Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Croatia

Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì

Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣebẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣebẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a si fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.

Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣebẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láàyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mù rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.

Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.

Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò.”

Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tíìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”

Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.

Ìbẹ̀wò

Štrokinec 28

HR-10090 ZAGREB-SUSEDGRAD

CROATIA

+385 1-37-95-001

Àwọn Iṣẹ́ Tí À Ń Ṣe Níbẹ̀

À ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ìjọ 57 lórílẹ̀-èdè Croatia àti ìjọ 16 lórílẹ̀-èdè Bosnia and Herzegovina. À ń túmọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sí èdè Bosnian, Croatian àti Èdè Adití ti Croatia. Àwọn tó bá wá máa ń rí àwọn ohun tó jẹ mọ́ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Yugoslavia àtijọ́ àti ipa tí orin ń kó nínú bá a ṣe ń yin Jèhófà.

Wa Ìwé Pẹlẹbẹ Tó Ń Ṣàlàyé Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Wa jáde