Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

“Mo Di Ọmọọ̀ta”

“Mo Di Ọmọọ̀ta”
  • Ọdún Tí Wọ́n Bí Mi: 1955

  • Orílẹ̀-Èdè Mi: Spain

  • Irú Ẹni Tí Mo Jẹ́ Tẹ́lẹ̀: Ìwà Ipá, Oògùn Olóró àti Ọtí Àmujù

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ

 Ó máa ń pẹ́ káwọn míì tó kẹ́kọ̀ọ́ láti inú àṣìṣe ara wọn. Bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ mi rí. Ìlú Barcelona, lórílẹ̀-èdè Spain ni wọ́n bí mi sí, ibẹ̀ sì ni mo gbé dàgbà. Ibì kan tó ń jẹ́ Somorrostro là ń gbé, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé etíkun ni gbogbo àgbègbè náà, àwọn oníwà ọ̀daràn àtàwọn tó ń lo oògùn olóró sì pọ̀ gan-an níbẹ̀.

 Èmi ni àkọ́bí nínú ọmọ mẹ́sàn-án táwọn òbí wa bí. A ò lówó lọ́wọ́, torí náà bàbá mi ní kí ń máa lọ ṣiṣé níbì kan tí wọ́n ti ń ṣe eré ìdárayá. Mi ò ju ọmọ ọdún mẹ́wàá lọ nígbà yẹn, wákàtí mẹ́wàá sì ni mo fi ń ṣiṣẹ́ lójúmọ́, torí náà mi ò lọ sí ilé ìwé. Nígbà tí mo pé ọmọ ọdún mérìnlá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń tún ẹ̀rọ ṣe.

Emi rèé nínú aṣọ ẹgbẹ́ ológun Spanish Foreign Legion nígbà tí mo dara pọ̀ mọ́ wọn lọ́dún 1975

 Ní ọdún 1975, wọ́n ní kí n wá wọṣẹ́ ológún. Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti fẹ́ fi ayé mi ṣe nǹkan táá fi hàn pé mo ní ìgboyà, torí náà mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ ológun Spanish Foreign Legion ní Melilla, ìyẹn àwọn ọmọ ogún Sípéènì tó wà ní apá àríwá ilẹ̀ Áfíríkà. Ìgbà yẹn náà ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lo oògùn olóró tí mo sì di ọ̀mùtí.

 Nígbà tí mo fi iṣẹ́ ológun sílẹ̀, mo pa dà sí Barcelona mo sì dá ẹgbẹ́ kan sílẹ̀. Olè là ń jà, oríṣiríṣi nǹkan la máa ń jí, a máa tà wọ́n, àá sì fi owó tá a bá rí níbẹ̀ ra oògùn olóró. Mo máa ń mutí gan-an, mo máa ń ta tẹ́tẹ́ mo sì ń ṣe ìṣekúṣe. Ìgbé ayé tí mò ń gbé yìí mú kí ń túbọ̀ di oníwà ipá. Gbogbo ìgbà ni ọ̀bẹ, ààké tàbí àdá máa ń wà lọ́wọ́ mi, kódà ẹ̀rù kì í bà mí láti lò ó.

 Ìgbà kan wà témi àtàwọn tá a jọ wà nínú ẹgbẹ́ burúkú yìí lọ jí ọkọ̀ kan, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ sí í lé wa. Ṣe ló dà bí ìgbà táà ń ṣe fíìmù. A gbé ọkọ̀ yẹn sáré kọjá ọgbọ̀n [30] kìlómítà, làwọn ọlọ́pàá bá bẹ̀rẹ̀ sí í yìnbọn sí wa. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn awakọ̀ wa fi ọkọ̀ náà kọlu nǹkan, gbogbo wa sì sá lọ. Nígbà tí bàbá mi gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, wọ́n lé mi kúrò nílé.

 Látìgbà yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í sun ìta, ọdún márùn-ún ni mo fi sun ìta. Ìgbà míì inú ọkọ̀ ni màá sùn, ìgbà míì orí bẹ́ǹṣì tó wà nínú ọgbà ìtura, kódà mo máa ń sùn sí itẹ́ òkú. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí mo sùn inú ihò àpáta. Ayé mi ò nítumọ̀ rárá, ayé sú mi, ṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n kú. Mo rántí ìgbà kan lẹ́yìn tí mo lo oògùn olóró, ṣe ni mò bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀bẹ gé ara mi lọ́wọ́, àpá ẹ̀ ṣì wà lára mi títí dòní.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ

 Nígbà tó yá, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í wá mi, wọ́n ní kí ń pa dà wálé, ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n [28] ni mí nígbà yẹn. Mo ṣèlérí fún wọn pé màá pa dà wálé, màá sì tún ìwà mi ṣe, àmọ́ ó pẹ́ díẹ̀ kí ń tó ṣe ohun tí mo sọ yẹn.

 Lọ́sàn-án ọjọ́ kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá wàásù fún wa nílé, bí mo ṣe ń tẹ́tí sí wọn ni bàbá mi pariwo láti inú ilé pé kí ń lé wọn dànù. Mi ò fẹ́ kéèyàn máa pàṣẹ fún mi, torí náà mì ò dá bàbá mi lóhùn. Tayọ̀tayọ̀ ni mo fi gbà ìwẹ́ mẹ́ta táwọn Ẹlẹ́rìí yẹn fún mi. Lẹ́yìn náà mo ní kí wọ́n sọ ibi tí ilé ìjọsìn wọn wà, ọjọ́ mélòó kan lẹ́yìn náà, mo lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba.

