Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì?

Kí Ló Ṣẹlẹ̀ sí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nígbà Ìpakúpa Rẹpẹtẹ Tó Wáyé Nígbà Ìjọba Násì?

 Nínú nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùndínlógójì (35,000) Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Jámánì àti láwọn orílẹ̀-èdè tí àwọn Násì ti ń ṣèjọba, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan ààbọ̀ (1,500) làwọn tó kú nínú wọn nígbà ìpakúpa rẹpẹtẹ tó wáyé nígbà ìjọba Násì. Kì í ṣe gbogbo àwọn tó kú la mọ ohun tó pa wọ́n. Ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́, torí náà, ó ṣeé ṣe ká mọ púpọ̀ sí i tó bá yá nípa iye àwọn tó kú àtàwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ míì.

 Irú ikú wo ni wọ́n kú?

  • Ẹ̀rọ guillotine táwọn Násì fi ń bẹ́ni lórí

      Wọ́n dájọ́ ikú fún wọn: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin (400) ni wọ́n dájọ́ ikú fún ní Jámánì àti láwọn orílẹ̀-èdè táwọn Násì ti ń ṣèjọba. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló fojú ba ilé ẹjọ́, tí wọ́n dájọ́ ikú fún, tí wọ́n sì bẹ́ lórí. Ṣe ni wọ́n yìnbọn pa àwọn míì, tí wọ́n sì gbé wọn kọ́ igi láìsí pé wọ́n ń kọ́kọ́ gbọ́ tẹnu wọn nílé ẹjọ́.

  •   Wọ́n fojú wọn gbolẹ̀ gan-an lọ́gbà ẹ̀wọ̀n: Ó lé ní ẹgbẹ̀rún kan (1,000) àwọn Ẹlẹ́rìí tó kú sí àwọn ọgbà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ àti ọgbà ẹ̀wọ̀n Násì. Àwọn kan ṣiṣẹ́ àṣekára títí ẹ̀mí wọn fi bọ́, ohun tó sì pa àwọn míì ni ìyà burúkú tí wọ́n fi jẹ wọ́n, bí wọ́n ṣe febi pa wọ́n, tí wọ́n sì ṣí wọn sí òtútù. Àìsàn àti àìrí ìtọ́jú gidi gbà ló pa àwọn míì. Torí bí wọ́n ṣe ṣe wọ́n ṣúkaṣùka lọ́gbà ẹ̀wọ̀n yìí, kò pẹ́ tí àwọn míì jáde lẹ́wọ̀n lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì tí wọ́n fi kú.

  •   Àwọn ohun míì tí wọ́n fi pa wọ́n: Wọ́n dé àwọn Ẹlẹ́rìí kan mọ́bi tó kún fún kẹ́míkà olóró, àwọn dókítà fi àwọn kan kọ́ṣẹ́, wọ́n sì gún àwọn míì ní abẹ́rẹ́ ikú.

 Kí nìdí tí wọ́n fi ṣenúnibíni sí wọn?

 Ohun tó fà á tí wọ́n fi ṣe inúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé wọ́n rọ̀ mọ́ ohun tí wọ́n kọ́ nínú Bíbélì. Nígbà tí ìjọba Násì ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ohun tó ta ko Bíbélì, wọn ò gbà láti ṣe é. Wọ́n pinnu láti “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Acts 5:​29) Wo apá méjì tí wọ́n ti ṣe irú ìpinnu yẹn.

  1.   Wọn ò dá sí òṣèlú. Bíi tàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yòókù kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ayé ìgbà ìjọba Násì náà ò dá sí ọ̀rọ̀ òṣèlú. (Jòhánù 18:36) Torí náà, wọ́n kọ̀ láti

  2.   Wọ́n ń ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n má ṣe ohun tí wọ́n gbà gbọ́, síbẹ̀ wọn ò jáwọ́, wọ́n ń

 Ọ̀jọ̀gbọ́n Robert Gerwarth sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “nìkan ni wọ́n ṣe inúnibíni sí láyé ìgbà ìjọba Násì torí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ lásán.” a Àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n jọ wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ mọyì àwọn Ẹlẹ́rìí gan-an torí bí wọn ò ṣe bọ́hùn lójú àtakò. Ẹlẹ́wọ̀n ọmọ ilẹ̀ Austria kan kíyè sí i pé: “Wọn kì í jagun. Wọ́n á yáà gbà kí wọ́n pa àwọn dípò káwọn pa ẹlòmíì.”

 Ibo ni wọ́n kú sí?

  •   Àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́: Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kú sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Ara àwọn àgọ́ tí wọ́n tì wọ́n mọ́ ni àgọ́ Auschwitz, Buchenwald, Dachau, Flossenbürg, Mauthausen, Neuengamme, Niederhagen, Ravensbrück àti Sachsenhausen. Ní Sachsenhausen nìkan, nǹkan bí igba (200) làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí ẹ̀rí wà pé wọ́n kú síbẹ̀.

  •   Ọgbà ẹ̀wọ̀n: Wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí kan lóró títí wọ́n fi kú sẹ́wọ̀n. Ọgbẹ́ táwọn míì fara gbà nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò ló pa wọ́n.

  •   Ibi tí wọ́n ti ń pààyàn: Àwọn ibi tí wọ́n ti pa ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n dájọ́ ikú fún ni ọgbà ẹ̀wọ̀n Berlin-Plötzensee, Brandenburg àti Halle/Saale. Yàtọ̀ síyẹn, a rí àkọsílẹ̀ àwọn ibòmíì tó tó àádọ́rin (70) tí wọ́n ti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn tí wọ́n dájọ́ ikú fún wọn.

 Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n pa

  •  Orúkọ: Helene Gotthold

     Ibi tí wọ́n ti pa á: Plötzensee (Berlin)

     Ìyàwó ilé ni Helene, ó sì ti bímọ méjì. Ó ju ẹ̀ẹ̀mejì lọ tí wọ́n ti fọlọ́pàá mú un. Nígbà tí wọ́n mú un lọ́dún 1937, tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n fìyà jẹ ẹ́ débi pé oyún bà jẹ́ lára ẹ̀. Nígbà tó di December 8, 1944, wọ́n fi ẹ̀rọ ńlá kan tí wọ́n ń pè ní guillotine bẹ́ ẹ lórí ní ọgbà ẹ̀wọ̀n Plötzensee, ní Berlin.

  •  Orúkọ: Gerhard Liebold

     Ibi tí wọ́n ti pa á: Brandenburg

     Ọmọ ogún (20) ọdún ni Gerhard nígbà tí wọ́n bẹ́ ẹ lórí ní May 6, 1943. Ọgbà ẹ̀wọ̀n yẹn kan náà ni wọ́n ti bẹ́ bàbá rẹ̀ lórí ní ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn. Ohun tó kọ sínú lẹ́tà ìdágbére tó kọ sí ìdílé ẹ̀ àti àfẹ́sọ́nà ẹ̀ ni pé: “Láìsí agbára Olúwa, mi ò bá má lè tọ ọ̀nà tí mo tọ̀ yìí.”

  •  Orúkọ: Rudolf Auschner

     Ibi tí wọ́n ti pa á: Halle/Saale

     Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún (17) péré ni Rudolf nígbà tí wọ́n bẹ́ ẹ lórí ní September 22, 1944. Ohun tó kọ sínú lẹ́tà ìdágbére tó kọ sí màmá ẹ̀ ni pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló ti tọ ọ̀nà yìí, èmi náà á sì tọ̀ ọ́.”

a Hitler’s Hangman: The Life of Heydrich, ojú ìwé 105.