Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Wọn Ò Pa Ẹran Igbó Lára Nílùú Chelmsford

Wọn Ò Pa Ẹran Igbó Lára Nílùú Chelmsford

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì wọn tuntun sí tòsí ìlú Chelmsford, lágbègbè Essex. Oríṣiríṣi ẹran igbó ló ń gbé ní àgbègbè tó rẹwà yìí, ìjọba orílẹ̀-èdè United Kingdom sì ti ṣòfin kan lọ́dún 1981 pé àwọn èèyàn ò gbọ́dọ̀ jẹ́ káwọn ẹranko yìí pa run. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣiṣẹ́ ìkọ́lé yìí, kí ni wọ́n ṣe kí wọ́n má bàa rú òfin yìí, káwọn ẹranko yìí má bàa pa run?

Wọ́n ń kọ́ ibi tí eku dormouse á máa gbé

Àwọn Ẹlẹ́rìí lò lára igi tí wọ́n gé lórí ilẹ̀ tí wọ́n ń kọ́lé sí, wọ́n fi ṣe àwọn ilé onípákó kékeré fún àwọn eku kéékèèké kan tó ń jẹ́ hazel dormouse, kí wọ́n má bàa wá síbi tí iṣẹ́ tó ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n tún lọ́ àwọn ewéko pọ̀, wọ́n fi ṣe ibi tí àwọn eku yìí á máa gbà látorí àwọn igi bọ́ sínú igbó míì. Ìdí ni pé wọ́n ti la ọ̀nà sínú igbó yẹn, wọn ò sì fẹ́ dí àwọn eku yìí lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe máa ti inú igbó kan bọ́ sínú òmíì, torí náà, wọ́n gbé àwọn ewéko yẹn gba orí ibi tí wọ́n la ọ̀nà sí. Àwọn Ẹlẹ́rìí tún ṣètò míì fún àǹfààní àwọn eku yìí. Wọn ò gé gbogbo igbó tán lẹ́ẹ̀kan náà. Díẹ̀díẹ̀ ni wọ́n ń gé e lọ́dọọdún, ó sì máa ń jẹ́ lásìkò táwọn eku yìí kì í jáde síta. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é yìí ò jẹ́ kí wọ́n pa àwọn eku yìí lára, igbó ṣì wà fún wọn láti dúró sí, èyí sì ń jẹ́ kí wọn ṣì máa rí oríṣiríṣi ibi tí wọ́n ti lè máa jẹ̀ káàkiri lórí ilẹ̀ náà.

Wọ́n ń dé ilé onípákó tí wọ́n ṣe fún eku dormouse mọ́ ara igi

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tún ṣèpalára fáwọn ejò, àwọn aláǹgbá àtàwọn aláǹgbá kéékèèké kan tí kì í lẹ́sẹ̀, tí wọ́n rí bí ejò, wọ́n ń pè wọ́n ní blindworm. Àwọn tó ń bójú tó àyíká rí àwọn aláǹgbá yìí níbi tí wọ́n fara pa mọ́ sí, lábẹ́ àwọn ohun èlò pẹlẹbẹ tí wọ́n fi ń ṣe òrùlé ilé, wọ́n wá kó wọn kúrò níbẹ̀ kí wọ́n má bàa pa wọ́n lára tí iṣẹ́ ìkọ́lé bá ń lọ lọ́wọ́. Wọ́n kó wọn lọ síbòmíì tí wọ́n ṣètò fún wọn, ibi tí wọ́n á máa wọ̀ sí wà níbẹ̀, wọ́n sì ṣe ọgbà yí wọn ká. Torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí ò fẹ́ kí ohunkóhun ṣe àwọn aláǹgbá yìí, wọ́n máa ń lọ wo ọgbà náà déédéé kí wọ́n lè tún un ṣe tí wọ́n bá rí i pé àwọn aláǹgbá náà ti fẹ́ máa gba àwọn ibì kan jáde níbẹ̀, síbi tí iṣẹ́ ìkọ́lé ti ń lọ.

Eku hazel dormouse

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún wá ọgbọ́n kan dá sọ́rọ̀ àwọn àdán tó wà nínú igbó náà. Torí pé alẹ́ làwọn àdán máa ń jáde, tí wọn ò sì fẹ́ ṣèdíwọ́ fún wọn, wọ́n ṣe àwọn gílóòbù ńlá kan sínú ọgbà náà. Àrà ọ̀tọ̀ làwọn gílóòbù yìí, torí kì í jẹ́ kí iná tó bá tàn níbòmíì mọ́lẹ̀ káàkiri. Tí gílóòbù yìí bá ti gbúròó mọ́tò, ṣe ló máa ń tàn. Èyí ò ní jẹ́ kí iná mọ́tò náà mọ́lẹ̀ káàkiri, débi táá máa tanná sáwọn àdán náà nínú òkùnkùn tí wọ́n máa ń fẹ́ wà. Torí pé àwọn àdán sábà máa ń wá oúnjẹ kiri lálẹ́ nínú igbó tó yí ọgbà yìí ká, àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣètò pé wọn ò ní gé ọ̀pọ̀ lára igbó yìí, wọ́n sì máa gbin igbó míì síbi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ gùn tó máìlì méjì lórí ilẹ̀ náà. Ó di dandan kí wọ́n gé àwọn igi kan lórí ilẹ̀ náà, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ fi pákó ṣe ilé táwọn àdán yìí lè máa wọ̀ sí torí wọ́n ti gé àwọn igi tó ṣeé ṣe kí àwọn ẹyẹ náà fẹ́ kọ́ ìtẹ́ sí.

Wọ́n ń dé ilé onípákó tí wọ́n ṣe fáwọn àdán mọ́ ara igi

Àwọn igi pàtàkì kan wà lórí ilẹ̀ náà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò gé, wọ́n ń pè é ní igi veteran. Wọn ò ṣiṣẹ́ ìkọ́lé wọn nítòsí ibi táwọn igi yìí ta gbòǹgbò dé. Oríṣiríṣi ẹranko, àdán àtàwọn ẹyẹ ló ń gbé orí àwọn igi veteran yìí. Gbogbo ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe yìí fi hàn pé wọ́n ti pinnu pé àwọn ò ní pa àwọn ẹran igbó lára nílùú Chelmsford.