Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Àwọn Ohun Alààyè

Bí Àwọn Ewéko Ṣe Ń Ṣètò Oúnjẹ Wọn​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo làwọn ewéko ṣe ń ṣètò oúnjẹ wọn, àǹfààní wo ló sì ń ṣe wá?

Àwọn Ohun Alààyè Ń Ṣọ́ Agbára Wọn Lò​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ṣé ńṣe làwọn ohun alààyè kàn ṣàdédé ń ṣọ́ agbára wọn lò, àbí ẹnì kan ló ṣètò pé kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀?

Ohun Alààyè Ń Mú Ìmọ́lẹ̀ Jáde​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Kì í ṣe pé àwọn ohun alààyè yìí kan ń mú ìmọ́lẹ̀ jáde nìkan, àmọ́ wọ́n tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó dáa ju ohun táwọn èèyàn ṣe lọ. Kí ló mú kọ́rọ̀ rí bẹ́ẹ̀?

Ara Àwa Èèyàn

Bí Afẹ́fẹ́ Oxygen Ṣe Ń Lọ Káàkiri Ara​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

O lè mọ̀ nípa ohun àrà tó ń mú kí afẹ́fẹ́ oxygen dé gbogbo ibi tí ara ti nílò ẹ̀.

Bí Ara Wa Ṣe Ń Mú Kí Egbò Jiná

Báwo làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe wo àpẹẹrẹ yìí láti fi ṣe oríṣi ike tuntun kan?

Àwọn Ẹranko

Imú Erin—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ẹnu ya àwọn tó ń ṣèwádìí nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò imú erin. Wàá rí ohun tó mú kí imú erin ṣàrà ọ̀tọ̀.

Ọpọlọ Ọ̀kẹ́rẹ́ Inú Yìnyín​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Wo fídíò yìí kó o lè rí agbára àrà ọ̀tọ̀ tí ọ̀kẹ́rẹ́ yìí ní láti mú kí ara ẹ̀ bọ̀ sípò lẹ́yìn tó ti sùn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́.

Irun Ara Ẹran Omi Tó Ń Jẹ́ Otter—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Àwọn ẹranko inú omi kan máa ń ní ọ̀rá lábẹ́ awọ wọn, èyí sì máa ń mú kí ara wọn móoru kí òtútù máa bàa tètè mú wọn. Àmọ́, ọ̀nà mí ì ni ara otter ń gbà móoru.

Ahọ́n Ológbò​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Nǹkan bí ìdá mẹ́rin àsìkò tí ológbò kò fi sùn ló fi ń tọ́jú ara ẹ̀. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún un láti máa tọ́jú ara ẹ̀?

Ise Ti Irun Imu Ologbo N Se

Ki nidi ti awon onimo sayensi fi n se robooti ti won pe ni e-whiskers?

Bí Ajá Ṣe Ń Gbóòórùn

Kí ló ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú bí ajá ṣe máa ń gbóòórùn nǹkan, táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì fi ń gbìyànjú àtimáa ṣe àwọn èrọ tó lè ṣe nǹkan tí ajá ń ṣe yìí?

Bí Àdán Ṣe Ń Fi Ìró Mọ Ohun Tó Wà Láyìíká Rẹ̀​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún ẹranko kan láti “ríran” láìlo ojú rẹ̀?

Òòlẹ̀ Ara Ìṣáwùrú Tó Ń Yọ̀

Táwọn oníṣègùn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ bá ní òòlẹ̀ tó dà bí òòlẹ̀ ara ìṣáwùrú, ó máa di ọ̀kan pàtàkì lára irin iṣẹ́ tí wọ́n á máa lò, kò sì ní sí pé wọ́n ń rán ẹ̀yà ara mọ́.

Àwọn Ohun Abẹ̀mí Inú Òkun

Awọ Ẹja Àbùùbùtán​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo ni awọ ẹja àbùùbùtán ṣe máa ń dáàbò bò ó lọ́wọ́ kòkòrò àrùn?

Lẹbẹ Ẹja Àbùùbùtán

Kọ́ nípa bí lẹ́bẹ́ ẹranko ńlá yìí ṣe ti nípa lórí ìgbésí ayé rẹ.

Bí Awọ Ẹja Àbùùbùtán Ṣe Máa Ń Fọ Ara Ẹ̀

Kí nìdí tí àrà tí ẹja yìí máa ń dá fi wu àwọn iléeṣẹ́ tó ń fi ọkọ̀ òkun kẹ́rù?

Bí Ẹja Dolphin Ṣe Ń Mọ Ohun Tó Ń Lọ Lábẹ́ Omi

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ń gbìyànjú láti ṣe ohun tó jọ nǹkan àgbàyanu táwọn ẹja yìí ń ṣe láti mọ ohun tó ń lọ láyìíká wọn.

Omi Tó Ń Yọ̀ Tó Wà Lára Ẹja Hagfish​​—⁠Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ohun ìríra ló jẹ́ fáwọn ẹranko tó fẹ́ pa ẹja hagfish jẹ́, àmọ́ ohun àrà ló jẹ́ fáwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì. Kí nìdìí?

