Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì

Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì

O nílò ìmọ̀ràn tó wúlò! Irú ìmọ̀ràn bẹ́ẹ̀ lo máa rí nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì. Nínú ìwé yìí wàá rí ohun tí àwọn ọ̀dọ́ sọ kárí ayé nígbà tí a fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò. Ìmọ̀ràn tó wúlò látinú Bíbélì ràn wọ́n lọ́wọ́. Wo bó ṣe lè ran ìwọ náà lọ́wọ́.

Ìwé náà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè nípa:

  • Ọ̀rọ̀ Ọkùnrin àti Obìnrin

  • Ìyípadà Ara

  • Yíyan Ọ̀rẹ́

  • Iléèwé Àtàwọn Ojúgbà Rẹ

  • Ọ̀ràn Owó

  • Àwọn Òbí Rẹ

  • Bí Nǹkan Ṣe Ń Rí Lára Ẹ

  • Eré Ìtura

  • Àjọṣe Rẹ Pẹ̀lú Ọlọ́run

O lè wa ẹ̀dà PDF ìwé náà jáde, tàbí kó o kọ̀wé sí ọ́fíìsì wa láti béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé náà.

Àkíyèsí: Ẹ̀dà PDF ìwé yìí ti wá ní àlàfo tó ṣe é kọ ọ̀rọ̀ sí lórí ẹ̀rọ. Tí ẹ̀rọ rẹ bá ní ètò ìṣiṣẹ́ tó ń kọ ọ̀rọ̀ sí PDF, ó lè kọ àlàyé àti ìdáhùn rẹ sí orí PDF tó o wà sórí ẹ̀rọ rẹ.