Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Mélòó Ló Wà Kárí Ayé?

Ìròyìn Ọdún Iṣẹ́ Ìsìn 2023

Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé

8,816,562

Iye ìjọ

118,177

Iye ilẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù

239

Gbogbo Àròpọ̀ ti Ọdún 2023

Ìròyìn Orílẹ̀-èdè àti ti Ìpínlẹ̀ Ọdún 2023

Ta ni ẹ máa ń kà sí ara yín?

 Àwọn tó bá ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run lóṣooṣù nìkan la máa ń kà sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà. (Mátíù 24:14) Àwọn yìí lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ti ṣèrìbọmi tàbí àwọn tí kò tíì ṣèrìbọmi, àmọ́ tí wọ́n tóótun láti wàásù.

Ṣé ẹnì kan gbọ́dọ̀ fi owó ṣètọrẹ kó tó lè di ara yín?

 Rárá. Ọrẹ tí ẹnì kan bá ṣe kọ́ ló ń mú ká kà á sí Ẹlẹ́rìí tàbí ká fún un ní iṣẹ́ tàbí ipò pàtàkì kan nínú ìsìn wa. (Ìṣe 8:18-20) A ò tiẹ̀ kí í dárúkọ ọ̀pọ̀ àwọn tó bá ṣe ọrẹ. Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan máa ń lo àkókò rẹ̀, okun rẹ̀ àtàwọn ohun tó ní bó bá ṣe fẹ́ láti fi ti iṣẹ́ tá à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn, láìka bó ṣe ní lọ́wọ́ sí.​—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Báwo lẹ ṣe máa ń mọ iye àwọn tó ń wàásù déédéé?

 Lóṣooṣù, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìjọ kọ̀ọ̀kan máa ń ròyìn ohun tá a ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A kì í fi dandan mú ẹnikẹ́ni láti ròyìn.

 A máa ṣírò ìròyìn gbogbo ìjọ, àá wá fi ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan. Ẹ̀ka ọ́fíìsì máa wá fi ìròyìn orílẹ̀-èdè tàbí àgbègbè kọ̀ọ̀kan ránṣẹ́ sí oríléeṣẹ́ wa.

 Tí ọdún iṣẹ́ ìsìn kọ̀ọ̀kan bá parí, a a máa ń ṣírò góńgó iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ kọ̀ọ̀kan lọ́dún yẹn. A máa wá ro gbogbo iye yẹn pọ̀ ká lè mọ iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a wà kárí ayé. A máa ń gbé ìròyìn tó kún rẹ́rẹ́ nípa orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan jáde ní abala “Kárí Ayé” lórí ìkànnì wa. Àwọn ìròyìn yìí máa ń gbé wa ró, bí irú ẹ̀ ṣe gbé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ró.​—Ìṣe 2:​41; 4:4; 15:3.

Ṣé ẹ máa ń ka àwọn tó ń dara pọ̀ mọ́ yín àmọ́ tí wọn kì í wàásù mọ́ ara yín?

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a kì í ka àwọn yìí mọ́ iye àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, a máa ń gbà wọ́n tọwọ́-tẹsẹ̀ tí wọ́n bá wá sípàdé wa. Ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń wá síbi Ìrántí Ikú Kristi tá a máa ń ṣe lọ́dọọdún, a sì lè mọ iye tí wọ́n tó tá a bá yọ iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kúrò nínú iye àwọn tó wá sípàdé yìí kárí ayé. 2023, iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ 20,461,767.

 Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í wá sípàdé wa la máa ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn. 2023, àwọn 7,281,212 là ń bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóṣooṣù, ìgbà míì sì wà táwọn mélòó kan lára àwọn yìí jọ máa ń ṣèkẹ́kọ̀ọ́ pọ̀.

Kí nìdí tí iye tí ìjọba máa ń kà yín pé ẹ jẹ́ fi pọ̀ ju iye tí ẹ̀yin máa ń sọ pé ẹ jẹ́ lọ?

 Nígbà ìkànìyàn, ṣe ni àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba máa ń bi àwọn èèyàn ní ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Ilé Iṣẹ́ Ìkànìyàn lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé ìwádìí táwọn máa ń ṣe jẹ́ káwọn “mọ̀ bóyá àwọn èèyàn ka ara wọn mọ́ ẹ̀sìn kankan,” wọ́n sì sọ pé ohun táwọn èèyàn bá sọ máa ń nípa lórí iye táwọn kà torí wọn ò mọ̀ bóyá ẹ̀sìn yẹn ni wọ́n ń ṣe lóòótọ́. Àmọ́ ní tiwa, àwọn tó bá ń wàásù fáwọn ẹlòmíì tó sì ń ròyìn ohun tí wọ́n ṣe yẹn la máa ń kà sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kì í ṣe àwọn tó kàn ń sọ pé ara wa làwọn.

a Ọdún iṣẹ́ ìsìn kan bẹ̀rẹ̀ láti September 1 ọdún tó ṣáájú sí August 31 ọdún yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ọdún iṣẹ́ ìsìn 2015 bẹ̀rẹ̀ láti September 1, 2014, sí August 31, 2015.