Àwọ̀ Ẹja Sea Cucumber

Kí ló mú kí àwọ̀ ẹja inú òkun yìí máa yíra pa dà?

Bí Ẹja Grunion Ṣe Ń Yé Ẹyin​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Wàá rí bí àwọn ẹja yìí ṣe ń yé ẹyin tí wọ́n sì ń dáàbò bò ó, káwọn ẹyin náà má bàa kú.

Bí Eyín Ìgbín Limpet Ṣe Rí

Kí ló mú kí eyín ìgbín limpet lágbára ju okùn aláǹtakùn lọ?

Bí Barnacle Ṣe Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan

Agbára tí barnacle fi ń lẹ̀ mọ́ nǹkan ju ti gọ́ọ̀mù èyíkéyìí téèyàn ṣe lọ. Ẹnu àìpẹ́ yìí làwọn èèyàn mọ àṣírí bí barnacles ṣe ń lẹ̀ mọ́ ibi tó bá lómi.

Ohun Àrà Kan Nípa Ìṣáwùrú Òkun

Ìṣáwùrú òkun máa ń lẹ̀ mọ́ nǹkan tímọ́tímọ́. Tá a bá mọ bó ṣe ń ṣe é, ó máa jẹ́ ká lè ṣe ohun tó ṣe lẹ nǹkan mọ́ ara ilé, tàbí lẹ iṣan àti eegun pọ̀.

Ìkarawun ìṣáwùrú

Bí ìkarawun ìṣáwùrú ṣe rí máa ń jẹ́ kó lè dáàbò bo ìṣáwùrú.

Apá Àràmàǹdà Tí Octopus Ní​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Àwọn ẹnjiníà ti ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ní apá tó ń ṣiṣẹ́ àgbàyanu.

Ìrù Ẹja Olórí Ẹṣin

Wo bí ìrù ẹja olórí ẹṣin tó ṣàrà ọ̀tọ̀ gan-an ṣe ń ran àwọn tó ń ṣe rọ́bọ́ọ̀tì lọ́wọ́ láti ṣe èyí tó dáa ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Bí Ẹja Remora Ṣe Máa Ń Lẹ̀ Mọ́ Nǹkan​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Kí ló ń mú kó rọrùn fún ẹja yìí láti máa lẹ̀ mọ́ ẹja àtàwọn nǹkan nínú omi?

Bí Asẹ́ Tó Wà Lẹ́nu Ẹja Àpátámàjà Ṣe Ń Ṣiṣẹ́​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo ni asẹ́ ẹnu ẹja àpátámàjà ṣe ń sẹ́ àwọn ẹja tíntìntín tó yẹ kó bá omi jáde, kó lè lọ sí ọ̀nà ọ̀fun ẹja náà bí oúnjẹ?

Àwọn Ẹyẹ

Ahọ́n Ẹyẹ Akùnyùnmù​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ẹyẹ kékeré yìí máa ń la omi inú òdòdó láì lo agbára ẹ̀ rárá.

Bí Ẹyẹ Gannet Ṣe Máa Ń Bẹ́ Ludò​​—⁠Ṣé Ẹnì Kan Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo làwọn ẹyẹ náà ṣe ń rù ú là tí wọ́n á sì tún pa dà já wọnú omi pẹ̀lú agbára tó ju ti òòfà lọ lọ́nà ogún?

Àwọ̀ Ẹyẹ Tí Kì Í Ṣá

Kí làwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ṣàwárí nípa àwọ̀ àwọn ẹyẹ tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣe ọ̀dà tàbí aṣọ tí kò ní ṣá?

Ìyẹ́ Òwìwí

Bí ìyẹ́ òwìwí ṣe rí lè jẹ́ káwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ nǹkan tí wọ́n máa ṣe sí àwọn ẹ̀rọ tó ń bátẹ́gùn ṣiṣẹ́ tí wọ́n fi ń fáwọn èèyàn níná, tí ò fi ní máa pariwo.

Wẹ́rẹ́ Ni Ẹyẹ Albatross Máa Ń Fò

Wo bí ẹyẹ yìí ṣe máa ń fò fún ọ̀pọ̀ wákàtí láìmi ìyẹ́ apá rẹ̀!

Bí Ẹyẹ Godwit Ṣe Ń Rìnrìn Àjò

Kà nípa ìrìn ààjò ọlọ́jọ́ mẹ́jọ ti ẹyẹ Godwit máa ń rìn. Ohun àgbàyanu gbáà ni.

Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Malle Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ẹyẹ yìí máa n ṣiṣẹ́ àrà kan ní ti pé ó máa ń kọ ìtẹ́ tó móoru fún ẹyin rẹ̀. Báwo ló ṣe ń ṣe é tí ìtẹ́ rẹ̀ fi máa ń móoru láàárọ̀, lọ́sàn-án àti lálẹ́ jálẹ̀ ọdún?

Àwọn Ẹranko Afàyàfà Àtàwọn Jomijòkè

Bí Awọ Aláǹgbá Thorny Devil Ṣe Ń Fa Omi Mu

Báwo ni aláǹgbá yìí ṣe ń fa omi láti ẹsẹ̀ rẹ̀ wá sí ẹnu rẹ̀?

