Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Orúkọ?

Ǹjẹ́ Ọlọ́run Ní Orúkọ?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Gbogbo èèyàn ló ní orúkọ. Ǹjẹ́ kò bọ́gbọ́n pé kí Ọlọ́run ní orúkọ tiẹ̀? Bí a ṣe ń fi orúkọ àwọn èèyàn pè wọ́n máa ń jẹ́ kí ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú wọn dán mọ́rán. Ṣé kì í ṣe bó ṣe yẹ kó rí náà nìyẹn nínú ìbádọ́rẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú Ọlọ́run?

 Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” (Aísáyà 42:8) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ọlọ́run ní ọ̀pọ̀ orúkọ oyè, bí “Ọlọ́run Olódùmarè,” “Olúwa Ọba Aláṣẹ,” àti “Ẹlẹ́dàá,” ó dá àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ lọ́lá pé kí wọ́n máa fi orúkọ òun pe òun.—Jẹ́nẹ́sísì 17:1; Ìṣe 4:24; 1 Pétérù 4:19.

 Nínú ọ̀pọ̀ ìtumọ̀ Bíbélì, a rí orúkọ Ọlọ́run ní Ẹ́kísódù 6:3. Ẹsẹ yẹn sọ pé: “Èmi sì ti máa ń fara han Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù ní Ọlọ́run Olódùmarè, ṣùgbọ́n ní ti orúkọ mi Jèhófà èmi kò sọ ara mi di mímọ̀ fún wọn.”

 Láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni a ti ń pé orúkọ Ọlọ́run ní Jèhófà lédè Yorùbá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé “Yáwè” ni ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé máa ń kọ sílẹ̀, àmọ́ Jèhófà ni orúkọ táwọn èèyàn mọ̀ jù lọ. Kì í ṣe èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi kọ apá àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ́, wọ́n máa ń ka èdè yìí láti apá ọ̀tún sí apá òsì. Ní èdè Hébérù, wọ́n máa ń fi kọ́ńsónáǹtì mẹ́rin yìí, יהוה kọ orúkọ Ọlọ́run. Àwọn lẹ́tà tí wọ́n máa fi ń dípò àwọn kọ́ńsónáǹtì Hébérù mẹ́rin náà ni YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run.