Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ṣé Mósè Ló Kọ Bíbélì?

Ṣé Mósè Ló Kọ Bíbélì?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Ọlọ́run lo Mósè láti kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ nínú Bíbélì: Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Númérì àti Diutarónómì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ òun náà ló kọ ìwé Jóòbù àti Sáàmù 90. Àmọ́, ọ̀kan lára nǹkan bí ogójì [40] èèyàn tí Ọlọ́run lò láti kọ Bíbélì ni Mósè jẹ́.