Ìrù Aláǹgbá Adárípọ́n

Báwo ni aláǹgbá yìí ṣe máa ń fò láti ibi tó tẹ́jú pẹrẹsẹ sí ara ògiri?

Párì Ọ̀nì—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Agbára tó fi ń deyín mọ́ nǹkan fi ìlọ́po mẹ́ta ju ti kìnnìún àti ẹkùn lọ, síbẹ̀ ó máa ń yára mọ nǹkan lára ju àwa èèyàn lọ. Kí nìdí?

Ọ̀nà Àrà Táwọn Ọ̀pọ̀lọ́ Japanese Tree Ń Gbà Pe Ara Wọn​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo ni akọ ọ̀pọ̀lọ́ Japanese tree ṣe ń gbé ìró ohùn jáde tó bá fẹ́ fa ojú abo mọ́ra?

Kòròrò

Bí Oyin Ṣe Ń Fò Láìka Atẹ́gùn Tó Le Sí​—⁠Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Báwo ni oyin kékeré ṣe ń ṣe tó fi lè fò ju àwọn awakọ̀ ofúurufú tó já fáfá lọ tí atẹ́gùn tó le bá ń fẹ́?

Ọgbọ́n Tí Oyin Fi Ń Bà Lé Nǹkan

Kí ló mú kí ọgbọ́n tí oyin fi ń bà lé nǹkan láìfarapa wúlò fún àwọn tó ń ṣe rọ́bọ́ọ̀tì tó ń fò?

Báwo Ni Àwọn Èèrà Ṣe Ń Rìn Láìsí Sún Kẹẹrẹ Fà Kẹẹrẹ?

Àwọn èèrà máa ń rìn láìsí sún kẹẹrẹ fa kẹẹrẹ. Báwo ni wọ́n ṣe ń ṣe é?

Ọrùn Èèrà

Báwo ni èèrà ṣe ń gbé nǹkan tó wúwo ju òun fúnra rẹ̀ lọ?

Bí Eèrà Talamọ́ Ṣe Ń Nu Ìdọ̀tí Ara Rẹ̀

Kòkòrò kékeré yìí gbọ́dọ̀ máa nu ìdọ̀tí tó bá yí i lára kó má bàa kú. Báwo ló ṣe máa ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí?

Kòkòrò Saharan Silver

Ọ̀kan lára àwọn kòkòrò tó lè farada ooru gbígbóná ni kòkòrò yìí. Báwo ló ṣe ń ṣe é?

Bí Kòkòrò Periodical Cicada Ṣe Ń Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀

Bí kòkòrò yìí ṣe ń gbé ìgbé ayé rẹ̀ máa ń yani lẹ́nu torí pé ẹ̀ẹ̀kan ni wọ́n máa ń fara hàn láàárín ọdún mẹ́tàlá sí ọdún mẹ́tàdínlógún, wọ́n á sì lo ọ̀sẹ̀ mélòó kan péré.

Bí Tata Katydid Ṣe Ń Gbọ́ràn Jọni Lójú Gan-an

Bí etí tata katydid kékeré yìí ṣe ń ṣiṣẹ́ dà bíi ti èèyàn. Báwo ní ìwádìí nípa tata yìí á ṣe dá kún ìtẹ̀síwájú lágbo àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀?

Bí Labalábá Monarch Ṣe Ń Ṣí Kiri​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Ó máa jọ ẹ́ lójú gan-an tó o bá rí báwọn labalábá kan tí wọ́n ń pè ní monarch ṣe ń ṣí kiri. Ṣé o rò pé ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

Ìyẹ́ Labalábá Cabbage White

Kí ni àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ rí lára labalábá cabbage white tó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ṣe àwọn páànù solar tó túbọ̀ gbéṣẹ́?

Èyìn Kòkòrò Diabolical Ironclad Beetle​—Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Kí ni kì í jẹ́ kí kòkòrò yìí kú tí nǹkan tó lágbára gan-an bá tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀?

Bí Eṣinṣin Ìgbẹ́ Ṣe Máa Ń Dábírà Tó Bá Ń Fò

Kòkòrò yìí lè fò bí ọkọ̀ òfuurufú táwọn ológun máa ń lò, àmọ́ òun tún lè dédé ṣẹ́rí pa dà lórí eré, láàárín ohun tí kò tó ìṣẹ́jú àáyá kan.

Ewéko

Èèpo Ọsàn Pomelo Tó Rára Gba Nǹkan Sí​​—⁠Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?

Lẹ́yìn táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàyẹ̀wò èèpo ọsàn pomelo dáadáa, kí ni wọ́n fẹ́ ṣe tó máa rára gba nǹkan sí bí èèpo ọsàn náà?

Èso Pollia

Kò sí ewéko tàbí èso kan láyé yìí tó ní àwọ̀ búlúù tó ń tàn yanran tó èsò pollia, bẹ́ẹ̀ sì rèé, kò sí èròjà olómi aró kankan nínú èso yìí. Kí ló mú kó máa tan yanran tó bẹ́ẹ̀?