ló fàá tá a fi ń kú. (Róòmù 6:23) Àmọ́ Jésù ló ń ran àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà lọ́wọ́. (1 Jòhánù 2:1) Ó ń bá wọn bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run, pé kí Ọlọ́run wo ọlá ìràpadà, kó dáhùn àdúrà wọn, kó sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n. (Mátíù 1:21; Róòmù 8:34) Ọlọ́run máa ń gbọ́ ẹ̀bẹ̀ Jésù torí pé ohun tó ń béèrè fún bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé “kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.”​—Jòhánù 3:17.

Ṣé tá a bá ṣáà ti nígbàgbọ́ nínú Jésù, a máa rí ìgbàlà?

 Rárá. Lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ gba Jésù gbọ́ ká tó lè rí ìgbàlà, àmọ́ ohun púpọ̀ ṣì wà tó yẹ ká ṣe. (Ìṣe 16:30, 31) Bíbélì sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Ká a tó lè rí ìgbàlà, a gbọ́dọ̀:

  •   Kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù àti Jèhófà Baba rẹ̀.​—Jòhánù 17:3.

  •   Ní ìgbàgbọ́ nínú wọn.​—Jòhánù 12:44; 14:1.

  •   Máa tẹ̀lé àṣẹ wọn torí ìyẹn ló máa fi hàn pé a nígbàgbọ́ nínú wọn. (Lúùkù 6:46; 1 Jòhánù 2:17) Jésù kọ́ wa pé, kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá ń pe òun ní “Olúwa” ló máa rí ìgbàlà, ó sọ pé àwọn tó bá ń “ṣe ìfẹ́ Baba [òun] tí ń bẹ ní ọ̀run.”​—Mátíù 7:21.

  •   Máa fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́, láìka bí nǹkan ṣe le sí. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn gan-an nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”​—Mátíù 24:13.