 Ohun tí mo kọ́kọ́ kíyèsí nígbà tí mo dé ìpàdé ni ìmúra àwọn tó wà níbẹ̀. Kò sẹ́ni tó dà bí èmi, ṣe ni irun mi gùn, irùngbọ̀n mi kún, aṣọ mi sì rí wúruwùru. Nígbà tí mo rí i pé èmi nìkan ni mo dá yàtọ̀, ṣe ni mo dúró síta. Ìyàlẹnu ló jẹ́ fún mi nígbà tí mo rí Juan tá a jọ wà nínú ẹgbẹ́ burúkú tẹ́lẹ̀ tó wọ kóòtù. Nígbà tó yá ni mo gbọ́ pé òun náà ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́dún kan sẹ́yìn, ìyẹn fún mi nígboyà láti wọlé sínú ìpàdé. Àtìgbà yẹn ni ayé mi ti bẹ̀rẹ̀ sí í dáa.

 Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí ni mo rí i pé tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, mo ní láti yí ìwà mi pa dà, mo sì gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú àwọn ìwà pálapàla tí mò ń hù. Lóòótọ́, kò rọrùn fún mi rárá láti ṣe àwọn ìyípadà yẹn, àmọ́ mo kẹ́kọ̀ọ́ pé tí mo bá fẹ́ múnú Jèhófà dùn, mo gbọ́dọ̀ yí pa dà, mo sì gbọ́dọ̀ yí “èrò inú [mi] padà.” (Róòmù 12:2) Mo mọrírì bí Ọlọ́run ṣe fi àánú hàn sí mi. Kò wo àwọn àṣìṣe tí mo ti ṣe, ṣe ló fẹ́ kí ń yí pa dà. Ohun tí mo kọ́ nípa Jèhófà wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere sí mi pé Ọlọ́run bìkítà fún mi.​—1 Pétérù 5:6, 7.

 Èyí ló mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìyípadà. Bí àpẹẹre, nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ nípa sìgá mímu, mo ṣo fúnra mi pé, ‘Jèhófà ò fẹ́ kí n sọ ara mi di ẹlẹ́gbin, torí náà mi ò gbọ́dọ̀ mu sìgá mọ́.’ (2 Kọ́ríńtì 7:1) Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo da gbogbo ẹ̀ nù.

 Mo tún rí i pé kò yẹ kí n máa mu oògùn olóró kò sì yẹ kí ń máa tà á. Èyí ò rọrùn rárá, kódà ó gbà mí ní ọ̀pọ̀ àkókò àti ìsapá kí n tó lè jáwọ́. Kó tó lè ṣeé ṣe, mo ní láti fi àwọn ọ̀rẹ́ burúkú tí mò ń bá rìn sílẹ̀, torí pé wọn ò lè jẹ́ kí ń tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo túbọ̀ ń gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà fún ìrànlọ́wọ́, àwọn ọ̀rẹ́ tuntun tí mo ní nínú ìjọ náà ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ mi dénú, wọ́n sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ mi jẹ àwọn lógún. Láàárín oṣù díẹ̀, mo jáwọ́ nínú mímu oògùn olóró, mo sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀,” èyí tó máa ràn mí lọ́wọ́ láti jọ́sìn Ọlọ́run lọ́nà tó fẹ́. (Éfésù 4:24) Nígbà tó máa fi di August 1985, mo ṣèrìbọmi, mo sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ

 Bíbélì ló tún ayé mi ṣe, òhun ló jẹ́ kí ń jáwọ́ nínú àwọn ìwà pálapàla tí mò ń hù tẹ́lẹ̀, tó fẹ́ ba ayé mi jẹ́, tí kò sì jẹ́ kí n níyì lójú ara mi. Kódà àwọn tí mò ń bá rìn tẹ́lẹ̀ ṣì kéré nígbà tí àrùn AIDS àtàwọn àrùn míì pa èyí tó ju ọgbọ̀n [30] lọ nínú wọn. Inú mi dùn pé mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì ń fi àwọn ìlànà inú rẹ̀ sílò, èyí ni kò jẹ́ kí ọ̀rọ̀ mi dà bíi tàwọn tí mò ń bá rìn tẹ́lẹ̀.

 Mi ò kì í ń mú ọ̀bẹ àti àáké kiri mọ́ bí mo ṣe máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ nígbà tí mo ṣì ń hùwà ipá. Kódà, mi ò ròó rí pé èmi náà á máa fi Bíbélì ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ní báyìí, èmi àti ìyàwó mi ti di òjíṣé tó ń fi àkókò púpọ̀ wàásù.

 Lóòótọ́ àwọn òbí mi ò di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ wọ́n mọrírì bí Bíbélì ṣe tún ayé mi ṣe. Kódà, bàbá mi gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà táwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ sọ̀rọ̀ wọn láìda. Bàbá mi náà rí i pé ẹ̀sìn tí mò ń ṣe nísìnyí ló tún ayé mi ṣe. Èyí ló máa ń mú kí màmá mi sọ fún mi pé ká ló o mọ̀ ni, tipẹ́tipẹ́ ni oò bá ti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, èmi náà gbà pẹ̀lú wọn.

 Ìrírí tí mo ti ní láyé ti jẹ́ kí n rí i pé ìwà òmùgọ̀ ni téèyàn bá ń lo oògùn olóró téèyàn sì ń hùwàkiwà torí pé ó fẹ́ gbádùn ara rẹ̀. Ní báyìí, inú mi ń dùn bí mo ṣe ń kọ́ àwọn míì lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó máa jẹ́ káyé wọn dáa bíi tèmi.